Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Comstock Images/Stockbyte via Getty Images

ÀKÀNṢE ÌWÀÁSÙ

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe Sáwọn Olóṣèlú Jẹgúdújẹrá

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe Sáwọn Olóṣèlú Jẹgúdújẹrá

 Ọ̀rọ̀ àwọn olóṣèlú tó jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀ ti sú àwọn èèyàn. Torí náà, àwọn olóṣèlú tó ṣeé fọkàn tán ni wọ́n ń fẹ́. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe kárí ayé lọ́dún 2023 fi hàn pé, àwọn olóṣèlú wà lára àwọn táwọn aráàlú ò fọkàn tán rárá àti rárá. a

 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba kan tí alákòóso ẹ̀ jẹ́ olóòótọ́, tó sì ṣeé fọkàn tán, kódà alákòóso yìí kò ní ni àwọn èèyàn lára. Ìjọba wo ni ìjọba yìí? Ìjọba Ọlọ́run ni, Jésù sì ni Ọba Ìjọba náà.​—Àìsáyà 9:7.

 Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn ohun tó ṣe jẹ́ ká rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún. (Mátíù 9:35, 36) Láìpẹ́, ó máa mú kára tu gbogbo àwọn tó bá fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀, á sì mú kí àlàáfíà wà kárí ayé.​—Sáàmù 72:12-14.

a Ìwádìí Tí Edelman Trust Barometer Ṣe Kárí Ayé Lọ́dún 2023.