Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Nǹkan Ṣe Túbọ̀ Ń Gbówó Lórí Kárí Ayé?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Nǹkan Ṣe Túbọ̀ Ń Gbówó Lórí Kárí Ayé?

 Ààrẹ Àjọ Báńkì Àgbáyé kìlọ̀ nínú ìròyìn kan tó jáde ní June 2022 pé: “Ipò ọrọ̀ ajé túbọ̀ ń burú sí i kárí ayé. Gbogbo nǹkan túbọ̀ ń gbówó lórí, bẹ́ẹ̀ ni owó tó ń wọlé fáwọn èèyàn túbọ̀ ń dín kù.”

 Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Owó Lágbàáyé sọ pé: “Oúnjẹ àti epo túbọ̀ ń gbówó lórí gan-an, àwọn tálákà tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ló sì ń jìyà ẹ̀ jù.”

 Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí táwọn nǹkan yìí fi ń ṣẹlẹ̀, ó tún jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fara dà á àti ojútùú sí ìṣòro náà.

Bí nǹkan ṣe ń gbówó lórí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”

  •   Bíbélì pe àkókò tá à ń gbé yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”​—2 Tímótì 3:1.

  •   Jésù sọ pé “àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù” á máa ṣẹlẹ̀ lákòókò yìí. (Lúùkù 21:11) Bí owó ọjà ṣe ń lọ sókè túbọ̀ ń bani lẹ́rù. Àwọn èèyàn ń ṣàníyàn nípa bí nǹkan ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú, wọ́n sì máa ń rò ó pé bóyá làwọn á lè rówó gbọ́ bùkátà ìdílé wọn.

  •   Ìwé Ìfihàn nínú Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé oúnjẹ á túbọ̀ máa wọ́n lásìkò yìí. “Mo gbọ́ tí nǹkan kan dún bí ohùn . . . ó sọ pé: “Òṣùwọ̀n kúọ̀tì àlìkámà kan fún owó dínárì kan àti òṣùwọ̀n kúọ̀tì mẹ́ta ọkà báálì fún owó dínárì kan [ìyẹn owó iṣẹ́ ọjọ́ kan].’”​—Ìfihàn 6:6.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àti àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìfihàn, wo fídíò Ọdún 1914 Ni Ayé Yí Pa Dà Bìrí, kó o sì ka àpilẹ̀kọ “Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?

Bí ìṣòro ọrọ̀ ajé tó ń burú sí i ṣe máa dópin

  •   “Wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn. Wọn ò ní kọ́lé fún ẹlòmíì gbé, wọn ò sì ní gbìn fún ẹlòmíì jẹ.”​—Àìsáyà 65:​21, 22.

  •   “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà lórí ilẹ̀; ó máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ lórí àwọn òkè.”​—Sáàmù 72:16.

  •   “‘Nítorí ìnira àwọn tí ìyà ń jẹ, nítorí ìkérora àwọn aláìní, màá dìde láti gbé ìgbésẹ̀,’ ni Jèhófà wí.”​—Sáàmù 12:5. a

 Láìpẹ́, Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìṣòro ọrọ̀ ajé tó ń burú sí i, kì í ṣe ní orílẹ̀-èdè kan, àmọ́ kárí ayé. Tó o bá fẹ́ mọ bí Ọlọ́run ṣe máa ṣe é, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Táwọn Olówó Àtàwọn Tálákà Máa Ní Nǹkan Lọ́gbọọgba?

 Ní báyìí ná, Bíbélì lè jẹ́ kó o mọ àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń gbówó lórí. Bí àpẹẹrẹ, ó fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó dáa nípa bá a ṣe le máa ṣọ́wó ná. (Òwe 23:​4, 5; Oníwàásù 7:12) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àwọn àpilẹ̀kọ náà “Ṣe Ohun Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Àtijẹ Àtimu Nira Fún Ẹ” àti “Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná.”

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.​—Sáàmù 83:18.