Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

YURI LASHOV/AFP via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Lọ́wọ́ Sí Ogun​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Lọ́wọ́ Sí Ogun​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Bá a ṣe rí i nígbà ogun tó wáyé ní Ukraine, ọ̀pọ̀ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ló ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n lọ́wọ́ sí ogun. Ẹ kíyè sí bí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń ti orílẹ̀-èdè wọn lẹ́yìn nínú ogun náà:

  •   “A dúpẹ́ gan-an, a sì mọyì àwọn ọmọ ogun wa tó ń jà fún Ukraine tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ wọn bí àwọn ọ̀tá ṣe ń gbógun jà wá . . . A fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé tọkàntọkàn la fi ń tì yín lẹ́yìn, a sì ń gbàdúrà fún yín.”​—Ohun tí Àlùfáà Epiphanius Kìíní ti ìlú Kyiv sọ nínú ìwé ìròyìn The Jerusalem Post, March 16, 2022.

  •   “Ẹni tó jẹ́ olórí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe ìpàdé pàtàkì kan pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà lọ́jọ́ Sunday níbi tó ti fún wọn níṣìírí láti túbọ̀ máa ti orílẹ̀-èdè wọn lẹ́yìn ‘bí ọmọ ìlú Rọ́ṣíà tòótọ́’ kí ìlú Moscow sì máa tẹ̀ síwájú bí wọ́n ṣe ń bá orílẹ̀-èdè Ukraine jagun.”​—Reuters, April 3, 2022.

 Ṣé ó yẹ káwọn Kristẹni lọ́wọ́ sí ogun? Kí ni Bíbélì sọ?

Ohun tí Bíbélì sọ gan-an

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó ń tẹ̀ lé Jésù Kristi lóòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí ogun.

  •   “Dá idà rẹ pa dà sí àyè rẹ̀, torí gbogbo àwọn tó bá yọ idà máa ṣègbé nípasẹ̀ idà.”​—Mátíù 26:52.

     Ṣé ẹni tó ń kọ́wọ́ ti ogun tàbí tó ń ja ogun ń pa àṣẹ Jésù mọ́ lóòótọ́?

  •   “Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín. Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”​—Jòhánù 13:34, 35.

     Ṣe ẹni tó ń ti ogun lẹ́yìn ń fi hàn pé òun ní irú ìfẹ́ tí Jésù sọ pé wọ́n á fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀?

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Jagun?

Ojú wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni máa fi wo ogun lónìí?

 Ṣé ó ṣeé ṣe káwọn Kristẹni pinnu pé àwọn ò ní lọ́wọ́ sí ogun lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò wà yìí ìyẹn “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” pé, àwọn kan máa wà tí wọ́n máa wá láti ibi gbogbo láyé tí wọn ò sì ní “kọ́ṣẹ́ ogun mọ,” bí Jésù ṣe sọ.​—Àìsáyà 2:2, 4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.

 Láìpẹ́, Jèhófà a “Ọlọ́run àlàáfíà” máa lo Ìjọba rẹ̀ láti gba àwọn èèyàn sílẹ̀ “lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”​—Fílípì 4:9; Sáàmù 72:14.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.​—Sáàmù 83:18.