Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
2022: Ọdún Wàhálà àti Ìdàrúdàpọ̀—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Lọ́dún 2022, àwọn ìròyìn tó dá lórí ogun, ipò ọrọ̀ ajé tó ń dẹnu kọlẹ̀ àtàwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ ló gbalẹ̀ gbòde. Bíbélì nìkan ló ṣàlàyé ohun táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ń jẹ́ ká mọ̀.
Ohun táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún 2022 ń jẹ́ ká mọ̀
Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2022 jẹ́ kó túbọ̀ hàn gbangba pé àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà báyìí. (2 Tímótì 3:1) Àkókò yẹn sì bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Kíyè sí bí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ṣe bá ohun tí Bíbélì sọ nípa àkókò wa mu:
“Ogun.”—Mátíù 24:6.
“2022 Ni Ọdún Tí Ogun Bẹ̀rẹ̀ Pa Dà Nílẹ̀ Yúróòpù.” a
Wo àpilẹ̀kọ náà “Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Gbógun Wọ Orílẹ̀-èdè Ukraine.”
“Àìtó oúnjẹ.”—Mátíù 24:7.
“Ebi Àpafẹ́ẹ̀kú Pa Àwọn Èèyàn Lọ́dún 2022.” b
Wo àpilẹ̀kọ náà “Ogun Tó Ń Jà Ní Ukraine Ti Dá Kún Ìṣòro Àìtó Oúnjẹ.”
“Àjàkálẹ̀ àrùn.”—Lúùkù 21:11.
“Bí àrùn monkeypox àti Kòrónà ṣe ń ṣọṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àrùn rọpárọsẹ̀ tá a mọ̀ sí Polio tún bẹ̀rẹ̀ sí í han àwọn èèyàn léèmọ̀. Ṣe là ń tinú àìsàn kan bọ́ sínú òmíì.” c
Wo àpilẹ̀kọ náà “Àrùn Kòrónà Ti Pa Mílíọ̀nù Mẹ́fà Èèyàn.”
“Àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù.”—Lúùkù 21:11.
“Ojú ọjọ́ ò fara rọ rárá ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2022. Kárí ayé làwọn nǹkan bí ooru gbígbóná, ọ̀gbẹlẹ̀, igbó tó ń jó àti omíyalé ti ṣọṣẹ́ gan-an. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ojú ọjọ́ tí ò fara rọ yìí bà jẹ́, kódà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn lẹ̀mí wọn lọ sí i, ó sì sọ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé di aláìnílé mọ́.” d
Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Ooru Ṣe Ń Mú Gan-an Kárí Ayé?”
“Rògbòdìyàn [tàbí, “rúkèrúdò; ìdàrúdàpọ̀,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé].”—Lúùkù 21:9.
“Torí pé inú ń bí ọ̀pọ̀ èèyàn nítorí ọrọ̀ ajé tó ń dẹnu kọlẹ̀ àti bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń gbówó lórí, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn wọ́de lọ́dún 2022 láti fi ẹ̀hónú hàn sí ìjọba.” e
Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Nǹkan Ṣe Túbọ̀ Ń Gbówó Lórí Kárí Ayé?”
Báwo ni nǹkan ṣe máa rí lọ́dún tó ń bọ̀?
Kò sẹ́ni tó lè sọ ní pàtó pé báyìí ni nǹkan ṣe máa rí lọ́dún 2023. Àmọ́ ohun kan tá a mọ̀ ni pé, láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa tún ayé ṣe. (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba yẹn máa fòpin sí gbogbo ohun tó ń fa ìyà fáwa èèyàn, á sì jẹ́ kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé yìí ṣẹ.—Mátíù 6:9, 10.
A rọ̀ ẹ́ pé kó o fi ìmọ̀ràn Jésù Kristi sọ́kàn pé ká “máa ṣọ́nà,” ká sì máa kíyè sí bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyè ṣe ń fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ. (Máàkù 13:37) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nísinsìnyí àti bó ṣe lè jẹ́ kí ọkàn ìwọ àti ìdílé rẹ balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, jọ̀wọ́ kàn sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
a AP News, “2022 Ni Ọdún Tí Ogun Bẹ̀rẹ̀ Pa Dà Nílẹ̀ Yúróòpù,” látọwọ́ Jill Lawless, December 8, 2022.
b “Ìṣòro Àìtó Oúnjẹ Kárí Ayé” látọ̀dọ̀ World Food Programme.
c JAMA Health Forum, “Àjàkálẹ̀ Àrùn Gbalẹ̀ Gbòde, Látorí Kòrónà Dórí Monkeypox, Polio Àtàwọn Àrùn Míì,” látọwọ́ Lawrence O. Gostin, JD, September 22, 2022.
d Earth.Org, “Kí Ló Fà Á Tí Ojú Ọjọ́ Ò Fi Bára Dé Nígbà Ẹ̀ẹ̀rùn Ọdún 2022?” látọwọ́ Martina Igini, October 24, 2022.
e Carnegie Endowment for International Peace, “Ipò Ọrọ̀ Ajé Tó Dẹnu Kọlẹ̀ Mú Káwọn Èèyàn Wọ́de Gan-an Lọ́dún 2022,” látọwọ́ Thomas Carothers àti Benjamin Feldman, December 8, 2022.