Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ṣé Orílẹ̀-Èdè Israel Ni Amágẹ́dọ́nì Ti Máa Bẹ̀rẹ̀?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Bíbélì sọ pé Amágẹ́dọ́nì ni ogun tó máa wáyé láàárín gbogbo ìjọba èèyàn àti Ọlọ́run, kì í ṣe ogun tó máa wáyé lágbègbè kan pàtó.
“Àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹ̀mí èṣù mí sí. . . lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, láti kó wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè. . . . Wọ́n sì kó wọn jọ sí ibi tí wọ́n ń pè ní Amágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.”—Ìfihàn 16:14, 16.
Ọ̀rọ̀ náà “Amágẹ́dọ́nì” wá látinu ọ̀rọ̀ Hébérù náà Har Meghid·dohnʹ, tó túmọ̀ sí “Òkè Mẹ́gídò.” Ìlú kan ní agbègbè Ísírẹ́lì àtíjọ ni Mẹ́gídò jẹ́. Ìyẹn ló jẹ́ kí ọ̀pọ̀ gbà pé orílẹ̀-èdè Israel ni ogun Amágẹ́dọ́nì ti máa jà. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kò sí ibì kankan ní Mẹ́gídò tàbí ní agbègbè tó wà nítòsí ibẹ̀ tó lè gba “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé” àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn.
“Àmì,” tàbí èdè ìṣàpẹẹrẹ ni wọ́n lò nínú ìwé Ìfihàn. (Ìfihàn 1:1) Torí náà, kì í ṣe ibì kan pàtó ni Amágẹ́dọ́nì jẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó máa kárí ayé níbi tí àwọn orílẹ̀-èdè ti máa kó ara wọn jọ láti ta ko Ìjọba Ọlọ́run.—Ìfihàn 19:11-16, 19-21.