Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Rui Almeida Fotografia/Moment via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Wàhálà Tí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú Ń Dá Sílẹ̀ Kárí Ayé​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Wàhálà Tí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú Ń Dá Sílẹ̀ Kárí Ayé​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Ìjà àti rògbòdìyàn túbọ̀ ń wáyé torí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ìyẹn ò sì jẹ́ kọ́kàn àwọn èèyàn balẹ̀.

  •   Lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, wọ́n pa mọ́kàndínlógójì (39) lára àwọn olóṣèlú tó fẹ́ gbégbá ìbò, iye yẹn ló sì tíì pọ̀ jù látìgbà tí wọ́n ti ń dìbò. Yàtọ̀ síyẹn, ìlú ò fara rọ torí wàhálà tọ́rọ̀ òṣèlú ń dá sílẹ̀, ìyẹn ò sì jẹ́ kọ́kàn àwọn èèyàn balẹ̀ lásìkò ìdìbò ọdún 2023-2024.

  •   Nílẹ̀ Yúróòpù, wàhálà tọ́rọ̀ òṣèlú ń dá sílẹ̀ kọjá àfẹnusọ. Kódà, wọ́n gbìyànjú láti pa olórí ìjọba orílẹ̀-èdè Slovakia ní May 15, 2024.

  •   Ẹnu ya ọ̀pọ̀ èèyàn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà tẹ́nì kan gbìyànjú láti pa Donald Trump tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè náà tẹ́lẹ̀ ní July 13, 2024.

 Kí nìdí tí wàhálà tọ́rọ̀ òṣèlú ń fà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ìgbà wo ló máa dópin? Kí ni Bíbélì sọ?

Ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú

 Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn èèyàn ò ní ṣeé bá ṣe àdéhùn, wọ́n á sì tún máa hùwà ipá. Ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí gan-an nìyẹn.

  •   ’Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira. Torí àwọn èèyàn máa jẹ́ aláìmoore, aláìṣòótọ́, kìígbọ́-kìígbà, ẹni tó burú gan-an, ọ̀dàlẹ̀, alágídí, ajọra-ẹni-lójú.’​—2 Tímótì 3:1-4.

 Bíbélì tún sọ pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn èèyàn á máa ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, rògbòdìyàn á sì máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn olóṣèlú. (Lúùkù 21:9, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Àmọ́, ṣé gbogbo àwọn wàhálà yìí máa dópin? Bẹ́ẹ̀ ni.

Wàhálà tí ọ̀rọ̀ òṣèlú ń fà máa tó dópin láìpẹ́

 Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa gbé ìjọba tiẹ̀ kalẹ̀ èyí tó máa rọ́pò àwọn ìjọba èèyàn.

  •   “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀ . . . ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú, ó máa fòpin sí gbogbo wọn òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.”​—Dáníẹ́lì 2:44.

 Tí ìjọba Ọlọ́run bá dé, gbogbo èèyàn máa wà níṣọ̀kan, àlàáfíà sì máa wà kárí ayé.

  •   Bíbélì pe Jésù tó máa jẹ́ Ọba ìjọba náà ní “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” ó sì máa rí i dájú pé ‘àlàáfíà kò ní lópin’ nínú ìjọba rẹ̀.​—Àìsáyà 9:6, 7.

  •   Ní báyìí, àwọn tó máa wà nínú ìjọba náà ń kọ́ bí wọ́n á ṣe máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀, wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn. Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”​—Àìsáyà 2:3, 4.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?” kó o sì wo fídíò Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?