Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Kí Nìdí Tí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú Fi Túbọ̀ Ń Mú Káwọn Èèyàn Kẹ̀yìn Síra?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Ọ̀rọ̀ òṣèlú ti mú káwọn èèyàn kẹ̀yìn síra wọn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kárí ayé. Nínú ìwádìí kan tí Pew Research Center ṣe lọ́dún 2022, wọ́n rí i pé “ohun tó ju ìdajì àwọn èèyàn ní orílẹ̀-èdè mọ́kàndínlógún (19) ló sọ pé àwọn èèyàn tó wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè àwọn sábà máa ń bá ara wọn jiyàn gan-an, wọn kì í sì í fẹ́ rí imí ara wọn láàtàn.”
Ṣé ìwọ náà ti kíyè sí i pé ọ̀rọ̀ òṣèlú túbọ̀ ń mú káwọn èèyàn kẹ̀yìn síra wọn ládùúgbò tó ò ń gbé? Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? Ṣé ojútùú wà sí ìṣòro yìí? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ.
Ìdí tí kò fi sí ìṣọ̀kan
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìyẹn àkókò wa yìí, ìwà tọ́pọ̀ èèyàn á máa hù á mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti wà níṣọ̀kan.
“Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira. Torí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, . . . wọ́n á jẹ́ . . . kìígbọ́-kìígbà.”—2 Tímótì 3:1-3.
Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ ń kọ́wọ́ ti ìjọba kí wọ́n lè mú káwọn aráàlú ṣera wọn lọ́kan, kí ìlú sì tòrò, síbẹ̀ pàbó ni ìsapá wọn ń já sí. Ó máa ń ṣòro fáwọn tí èrò wọn yàtọ̀ síra láti ṣiṣẹ́ pa pọ̀, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti yanjú àwọn ìṣòro kan. Ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti sọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀.
“Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.
Àmọ́, Bíbélì sọ bí ìṣòro yìí ṣe máa yanjú. Ó sọ pé ìjọba kan máa tó dé, ẹnì tó sì lágbára láti yanjú ìṣòro tá à ń bá yí lónìí ló máa jẹ́ alákòóso ìjọba náà.
Alákòóso kan tó kúnjú ìwọ̀n tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù Kristi lẹni tó kúnjú ìwọ̀n láti ṣàkóso àwa èèyàn. Ìdí ni pé ó lágbára, ó ní ọ̀la àṣẹ, ó sì ń wù ú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà láàárín gbogbo èèyàn.
“Ní àkókò rẹ̀, àwọn olódodo yóò gbilẹ̀, àlàáfíà yóò sì gbilẹ̀.”—Sáàmù 72:7.
“Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa sìn ín.”—Sáàmù 72:11.
Jésù gan-an lẹni tó yẹ kó jẹ́ alákòóso wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ pàápàá àwọn tí wọ́n ti fọwọ́ ọlá gbá lójú.
“Yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀, yóò sì gba tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Yóò ṣàánú aláìní àti tálákà, yóò sì gba ẹ̀mí àwọn tálákà là. Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”—Sáàmù 72:12-14.
O ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba tí Jésù jẹ́ alákòóso rẹ̀. Kó o sì tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa àǹfààní tí ìjọba yẹn máa ṣe ẹ́ àti bó o ṣe lè fi hàn pé ìjọba náà lo fara mọ́.
Wo fídíò náà Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
Ka àpilẹ̀kọ náà “Ijoba Olorun, Ijoba To Bo Lowo Iwa Ibaje.”