Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

sinceLF/E+ via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ta Ló Máa Gba Àwọn Aráàlú?​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Ta Ló Máa Gba Àwọn Aráàlú?​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ pé:

  •   Láti October 7 sí October 23, 2023, ìjà tó wáyé láàárín ìlú Gaza àti Israel ti gbẹ̀mí àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (6,400), ohun tó sì tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ọgọ́rùn-ún méjì (15,200) ló ti fara pa. Ohun tó dunni jù ni pé àwọn aráàlú tí ò mọwọ́ mẹsẹ̀ ló pọ̀ jù nínú àwọn tó kàgbákò yìí. Kò tán síbẹ̀ o, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló ti sá kúrò nílùú nítorí ogun yìí.

  •   Láti ìgbà tí ogun tó wáyé láàárín Rọ́ṣíà àti Ukraine ti bẹ̀rẹ̀, títí di September 24, 2023, àwọn aráàlú Ukraine tó ti kú tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án àti ọgọ́rùn-ún méje ó lé kan (9,701), àwọn tó sì ti fara pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún àti ọgọ́rùn-ún méje ó lé mejìdínláàádọ́ta (17,748).

 Kí ni Bíbélì sọ tó máa fi àwọn tí ogun ń hàn léèmọ̀ lọ́kàn balẹ̀?

Ohun tó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀

 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run máa “fòpin sí ogun kárí ayé.” (Sáàmù 46:9) Ó máa fi Ìjọba ẹ̀ rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn. (Dáníẹ́lì 2:44) Kò sí àní-àní pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú kára tu gbogbo èèyàn.

 Lára ohun tí Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe nìyí:

  •   “Yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀, yóò sì gba tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Yóò ṣàánú aláìní àti tálákà, yóò sì gba ẹ̀mí àwọn tálákà là. Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”​—Sáàmù 72:12-14.

 Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti fòpin sí ogun àti ìwà ipá, á sì mára tu gbogbo àwọn tí ogun àti rògbòdìyàn tí kó ìnira bá.

  •   “Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”​—Ìfihàn 21:4.

 Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa tún ayé ṣe. Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé lásìkò wa yìí, àá máa gbọ́ nípa ‘àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun.’ (Mátíù 24:6) Èyí àtàwọn nǹkan míì tó ń ṣẹlẹ̀ jẹ́ kó hàn gbangba pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ìjọba èèyàn la wà yìí.​—2 Tímótì 3:1.