Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Àwọn Èrọ Tó Ń Gbé Ohùn àti Fídíò Jáde Ń Mú Ká Túbọ̀ Gbádùn Àwọn Àpéjọ Wa

Àwọn Èrọ Tó Ń Gbé Ohùn àti Fídíò Jáde Ń Mú Ká Túbọ̀ Gbádùn Àwọn Àpéjọ Wa

JULY 1, 2024

 Ó ti lé ní àádóje (130) ọdún báyìí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń pé jọ fún àwọn àpéjọ agbègbè tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. Lára àwọn ohun tá a máa ń gbádùn níbẹ̀ làwọn àwọn àsọyé tó lé lógójì (40), orin,ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, àtàwọn fídíò lónírúurú. Káwọn èèyàn tó lè gbádùn àwọn àpéjọ yìí dáadáa, wọ́n gbọ́dọ̀ ‘gbọ́ ọ ketekete, kí wọ́n sì rí i’ kedere. (Lúùkù 2:20) Báwo la ṣe ń lo owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètọrẹ káwọn èèyàn lè gbádùn àwọn àpéjọ yìí láìka ibi tí wọ́n ń gbé sí?

A Ṣètò Àwọn Ẹ̀rọ Tó Ń Gbé Ohùn àti Fídíò Jáde Kó Lè Bá Àwọn Ibi Àpéjọ Wa Mu

 Láwọn ìlú òyìnbó, ọ̀pọ̀ pápá ìṣeré àti gbọ̀ngàn ìwòran ló ti máa ń ní àwọn ẹ̀rọ tó ń gbé ohùn àti fídíò jáde. Kí wá nìdí tó fi jẹ́ pé tá a bá fẹ́ lo àwọn gbọ̀ngàn yìí, àwọn ẹ̀rọ tiwa la máa ń kó wá? David tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Ṣe Àtagbà Fídíò Lóríléeṣẹ́ wa sọ pé: “Ìwọ̀nba díẹ̀ nínú àwọn pápá yìí ló ní ẹ̀rọ tó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ tí wọ́n lè lò fún wákátì mẹ́fà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn pápá ìṣeré máa ń ní àwọn ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí wọ́n lè fi ṣe àwọn ìfilọ̀ ṣókí, kí wọ́n sì gbé ohùn orin ránpẹ́ sórí afẹ́fẹ́. Wọ́n tún máa ń ní tẹlifíṣọ̀n ńlá tí wọ́n fi ń gbé àmì ìdíje tó ń lọ tàbí ìpolówó ọjà àtàwọn nǹkan míì sáfẹ́fẹ́. Àmọ́ láwọn àpéjọ wa, ọ̀pọ̀ àwọn fídíò tó gùn la máa ń wò, a sì máa ń fẹ́ kí àwùjọ gbọ́ ohun tí alásọyé ń sọ látorí pèpéle ketekete kí wọ́n sì lóye ẹ̀.”

 Àwọn ibi tá a máa ń lò fáwọn àpéjọ wa máa ń yàtọ̀ síra, torí náà bá a ṣe máa to àwọn ẹ̀rọ tá à ń lò náà máa ń yàtọ̀ síra. Gbàrà tá a bá ti mọ pápá ìṣeré tá a fẹ́ lò ni Ẹ̀ka Tó Ń Ṣe Àtagbà Fídíò láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ti máa wo iye èèyàn tí pápá náà lè gbà, iye èèyàn tá a pè àti ibi tí wọ́n máa jókòó sí. Èyí máa jẹ́ kí àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ náà mọ ibi tí wọ́n máa gbé ẹ̀rọ tó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ àtàwọn tẹlifíṣọ̀n sí, wọ́n á sì mọ bí wọ́n ṣe máa to gbogbo ẹ̀ pọ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ohun tí wọ́n nílò káwọn àwùjọ lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ ketekete kí wọ́n sì rí àwọn fídíò náà kedere.

Àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Ṣe Àtagbà Fídíò (LBD) ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìsọfúnni tó wà fún iṣẹ́ wọn

 Kì í rọrùn láti ṣètò àwọn ẹ̀rọ tá a máa ń lò láwọn àpéjọ tí wọ́n á ti sọ onírúurú èdè. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá máa túmọ̀ àpéjọ náà sí èdè míì, àwọn tó ń ṣe ìtumọ̀ náà gbọ́dọ̀ máa wo fídíò kí wọ́n sì máa gbọ́ ohùn àpéjọ náà. Bí wọ́n bá ṣe ń ṣe ìtumọ̀ náà làwọn amojú ẹ̀rọ á máa ṣe àtagbà ẹ̀ fún àwọn tó ń sọ èdè náà kí wọ́n lè lóye ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ. A dúpẹ́ pé ìmọ̀ ẹ̀rọ ti tẹ̀ síwájú gan-an. Èyí jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti gbé ohùn àti fídíò sáfẹ́fẹ́ láwọn àpéjọ tí wọ́n tí ń tú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí onírúurú èdè, kálukú á sì máa gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ketekete kódà kó jẹ́ èdè mẹ́jọ ni wọ́n ń túmọ̀ rẹ̀ sí. David sọ pé: “Àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé yìí díjú gan-an, ó sì máa gba pé kí wọ́n dá àwọn tó bá fẹ́ lò ó lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa.”

 Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ló ní àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò lọ́dọọdún. Làwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì yìí, àwọn arákùnrin kan máa ṣètò bá a ṣe máa kó àwọn ẹ̀rọ yẹn láti àpéjọ kan lọ sí àpéjọ míì. Ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-un méjì dọ́là ($200,000) a là ń ná lọ́dọọdún láti fi kó àwọn ẹ̀rọ yìí láti àpéjọ kan lọ sí òmíì. Owó yìí kéré tá á bá fi wéra pẹ̀lú owó tó máa ná wa tá a bá ní ká ra àwọn ẹ̀rọ yìí fún ibi àpéjọ kọ̀ọ̀kan. Steven tó jẹ́ alábòójútó àwọn tó ṣètò ẹ̀rọ tó ń gbé ohun àti fídíò jáde ní àpéjọ kan ní Kánádà sọ pé: “Gbogbo àwọn tá a jọ ṣiṣẹ́ rí i dájú pé ohunkóhun ò sọnù lára àwọn ohun èlò náà, wọ́n sí tójú ẹ̀ dáadáa kí wọ́n lè rí i lò ní àpéjọ tó kàn.”

Bá A Ṣe Ń Rí Àwọn Ẹ̀rọ Tá À Ń Lò Tá A sì Ń Bójú Tó Wọn

 Tá a bá ní ká lọ rẹ́ǹtì àwọn ẹ̀rọ tá a fẹ́ lò, owó tá a máa ná ti máa pọ̀ jù. Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í tọ́jú àwọn ẹ̀rọ yìí dáadáa àti pé wọn kì í ṣiṣẹ́ bá a ṣe fẹ́. Torí náà, ṣe la máa ń ra ti wa. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún dọ́là ($24,000) ni wọ́n ń ta èrọ tó ń gbé fídíò jáde tó gùn tó mítà márùn-ún, tó sì fẹ̀ tó mítà mẹ́ta, okùn makirofóònù tí ò gùn ju mítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ni wọ́n ń tà ní ogún dọ́là ($20). Ẹ̀ka Tó Ń Ṣe Àtagbà Fídíò máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Rajà, wọ́n á sì ‘ṣírò ohun tó máa ná’ wa kí wọ́n tó ra ẹ̀rọ èyíkéyìí. (Lúùkù 14:28) Bí àpẹẹrẹ, wọ́n á béèrè pé, èèyàn mélòó ni ẹ̀rọ yìí máa ṣe láǹfààní? Ṣó pọn dandan ká ra tuntun? Ṣé a ní ibi tá a máa tọ́jú wọn sí? Ṣé a ní àwọn tó máa lè tún wọn ṣe?

