Bó O Ṣe Lè Yẹra fún Ọtí Àmujù
Àwọn kan máa ń mu ọtí láti pa ìrònú rẹ́ nítorí ìdánìkanwà, ìdààmú tàbí nítorí pé nǹkan sú wọn. Ṣé ìwọ náà ti ń mu ọtí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe tí oò fi ni máa mu ọtí kọjá àyè tàbí tí ọtí ò fi ní di bárakú fún ẹ? Àwọn ìsọfúnni tó gbéṣẹ́ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe kọjá àyè nídìí ọtí:
Kí ló túmọ̀ sí láti mu ọtí níwọ̀n tó yẹ?
Ohun tí Bíbélì sọ: “Má ṣe wà lára àwọn tó ń mu wáìnì lámujù.”—Òwe 23:20.
Rò ó wò ná: Bíbélì kò sọ pé ó burú téèyàn bá mú ọtí níwọ̀n tó yẹ. (Oníwàásù 9:7) Àmọ́, ó fìyàtọ̀ sáàárin mímu ọtí níwọ̀n, àmujù ọtí àti àmuyíràá. (Lúùkù 21:34; Éfésù 5:18; Títù 2:3) Kódà tí ọtí ò bá tiẹ̀ pani, àmujù ọtí lè mú kéèyàn ṣèpinnu tí kò dáa, ó lè ṣàkóbá fún ìlera, ó sì lè ba àárín àwa àtàwọn ẹlòmíì jẹ́.—Òwe 23:29, 30.
Ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ fìyàtọ̀ sáàárín mímu ọtí níwọ̀nba àti àmujù ọtí, ohun tí wọ́n sì sábà máa ń fi díwọ̀n ẹ̀ ni iye ọtí tẹ́nì kan mu lójúmọ́, àti iye ọjọ́ tó fi ń mu ọtí lọ́sẹ̀ kan. a Àmọ́ ohun kan ni pé bí ọtí ṣe máa ń rí lára oníkalukú yàtọ̀ síra, nígbà míì ohun tó dáa ni pé kéèyàn má ṣe mu ọtí rárá. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé:
“Kódà ìgò kan tàbí méjì lè pọ̀ jù fún ẹ lábẹ́ àwọn ipò yìí:
Tó o bá ń fi ẹ̀rọ ṣiṣẹ́.
Tó o bá lóyún tàbí tí o bá ń fún ọmọ lọ́mú.
Tó o bá ń lo àwọn oògùn kan.
Tó o bá ní àwọn aìsàn kan.
Tó o bá ń gbìyànjú láti jáwọ́ nínú ọtí.”
Bó o ṣe lè mọ̀ tó o bá ti ń mu ọtí jù
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ jẹ́ ká yẹ ọ̀nà wa wò, ká wò ó fínnífínní.”—Ìdárò 3:40.
Rò ó wò ná: Tó o bá ń fiyè sí ìwọ̀n ọtí tó ò ń mu, tó o sì ń ṣe àyípadà tó yẹ déédéé, wàá dáàbò bo ara ẹ lọ́wọ́ àkóbá tí ọtí máa ń fà. Kíyè sí àwọn àmì yìí láti mọ̀ bóyá o ti ń ṣàṣejù nídìí ọtí.
Ọtí nìkan ló máa ń fún ẹ láyọ̀. O gbà pé ọtí lo lè fi tura, lo lè fi ṣe fàájì tàbí tó o lè fi gbádùn ara ẹ. Ọtí lo máa ń fi pa ìrònú rẹ́.
O ti ń mu ọtí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ò ń mutí lóòrèkóòrè. Ọtí líle lò ń mu, ó sì dìgbà tó o bá mu púpọ̀ kí ara tó tù ẹ́.
Ọtí tó ò n mu ti fa ìṣòro fún ẹ ní ilé tàbí níbi iṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ò ń ná owó tó pọ̀ lórí ọtí ju iye tí agbára ẹ ká lọ.
O máa ń ṣe ìpinnu tó léwu lẹ́yìn tó o bá mu ọtí tán, bí wíwa mọ́tò, wíwẹ̀ lódò tàbí fífi ẹ̀rọ ṣiṣẹ́.
Àwọn èèyàn ń kọminú sí bó o ṣe ń mu ọtí. Tí wọ́n bá sọ̀rọ̀, o máa ń ṣàwáwí. O máa ń gbìyànjú kí àwọn míì má bàa mọ̀ pé ò ń mu ọtí tàbí o máa ń purọ́ iye ọtí tó o máa ń mu.
