Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Táwọn Olówó Àtàwọn Tálákà Máa Ní Nǹkan Lọ́gbọọgba?

Ṣé Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Táwọn Olówó Àtàwọn Tálákà Máa Ní Nǹkan Lọ́gbọọgba?

 Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn ń fi ẹ̀hónú hàn torí ọ̀wángógó ọjà. Ńṣe ni àrùn Corona tún wá fọ́ gbogbo ẹ̀ lójú torí pé òfin kónílé-gbélé ti mú kí nǹkan túbọ̀ gbówó lórí, káwọn èèyàn máa wọ́de, kí ọ̀pọ̀ má sì rí ìtọ́jú ìṣègùn tó péye gbà. Àwọn nǹkan yìí wá jẹ́ kí ìyàtọ̀ tó wà láàárín olówó àti tálákà túbọ̀ hàn kedere.

 Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí gbogbo àwọn ìṣòro tá à ń dojú kọ máa dópin? Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe máa yanjú àwọn ìṣòro tá à ń dojú kọ.

Ìṣòro ọrọ̀ ajé tí Ọlọ́run máa yanjú

 Ìṣòro: Ìjọba aráyé ò lè pèsè gbogbo ohun táwọn èèyàn nílò.

 Ohun tí Ọlọ́run máa ṣe: Ọlọ́run máa fi Ìjọba rẹ̀ rọ́pò ìjọba èèyàn, Ìjọba yìí á sì máa ṣàkóso gbogbo ayé látọ̀run.—Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10.

 Ohun tá a máa gbádùn: Ọ̀nà tó dáa ni ìjọba Ọlọ́run máa gbà ṣàkóso gbogbo ayé. Àwọn èèyàn ò tún ní máa ṣàníyàn torí àtijẹ-àtimu tàbí kẹ́rù máa bà wọ́n nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Sáàmù 9:7-9, 18) Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn á maá gbádùn iṣẹ́ wọn, wọ́n á sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ìdílé wọn. Bíbélì ṣèlérí pé: “Wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn. Wọn ò ní kọ́lé fún ẹlòmíì gbé, wọn ò sì ní gbìn fún ẹlòmíì jẹ.”—Àìsáyà 65:21, 22.

 Ìṣòro: Kò sẹ́ni tí nǹkan burúkú kì í ṣẹlẹ̀ sí.

 Ohun tí Ọlọ́run máa ṣe: Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, àwọn èèyàn ò ní bẹ̀rù mọ́ ọkàn wọn á sì balẹ̀.

 Ohun tá a máa gbádùn: Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kò ní sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá mú káwọn èèyàn pàdánù àwọn ohun kòṣéémání wọn. Ogun, Àìtó oúnjẹ àti Àjàkálẹ̀ àrùn máa dohun ìtàn. (Sáàmù 46:9; 72:16; Àìsáyà 33:24) Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Ibi tí àlàáfíà ti jọba làwọn èèyàn mi á máa gbé, nínú àwọn ibi tó ní ààbò àtàwọn ibi ìsinmi tó pa rọ́rọ́.”—Àìsáyà 32:18.

 Ìṣòro: Àwọn onímọtara-ẹni-nìkan àti àwọn olójú kòkòrò máa ń kó àwọn èèyàn nífà.

 Ohun tí Ọlọ́run máa ṣe: Àwọn tó bá jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run á máa fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sí ara wọn, wọn ò sì ní mọ tara wọn nìkan.—Mátíù 22:37-39.

 Ohun tá a máa gbádùn: Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run gbogbo èèyàn á fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn ìyẹn ìfẹ́ tí “kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Bíbélì sọ pé: “Wọn ò ní fa ìpalára kankan, tàbí ìparun kankan ní gbogbo òkè mímọ́ mi, torí ó dájú pé ìmọ̀ Jèhófà  a máa bo ayé, bí omi ṣe ń bo òkun.”—Àìsáyà 11:9.

 Bíbélì fi hàn pé à ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan yìí àti pé láìpẹ́ Ọlọ́run máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ láti fòpin sí gbogbo ìṣòro ọ̀wọ́ngógó ọjà. b (Sáàmù 12:5) Àmọ́ ní báyìí, àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro àìrówóná. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àwọn àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná” àti “Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó.”

a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.

b Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ìdí tó o fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì, wo àpilẹ̀kọ náà “Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì, Ó sì Ṣeé Gbára Lé.”