Ìgbà Wo La Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Afẹ̀míṣòfò?
Táwọn afẹ̀míṣòfò bá ṣọṣẹ́, ó ṣeé ṣe kó o máa ṣe kàyéfì pé: ‘Ṣé Ọlọ́run tiẹ̀ rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí? Kí ló dé tírú àwọn nǹkan báyìí fi ń ṣẹlẹ̀? Ìgbà wo la máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn afẹ̀míṣòfo a? Kí lá jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀ láìka gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí sí?’ Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí lọ́nà tó ń fini lọ́kàn balẹ̀.
Ṣé inú Ọlọ́run ń dùn sáwọn tó ń fẹ̀mí ṣòfò?
Ọlọ́run kórìíra ìwà ipá àti fífi ẹ̀mí èèyàn ṣòfò. (Sáàmù 11:5; Òwe 6:16, 17) Jésù tí Ọlọ́run rán wá sáyé náà bá àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ wí nígbà tí wọ́n fa idà yọ láti gbèjà Jésù. (Mátíù 26:50-52) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan máa ń sọ pé Ọlọ́run fọwọ́ sí báwọn ṣe ń pààyàn, àmọ́ Ọlọ́run ò fọwọ́ sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Kódà, Ọlọ́run kì í tẹ́tí sí àdúrà wọn.—Àìsáyà 1:15.
Ó máa ń dun Ọlọ́run tó bá rí àwọn tó ń jìyà, títí kan àwọn táwọn afẹ̀míṣòfò ṣe lọ́ṣẹ́. (Sáàmù 31:7; 1 Pétérù 5:7) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa tó fòpin sí ìwà ipá.—Àìsáyà 60:18.
Ohun tó fà á táwọn kan fi máa ń fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò
Bíbélì sọ ohun tó fa ìwà burúkú yìí, ó ní: “Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ọjọ́ pẹ́ táwọn tó wà nípò àṣẹ ti máa ń lo ọwọ́ agbára àti ìwà ipá láti tẹ àwọn èèyàn lórí ba. Bójọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn tí wọ́n ń jẹ gàba lé lórí lè yarí, wọ́n sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn èèyàn kí wọ́n lè fi ìhónú hàn.—Oníwàásù 7:7.
Ìgbà tá a máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn afẹ̀míṣòfò
Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fòpin sí ìwà ipá àti ìbẹ̀rù, òun á sì mú kí àlàáfíà jọba kárí ayé. (Àìsáyà 32:18; Míkà 4:3, 4) Lára ohun tó máa ṣe ni pé:
Ó máa fòpin sí ohun tó ń mú káwọn èèyàn hùwà ipá. Ọlọ́run máa fi ìjọba ẹ̀ rọ́pò ìjọba èèyàn. Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba náà ò ní ṣojúsàájú tàbí kó gbè sẹ́yìn ẹnì kan, á sì fòpin sí ìnilára àti ìwà ipá. (Sáàmù 72:2, 14) Tó bá dìgbà yẹn, kò sẹ́ni táá máa hùwà ipá mọ́. Bíbélì sọ pé: “Inú [àwọn èèyàn] yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.
Ó máa mú gbogbo ohun tí ìwà ipá ti fà kúrò. Gbogbo àwọn táwọn afẹ̀míṣòfò ti ṣe léṣe ni Ọlọ́run máa mú lára dá, á sì pẹ̀tù sọ́kàn àwọn tí wọ́n ti kó ẹ̀dùn ọkàn bá. (Àìsáyà 65:17; Ìfihàn 21:3, 4) Ó tún ṣèlérí pé òun máa jí àwọn tó ti kú díde, wọ́n á sì gbádùn àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 5:28, 29.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọlọ́run á fi ṣe àwọn nǹkan yìí. Àmọ́ o lè máa ronú pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run fi ń dúró kó tó fòpin sí ìwà burúkú yìí?’ Kó o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè ẹ, wo fídíò náà Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?
a “Àwọn afẹ̀míṣòfò” làwọn tó máa ń hùwà ipá sáwọn èèyàn, tí wọ́n sì máa ń kó ìpayà bá àwọn aráàlú, torí pé wọ́n fẹ́ kí ìyípadà wáyé lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ìsìn tàbí àwọn nǹkan míì láwùjọ. Àmọ́, táwọn kan bá hùwà ipá, ẹnu àwọn èèyàn kì í kò lórí bóyá afẹ̀míṣòfò ni wọ́n tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.