Ó ṣòro fún ẹ láti jáwọ́. O ti gbìyànjú láti dín ọtí tó ò ń mu kù tàbí kó o jáwọ́, àmọ́ oò rí i ṣe.
Àbá márùn-ún tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa mu ọtí jù
1. Ní ìṣètò.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.”—Òwe 21:5.
Gbìyànjú èyí wò: Yan àwọn ọjọ́ tí wàá máa mu ọtí lọ́sẹ̀. Fi gbèdéke sí iye ọtí wàá mu láwọn ọjọ́ náà. Kó o sì yan ó kéré tán, ọjọ́ méjì nínú ọ̀sẹ̀ tó ò ní mu ọtí rárá.
Àjọ kan nílè Gẹ̀ẹ́sì tó ń kọ́ni béèyàn ṣe lè jáwọ́ nínú ọtí sọ pé: “Ọ̀nà kan tó dáa jù tí ọtí ò fi ní di bárakú fúnni ni pé kéèyàn dín iye ọjọ́ tó fi ń mútí kù, kó yéé máa mutí lọ́jọ́ kan tẹ̀ lé òmíì.”
2. Ṣiṣẹ́ lórí ètò tó o ṣe.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ parí ohun tí ẹ ti bẹ̀rẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 8:11.
Gbìyànjú èyí wò: Mọ ìwọ̀n ọtí tó wà, kó o lè fi díwọ̀n bó o ṣe mu ọtí tó. Fi àwọn ohun mímu ẹlẹ́rìndòdò tó lè ṣàǹfààní fún ẹ rọ́pọ̀ rọ́pọ̀ ọtí tó o ti ń mu tẹ́lẹ̀, kó o sì jẹ́ kí wọ́n wà lárọ̀ọ́wọ́tó.
Àjọ tó ń rí sí ìlòkúlò ọtí àti ọtí àmupára nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Àwọn ìsapá kéékèèké tẹ́nì kan ń ṣe lè rà án lọ́wọ́ gan-an láti yẹra fún àwọn ìṣòro tí ọtí máa ń fà.”
3. Dúró lórí ohun tó o pinnu.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́.”—Jémíìsì 5:12.
Gbìyànjú èyí wò: Tẹ́nì kan bá fi ọtí lọ̀ ẹ́, tó o sì ti pinnu pé o fẹ́ jáwọ́ nínú ọtí, má tijú láti sọ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé “Rárá.”
Àjọ tó ń rí sí ìlòkúlò ọtí àti ọtí àmupára nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Bó bá ṣe yá ẹ lára tó láti tètè sọ pé rárá náà ló ṣe máa ṣòro fún ẹ́ tó láti gba ọtí náà.”
4. Àǹfààní tó wà nínú ìpinnu ẹ ni kó o máa rò.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ.”—Oníwàásù 7:8.
Gbìyànjú èyí wò: Ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìdí tó o fi ń sapá láti yẹra fún ọtí àmujù. O lè kọ ọ́ síbẹ̀ pé, o fẹ́ máa sùn dáadáa, o fẹ́ kí ìlera ẹ sunwọ̀n sí i, ó fẹ́ máa ṣọ́wó ná, o sì fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì. Tó o bá ń sọ ìpinnu rẹ fáwọn míì, àǹfààní tí ò ń rí nínú ìpinnu ẹ ni kó o tẹnu mọ́ dípò àwọn ìṣòro ibẹ̀.
5. Bẹ Ọlọ́run pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”—Fílípì 4:13.
Gbìyànjú èyí wò: Tó bá ti ń ṣe ẹ́ bíi pé o ti ń mutí lámujù, bẹ Ọlọ́run pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ lókun àti àgbára láti kó ara rẹ níjàánu. b Kí ìwọ fúnra ẹ sì wáyè láti ka àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó dájú pé Ọlọ́run máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro ọtí mímu.
a Bí àpeerẹ, Ẹ̀ka Tó Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Ìlera ní Amẹ́ríkà sọ pé “tí obìnrin bá mu ọtí mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́jọ́ kan tàbí tó mu ọtí mẹ́jọ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́sẹ̀ kan, ó ti mu àmujù. Bákan náà, tí ọkùnrin bá mu ọtí márùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́jọ́ kan tàbí tó mu ọtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́sẹ̀, ó ti mu ọtí jù.” Ìwọ̀n ọtí yàtọ̀ síra ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan, torí náà, ó ṣe pàtàkì béèrè lọ́wọ́ dọ́kítà rẹ nípa ìwọ̀n ọtí tó yẹ fún ẹ.
b Tó bá wá ṣòro fún ẹ láti borí ọtí mímú, ó lè gba pé kó o wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà.