Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

hadynyah/E+ via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ogun àti Ojú Ọjọ́ Tó Ń Burú Sí I Túbọ̀ Ń Fa Ọ̀wọ́n Gógó Oúnjẹ Kárí Ayé​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Ogun àti Ojú Ọjọ́ Tó Ń Burú Sí I Túbọ̀ Ń Fa Ọ̀wọ́n Gógó Oúnjẹ Kárí Ayé​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Ogun tó ń jà ní orílẹ̀-èdè Ukraine, àti ojú ọjọ́ tó ń burú sí i ti mú kí oúnjẹ túbọ̀ wọ́n kárí ayé. Ìṣòro yìí tún wá légbá kan láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.

  •   “Rògbòdìyàn, ojú ọjọ́ tó ń burú sí i, ọ̀wọ́n gógó epo àtàwọn ìṣòro míì ló ń jẹ́ kí àìtó oúnjẹ wà.”​—António Guterres tó jẹ́ akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé, July 17, 2023.

  •   “Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n gbà pé bí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe yọwọ́ nínú àdéhùn tí wọ́n ṣe láti máa ta ọkà fáwọn orílẹ̀-èdè míì máa mú kí oúnjẹ túbọ̀ wọ́n, pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ò ti rọ̀ṣọ̀mù bí àríwá ilẹ̀ Áfíríkà àti Middle East.”​—Atalayar.com, July 23, 2023.

 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àìtó oúnjẹ máa wà

  •   Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ . . . sì máa wà.”​—Mátíù 24:7.

  •   Ìwé Ìfihàn sọ nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin kan. Ọ̀kan nínú wọn dúró fún ogun, èyí tó sì tẹ̀ lé e dúró fún àìtó oúnjẹ, ìyẹn ìgbà tí oúnjẹ ò ní tó, tí èyí tó wà sì máa wọ́n gan-an. Bíbélì sọ pé: “Mo rí ẹṣin dúdú kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Mo wá gbọ́ nǹkankan tí ó dàbí ohùn . . . ó ní, ‘Páànù ọkà bàbà kan fún owó fadaka kan. Páànù ọkà baali mẹta fún owó fadaka kan.’”​—Ìfihàn 6:5, 6, Yoruba Bible.

 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí nípa àìtó oúnjẹ ti ń ṣẹ lónìí lákòókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àtàwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin tó wà nínú Ìfihàn, wo fídíò náà Ọdún 1914 Ni Ayé Yí Pa Dà Bìrí kó o sì ka àpilẹ̀kọ “Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?

Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́

  •   Ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó wúlò tó lè ràn wá lọ́wọ́ tí nǹkan ò bá rọrùn ló wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ ohun tá a lè ṣe bí oúnjẹ ṣe ń wọ́n sí i. Wàá rí àwọn àpẹẹrẹ míì nínú àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná.”

  •   Bíbélì tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé nǹkan ṣì máa dáa. Ó sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà lórí ilẹ̀,” gbogbo èèyàn sì máa jẹ àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù. (Sáàmù 72:16) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìrètí tá a ní yìí àti ohun tó mú kó dá wa lójú, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa.”