Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ṣé Lóòótọ́ ni Ìdíje Olympic Lè Mú Kí Ìṣọ̀kan àti Àlàáfíà Wà Kárí Ayé?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Wọ́n fojú bù ú pé àwọn èèyàn tó tó bílíọ̀nù márùn-ún ló máa wo ìdíje Olympic ti ọdún 2024. Àwọn tó máa kópa nínú ìdíje náà wá láti ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mẹ́fà (206) orílẹ̀-èdè. Thomas Bach tó jẹ́ ààrẹ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìdíje Olympic sọ pé: “Ìdíje yìí máa mú káwọn èèyàn kárí ayé wà níṣọ̀kan. Ẹ jẹ́ ká yọ̀, ká sì gbé ìdíje Olympic yìí lárugẹ torí pé ó máa jẹ́ ká wà ní àlàáfíà láìka pé orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ti wá.”
Ṣé ìdíje Olympic lè mú kí aráyé wà níṣọ̀kan? Kí ló lè mú kí ìṣọ̀kan àti àlàáfíà wà kárí ayé?
Ṣé ìdíje yìí lè mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà?
Tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ nípa Olympic ọdún yìí, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìdíje nìkan ló máa wá sọ́kàn àwọn èèyàn. Ìdí ni pé onírúurú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń dá awuyewuye sílẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òṣèlú ló ń jẹ yọ. Lára àwọn ohun tó jẹ yọ ni ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àtàwọn nǹkan míì tó ń fa ìyapa.
Eré ìdárayá téèyàn lè fi najú ló yẹ káwọn ìdíje bí Olympic jẹ́. Àmọ́ ìdíje yìí tún ń gbé ẹ̀mí orílẹ̀-èdè mi lọ̀gá lárugẹ, irú èrò bẹ́ẹ̀ kì í sì í jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà.
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé lásìkò yìí àwọn èèyàn máa ní àwọn ìwà tí kì í jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà. (2 Tímótì 3:1-5) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Á Ṣe Máa Hùwà Lónìí?”
Ohun táá mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà
Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun táá mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà kárí ayé. Ó ṣèlérí pé gbogbo èèyàn láyé máa wà níṣọ̀kan lábẹ́ ìjọba kan tó pè ní “Ìjọba Ọlọ́run.”—Lúùkù 4:43; Mátíù 6:10.
Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba yìí máa mú kí àlàáfíà wà kárí ayé. Bíbélì sọ pé:
“Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀, àlàáfíà yóò sì gbilẹ̀.”—Sáàmù 72:7.
“Yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀ . . . Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”—Sáàmù 72:12, 14.
Lónìí, ẹ̀kọ́ Jésù ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn láti ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mọ́kàndínlógójì (239) ilẹ̀ wà níṣọ̀kan. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti kọ́ bá a ṣe lè wà ní àlàáfíà. Tíwọ náà bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè wà ní àlàáfíà, ka Ilé Ìṣọ́ tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Bá A Ṣe Lè Borí Ìkórìíra.”