Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Wọ́n Ṣe Ń Yìnbọn Pa Àwọn Èèyàn Nípakúpa Kárí Ayé?
Ní July 2022, kárí ayé ni wọ́n ti yìnbọn pa àwọn èèyàn nípakúpa:
“Bí wọ́n ṣe pa gbajúmọ̀ olóṣèlú kan lórílẹ̀-èdè Japan [ìyẹn Shinzo Abe, tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olórí ìjọba] ti dá wàhálà sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè náà, ó sì ti mú kẹ́rù máa ba àwọn èèyàn kárí ayé torí pé ìwà ipá ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní orílẹ̀-èdè Japan, òfin sì tún wà nípa bí wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ lo ìbọn.”—July 10, 2022, The Japan Times.
“Bí ọkùnrin kan ṣé yìnbọn pa àwọn mẹ́ta ní ilé ìtajà Copenhagen lórílẹ̀-èdè Denmark ti kó ìpayà bá àwọn èèyàn.”—July 4, 2022, Reuters.
Lórílẹ̀-èdè South Africa, àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ló kú nígbà tí àwọn ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀jò ìbọn sí ilé ìgbafẹ́ kan ní ìlú Soweto.”—July 10, 2022, The Guardian.
“Nígbà ọlidé July 4 lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ohun tó lé ní igba ó lé ogún (220 ) èèyàn ni wọ́n yìnbọn pa nípakúpa lópin ọ̀sẹ̀ yẹn.”—July 5, 2022, CBS News.
Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tírú ìwà ipá yìí máa dópin? Kí ni Bíbélì sọ?
Ìwà Ipá Máa Dópin
Bíbélì pe àkókó wa yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìyẹn àkókò tí àwọn èèyàn á jẹ́ ẹni tó burú gan-an, tí wọ́n á sì máa hùwà ipá. (2 Tímótì 3:1, 3) Irú àwọn ìwà yìí ti mú kẹ́rù máa ba àwọn èèyàn. (Lúùkù 21:11) Bíbélì ṣèlérí pé àkókò kan ń bọ̀ tí ìwà ipá máa dópin tí ‘àwọn èèyàn á máa gbé ibi tí àlàáfíà ti jọba, nínú àwọn ibi tó ní ààbò àtàwọn ibi ìsinmi tó pa rọ́rọ́.’ (Àìsáyà 32:18) Báwo ni ìwà ipá ṣe máa dópin?
Ọlọ́run máa pa àwọn ẹni ibi run, ó sì máa run àwọn ohun ìjà ogun wómúwómú.
“Ní ti àwọn ẹni burúkú, a ó pa wọ́n run kúrò ní ayé.”—Òwe 2:22.
“[Ọlọ́run] ń fòpin sí ogun kárí ayé. Ó ṣẹ́ ọrun, ó sì kán ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun nínú iná.”—Sáàmù 46:9.
Ọlọ́run á mú káwọn èèyàn máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà, ìyẹn á sì mú kí ìwà ipá dópin títí láé.
“Wọn ò ní fa ìpalára kankan, tàbí ìparun kankan ní gbogbo òkè mímọ́ mi, torí ó dájú pé ìmọ̀ Jèhófà máa bo ayé, bí omi ṣe ń bo òkun.”—Àìsáyà 11:9.
Kódà ní báyìí, Ọlọ́run ń kọ́ àwọn èèyàn kárí ayé láti jáwọ́ nínú ìwà ipá àti lílo àwọn ohun ìjà. Ó fẹ́ kí ‘wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀, kí wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.’—Míkà 4:3.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìlérí tí Bíbélì ṣe pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ẹ̀rù ò ní bà wá mọ́ kárí ayé, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Aráyé Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ohun Tó Ń Fa Ìbẹ̀rù?”
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó máa fòpin sí ìwà ipá pátápátá, ka àpilẹ̀kọ náà “Peace on Earth at Last!” Lédè Gẹ̀ẹ́sì.