Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ogun Tó Ń Jà Ní Ukraine Ti Dá Kún Ìṣòro Àìtó Oúnjẹ

Ogun Tó Ń Jà Ní Ukraine Ti Dá Kún Ìṣòro Àìtó Oúnjẹ

 Ní May 19, 2022, ohun tó ju márùndínlọ́gọ́rin (75) nínú àwọn ọ̀gá àgbà tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Ààbò Nínú Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ pé, “àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà àti ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà tó ti dá kún ìṣòro àìtó oúnjẹ tó wà kárí ayé la ṣì ń bá yí. Ní báyìí, ogun tó ń jà ní Ukraine ti mú kí ọ̀rọ̀ náà burú débi pé ó ṣeé ṣe kí ìyàn mú láwọn ibì kan láyé.” Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ìwé ìròyìn The Economist sọ pé, “ṣe ni ogun tó ń jà yìí máa mú kí àìtó oúnjẹ túbọ̀ pọ̀ sí i nínú ayé tó ti dojú rú tẹ́lẹ̀.” Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìṣòro àìtó oúnjẹ máa wà ní àkókò wa yìí, ó sì tún sọ ohun tá a lè ṣe tá a bá bára wa nípò yẹn.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àìtó oúnjẹ máa wà

  •    Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ . . . sì máa wà.”Mátíù 24:7.

  •    Ìwé Ìfihàn inú Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin kan. Ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́ṣin yẹn ṣàpẹẹrẹ ogun. Ẹlẹ́ṣin tó tẹ̀ lé e ṣàpẹẹrẹ ìyàn, ìyẹn ìgbà tí oúnjẹ ò ní kárí, tí ìwọ̀nba tó wà sì máa wọ́n gan-an. Bíbélì sọ pé: “Mo rí ẹṣin dúdú kan, òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì sì wà lọ́wọ́ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀. Mo gbọ́ tí nǹkan kan dún bí ohùn . . . Ó sọ pé: ‘Òṣùwọ̀n kúọ̀tì àlìkámà kan fún owó dínárì kan àti òṣùwọ̀n kúọ̀tì mẹ́ta ọkà báálì fún owó dínárì kan.’”—Ìfihàn 6:5, 6.

 Ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àìtó oúnjẹ tí ń ṣẹ ní àkókò wa yìí tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àtàwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin tí ìwé Ìfihàn sọ nípa wọn, wo fídíò náà Ọdún 1914 Ni Ayé Yí Pa Dà Bìrí, kó o sì ka àpilẹ̀kọ “Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?

Bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́

  •    Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá dojú kọ àwọn ipò tí kò bára dé, bí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ tàbí àìtó oúnjẹ. O lè rí àpẹẹrẹ àwọn ìmọ̀ràn yìí nínú àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná.

  •    Bíbélì tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé nǹkan ṣì máa dáa. Ó ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà lórí ilẹ̀,” gbogbo wa sì máa ní nǹkan rẹpẹtẹ láti jẹ. (Sáàmù 72:16) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ iwájú àti ìdí tá a fi gbà pé ohun tó sọ máa ṣẹ, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa.”