BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ
Àwọn Ará Ń Gbádùn Tẹlifíṣọ̀n JW Láwọn Ibi Tí Ò Ti Sí Íńtánẹ́ẹ̀tì
APRIL 1, 2021
Oṣooṣù la máa ń fojú sọ́nà láti wo ètò tẹlifíṣọ̀n JW. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa nílẹ̀ Áfíríkà ni ò láǹfààní láti wa ètò yìí jáde lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí nìdí?
Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ibi nílẹ̀ Áfíríkà ni ò ti sí íńtánẹ́ẹ̀tì. Láwọn ibi tó bá sì wà, ó lè má ṣiṣẹ́ dáadáa tàbí kó wọ́nwó. Bí àpẹẹrẹ, alábòójútó àyíká kan ní Madagascar ná ohun tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́fà náírà (6,000) láti wa ètò tẹlifíṣọ̀n JW toṣù kan jáde, ìyẹn sì ju iye owó táwọn míì ń gbà lọ́sẹ̀!
Láìka àwọn ìṣòro yìí sí, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa nílẹ̀ Áfíríkà ti ń gbádùn ètò tẹlifíṣọ̀n JW láìlo íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí ló mú kíyẹn ṣeé ṣe?
Àtọdún 2017 la ti ń tàtagbà ètò tẹlifíṣọ̀n JW sáwọn ará tó wà ní gúúsù aṣálẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà kí wọ́n lè máa rí i wò ní tààràtà látorí tẹlifíṣọ̀n wọn. Èdè mẹ́rìndínlógún (16) la fi ń gbé e jáde, àwọn ará ò kì í sanwó kí wọ́n tó wò ó, kò sì sígbà tí wọn ò lè rí i wò.
Kíyẹn lè ṣeé ṣe, a sanwó fún ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan kí wọ́n lè máa bá wa gbé àwọn fídíò wa sáfẹ́fẹ́. Wọ́n ṣe é lọ́nà tó fi jẹ́ pé àwọn ará á lè rí i wò lórílẹ̀-èdè márùndínlógójì (35) lápá gúúsù aṣálẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà. Oṣooṣù là ń san ohun tó ju mílíọ̀nù mẹ́rin ààbọ̀ náírà (4,500,000) fún ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n tó ń gbé ètò náà jáde. Yàtọ̀ síyẹn, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tá a bá fẹ́ káwọn ará wo ètò pàtàkì kan, a máa ń san àfikún owó káwọn ará lè máa rí i wò lórí tẹlifíṣọ̀n wọn nígbà tá a bá ń ṣe ètò náà lọ́wọ́. Ìyẹn máa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbádùn àwọn àpéjọ àtàwọn ètò tá a máa ń ṣe nígbà táwọn aṣojú ètò Ọlọ́run bá ń bẹ ẹ̀ka ọ́fíìsì kan wò.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń wo àwọn fídíò tá à ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n JW, títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, àwọn ará wa kan ò lówó tí wọ́n á fi ra àwọn nǹkan tí wọ́n lè fi wo tẹlifíṣọ̀n rárá. Ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́, a fi ẹ̀rọ sátẹ́láìtì tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti àádọ́rin (3,670) ránṣẹ́ sáwọn ìjọ kan, ìyẹn sì jẹ́ káwọn ará láǹfààní láti máa wo ètò tẹlifíṣọ̀n JW nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. A máa ń ná ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n náírà (27,000) láti ra ẹ̀rọ sátẹ́láìtì àti láti fi ránṣẹ́ sáwọn ìjọ. Àmọ́ àwọn ìjọ kan ò ní ohun tó ń gbé àwòrán jáde, torí náà a máa ń ná ohun tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì náírà (200,000) láti ra ẹ̀rọ náà àti ohun tó ń gbé àwòrán jáde ránṣẹ́ sí irú ìjọ bẹ́ẹ̀.
Àwọn ará mọyì ètò tá a ṣe yìí gan-an. Alàgbà kan lórílẹ̀-èdè Cameroon sọ pé: “Ṣe ni tẹlifíṣọ̀n JW dà bíi mánà nínú aginjù fún èmi àti ìdílé mi.” Arákùnrin Odebode, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Nigeria sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀ lèmi àti ìdílé mi máa ń wo tẹlifíṣọ̀n yìí. Ṣe làwọn ọmọ mi máa ń fojú sọ́nà láti wò ó. Kódà láwọn ìgbà míì, wọ́n máa ń sọ pé ká yí tẹlifíṣọ̀n síbi tá a ti ń wo ètò náà.” Arábìnrin Rose tóhun náà ń gbé lórílẹ̀-èdè Nigeria sọ pé: “Inú mi ń dùn báyìí, torí pé tẹlifíṣọ̀n JW ni mo máa ń wò dípò tí màá fi máa gbọ́ ìròyìn ní gbogbo ìgbà. Láwọn ìgbà tí mo ṣì máa ń gbọ́ ìròyìn dáadáa, ohun tí mó máa ń gbọ́ máa ń jẹ́ kí nǹkan tètè sú mi, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ìfúnpá mi ga. Àmọ́, ṣe làwọn nǹkan tí mò ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n JW máa ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀, ó sì máa ń jẹ́ kára tù mí! Ẹ̀bùn àtàtà ni látọ̀dọ̀ Jèhófà. Mo fẹ́ràn ẹ̀ gan-an.”
Alábòójútó àyíká kan lórílẹ̀-èdè Mozambique sọ pé àwọn ìjọ tó wà láyìíká tóun ti ń sìn ti ní ẹ̀rọ tí wọ́n lè fi máa wo tẹlifíṣọ̀n JW. Torí náà, àwọn ará máa ń dé Gbọ̀ngàn Ìjọba ní wákàtí kan kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ kí wọ́n lè wo ètò tẹlifíṣọ̀n JW.
Nígbà tá a ṣe àpéjọ àgbáyé 2019 ní Johannesburg, lórílẹ̀-èdè South Africa, a fi tẹlifíṣọ̀n yìí tàtagbà àwọn àsọyé pàtàkì, títí kan èyí táwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ, ibi mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn ará sì ti wo àsọyé náà. Arákùnrin Sphumelele, tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń tàtagbà fídíò ní ẹ̀ka orílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, orí íńtánẹ́ẹ̀tì la ti máa ń tàtagbà irú àwọn àsọyé yìí. Àmọ́, ìyẹn máa ń gba pé ká ní íńtánẹ́ẹ̀tì tó dáa, á sì ná wa lówó tó pọ̀. Ní báyìí tó jẹ́ pé orí tẹlifíṣọ̀n JW la ti tàtagbà ẹ̀, ìyẹn ti jẹ́ ká náwó níwọ̀nba, ó sì jẹ́ kó rọrùn fáwọn ará láti rí i wò.”
Ìtìlẹyìn tẹ́ ẹ̀ ń ṣe fún iṣẹ́ kárí ayé ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní Áfíríkà láti máa gbádùn tẹlifíṣọ̀n JW. Ọ̀pọ̀ lára ìtìlẹyìn yìí lẹ sì ń fi ránṣẹ́ láti ọ̀kan lára àwọn apá tó wà lórí ìkànnì donate.pr418.com, a mọyì ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín.