Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Comstock Images/Stockbyte via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Alákòóso Wo Lo Máa Yàn?​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Alákòóso Wo Lo Máa Yàn?​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Láìpẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè kárí ayé máa dìbò kí wọ́n lè yan alákòóso míì. Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ronú nípa ẹni tí wọ́n máa dìbò fún.

 Kí ni Bíbélì sọ?

Ó níbi tí agbára àwọn alákòóso èèyàn mọ

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó níbi tí agbára gbogbo àwọn alákòóso èèyàn mọ. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé:

  •   “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn olórí tàbí lé ọmọ èèyàn, tí kò lè gbani là. Èémí rẹ̀ jáde lọ, ó pa dà sínú ilẹ̀; ọjọ́ yẹn gan-an ni èrò inú rẹ̀ ṣègbé.”​—Sáàmù 146:3, 4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.

 Kò sí bí alákòóso kan ṣe dáa tó, ó máa pa dà kú náà ni. Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò lè fọwọ́ sọ̀yà pé ẹni tó máa ṣàkóso lẹ́yìn àwọn á máa bá iṣẹ́ rere wọn lọ.​—Oníwàásù 2:18, 19.

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ò dá àwa èèyàn láti máa ṣàkóso ara wa.

  •   “Kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”​—Jeremáyà 10:23.

 Ṣé ẹnì kan wà tó lè ṣàkóso lọ́nà tó dáa lónìí?

Alákòóso tí Ọlọ́run fọwọ́ sí

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti yan alákòóso kan tó dáńgájíá, tó sì ṣeé fọkàn tán, ìyẹn Jésù Kristi. (Sáàmù 2:6) Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba tó ń ṣàkóso láti ọ̀run.​—Mátíù 6:10.

 Ṣé wàá fara mọ́ ìṣàkóso Jésù? Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tí ìbéèrè yẹn fi ṣe pàtàkì:

  •   Ẹ bọlá fún [Jésù Kristi], àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run máa bínú ẹ sì máa ṣègbé kúrò lójú ọ̀nà, nítorí ìbínú Rẹ̀ tètè máa ń ru. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó fi Í ṣe ibi ààbò.”​—Sáàmù 2:12.

 Àkókò yìí gan-an ló yẹ ká ṣèpinnu. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ọdún 1914 ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, àti pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn.​—Dáníẹ́lì 2:44.

 Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè fara mọ́ ìṣàkóso Jésù, ka àpilẹ̀kọ náà “Fi Hàn Nísinsìnyí Pé Ìjọba Ọlọ́run Lo Fara Mọ́!