Ìwádìí Àwọn Awalẹ̀pìtàn Jẹ́ Ká Rí I Pé Ọba Dáfídì Gbé Láyé Rí Lóòótọ́
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọgọ́rùn-ún ọdún kọkànlá Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Ọba Dáfídì gbé láyé, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún làwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ sì fi jọba. Àmọ́ àwọn alárìíwísí kan ò gbà, wọ́n ní ìtàn àròsọ lásán ni ìtàn Dáfídì, pé àwọn èèyàn ló hùmọ̀ ẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ́ kiri. Ṣé òótọ́ ni Ọba Dáfídì gbé láyé rí?
Lọ́dún 1993, awalẹ̀pìtàn kan tó ń jẹ́ Avraham Biran àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ rí àfọ́kù òkúta kan nílùú Tel Dan, ní àríwá ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ohun tí wọ́n kọ sára òkúta náà ń tọ́ka sí “Ilé Dáfídì.” Bí àwọn Júù àtàwọn ará Arébíà ayé àtijọ́ ṣe máa ń kọ̀wé ni wọ́n ṣe kọ ọ̀rọ̀ tó wà lára òkúta náà, ó sì ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹsàn-án Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ẹ̀rí fi hàn pé àfọ́kù táwọn awalẹ̀pìtàn rí yìí wà lára òkúta gìrìwò kan táwọn ọmọ Árámù gbẹ́ láti máa fi rántí báwọn ṣe ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé Bible History Daily sọ pé: “Àwọn kan wà tí wọ́n kọminú sí àkọlé tó wà lára àfọ́kù òkúta yẹn, ìyẹn ‘Ilé Dáfídì’ . . . Àmọ́, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń ṣèwádìí nípa Bíbélì àtàwọn awalẹ̀pìtàn gbà láìjanpata pé òkúta tí wọ́n rí nílùú Tel Dan ni ẹ̀rí àkọ́kọ́ tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ẹnì kan wà lóòótọ́ tó ń jẹ́ Ọba Dáfídì, bí Bíbélì ṣe sọ. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára ìwádìí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ jù lọ nípa Bíbélì tí ìwé BAR [ìyẹn Biblical Archaeology Review] sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”