Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Wọ́n Ṣe Pa Ọ̀pọ̀ Èèyàn Nípakúpa Títí Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Wọ́n Ṣe Pa Ọ̀pọ̀ Èèyàn Nípakúpa Títí Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

 Ní January 27, 2023, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣèrántí ọjọ́ tí wọ́n pa àwọn Júù àtàwọn èèyàn míì nípakúpa. Ayẹyẹ yìí ni wọ́n ń pè ní International Holocaust Remembrance Day. Ìwà ìkà tó burú jáì tó wáyé ní ohun tó lé ní ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) sẹ́yìn yìí, lè jẹ́ kó o máa ronú pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìpakúpa bí èyí.

 Àwọn Júù ni wọ́n jìyà jù nígbà ìpakúpa náà. Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù wọn ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ pa. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn míì ni wọ́n tún ṣenúnibíni sí tí wọ́n sì pa nípakúpa. Lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣenúnibíni sí nítorí ìgbàgbọ́ wọn.

“Ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan”

 Ọ̀pọ̀ lẹ̀rù ń bà, torí wọ́n rò pé irú ìpakúpa yẹn tún lè ṣẹlẹ̀. Àmọ́ ìròyìn ayọ̀ kan rèé, Bíbélì ṣèlérí pé lọ́jọ́ iwájú irú ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí ò tún ní wáyé mọ́.

  •   “‘Nítorí mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa,’ ni Jèhófà wí, ‘èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’”​—Jeremáyà 29:11. a

 Ìlérí yìí kì í ṣe àlá tí ò lè ṣẹ, torí Jèhófà máa fòpin sí gbogbo aburú yìí, ó sì máa ṣàtúnṣe sí àkóbá tó ti fà fún aráyé. Láìpẹ́ ó máa:

 Ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ á sì jẹ́ kó o nírètí. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, a rọ̀ ẹ́ pé kó o jẹ́ kẹ́nì kan ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.​—Sáàmù 83:18.