 Kí àwọn ẹ̀rọ yìí lè lálòpẹ́, ká sì tún dín ìnáwó kù, a máa ń tún wọn ṣe látìgbàdégbà. Tá a bá fẹ́ kó wọn láti ibì kan lọ sí ibòmíì, a máa ń kó wọn sínú ohun kan tó nípọn dáadáa kí wọ́n má bàa bà jẹ́. Tá a bá sì kíyè sí pé ohun tá à ń kó wọn sí nílò àtúnṣe, a máa ń tún wọn ṣe láìjáfara.

Bá a ṣe ń bójú tó àwọn ẹ̀rọ tó ń gbóhùn àti fídíò sáfẹ́fẹ́ tá a sì ń tún wọ́n ṣe ń jẹ́ kí wọ́n lálòpẹ́

Bá A Ṣe Ń Gbé Ohùn àti Fídíò Jáde Ń Jẹ́rìí Fáwọn Èèyàn

 Bí ohùn àti fídíò tá à ń gbé sáfẹ́fẹ́ ṣe ń jáde kedere láwọn àpéjọ wa máa ya àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ kan tó gbajúmọ̀ sọ pé ohùn àti àwòrán tá a gbé sáfẹ́fẹ́ jọ òun lójú gan-an. Arákùnrin Jonathan tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣètò ẹ̀rọ tó ń gbé ohùn àti fídíò jáde láwọn àpéjọ wa sọ pé: “Ó ya ọkùnrin náà lẹ́nu nígbà tó gbọ́ pe gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka yìí kì í ṣe akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, àti pé wọ́n kàn yọ̀ǹda ara wọn ni. Ó tún sọ pé ó máa gba ilé iṣẹ́ tóun ti ń ṣiṣẹ́ ní odindi ọjọ́ márùn-ún gbáko láti ṣètò gbogbo ẹ̀rọ táwa fi ọjọ́ kan àtààbọ̀ péré ṣètò.” Ẹni tó ń bójú tó pápá ìṣeré kan tá a ti ṣe àpéjọ wa sọ pé: “Ọ̀pọ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nídìí iṣẹ́ orin àti fídíò ló ti wá lo ibí, àmọ́ tó bá kan bẹ́ ẹ ṣe ṣètò àwọn ẹ̀rọ tẹ́ ẹ lò, kò sẹ́lẹgbẹ́ yín!”

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń gbádùn àpéjọ kan

 Ṣé bí ohùn àti fídíò ṣe ń jáde dáadáa láwọn àpéjọ wa ti ṣe ẹ́ láǹfààní? Ó lè ṣe ẹ́ bíi ti David tó ń gbé ní England. Ó sọ pé: “Ẹni ọdún méjìdìnláàádọ́rùn-ún (88) ni mí, àti kékeré ni mo ti máa ń lọ sáwọn àpéjọ wa. Àmọ́ ní báyìí, ó rọrùn fún mi láti pọkàn pọ̀ torí àwọn fídíò yẹn ṣe kedere gbogbo ètò sì ń lọ bó ṣe yẹ, a sì ń gbọ́ wọn ketekete.” Micheal tó ń gbé ní Nàìjíríà náà sọ pé: “Àwọn ará túbọ̀ ń pọkàn pọ̀, wọ́n sì ń gbádùn àwọn àpéjọ wa torí pé wọ́n ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àpéjọ náà ketekete, wọ́n sì ń rí àwọn fídíò kedere.”

 Torí náà, tó o bá lọ sí àpéjọ agbègbè tàbí Àkànṣe Àpéjọ Agbègbè “Ẹ Máa Kéde Ìhìn Rere”! tọdún yìí, fara balẹ̀ ronú nípa ìsapá tí wọ́n ti ṣe ká lè gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àpéjọ náà ketekete ká sì wo àwọn fídíò. Àwọn ọrẹ tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́ fún iṣẹ́ kárí ayé títí kan èyí tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́ látorí ìkànnì donate.pr418.com ló mú kí èyí ṣeé ṣe. A mọrírì ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín, ẹ ṣeun gan-an.

a Gbogbo dọ́là tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí ló jẹ́ owó dọ́là ti Amẹ́ríkà.