Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Chris McGrath/Getty Images

ÀKÀNṢE ÌWÀÁSÙ

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Ogun

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Ogun

 Ogun tó ń jà kárí ayé ti ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́, ó sì ti fa ọ̀pọ̀ ìnira fáwọn èèyàn. Kíyè sí àwọn ìròyìn tó tẹ̀ lé e yìí:

  •   “Iye àwọn tí ogun pa lórílẹ̀-èdè Etiópíà àti Ukraine lọ́dún tó kọjá nìkan ju àwọn tí ogun ti pa láti 1994.” ​—Peace Research Institute Oslo, June 7, 2023.

  •   “Lọ́dún 2022, ogun tó jà ní Ukraine wà lára ogun tó tíì burú jù lọ. Kárí ayé ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn olóṣèlú légbá kan sí i lọ́dún tó kọjá, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lèyí sì ṣàkóbá fún.”​—The Armed Conflict Location & Event Data Project (ACLED), February 8, 2023.

 Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀. Ó sọ pé “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Lábẹ́ Ìjọba yìí, Ọlọ́run máa “fòpin sí ogun kárí ayé.”​—Sáàmù 46:9.