Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Àwọn Ará Ṣiṣẹ́ Kára Kí Wọ́n Lè Ṣe Fídíò “Ìhìn Rere Látọ̀dọ̀ Jésù”

Àwọn Ará Ṣiṣẹ́ Kára Kí Wọ́n Lè Ṣe Fídíò “Ìhìn Rere Látọ̀dọ̀ Jésù”

OCTOBER 1, 2024

 Ọ̀kan lára ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fojú sọ́nà fún ní ọdún yìí ni Abala 1 fídíò Ìhìn Rere Látọ̀dọ̀ Jésù. Inú wa dùn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ti wò ó. Èyí sì ni abala àkọ́kọ́ nínú abala méjìdínlógún (18) tí fídíò náà ní. Àwọn nǹkan wo làwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ń ṣe ká lè ṣe fídíò yìí láṣeyọrí, báwo nìwọ náà ṣe ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ yìí?

Bá A Ṣe Bójú Tó Àwọn Tó Ṣe Fídíò

 Ẹ̀ka ọ́fíìsì Australasia la ti ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lára fídíò yìí, nǹkan bí àádọ́ta (50) sí ọgọ́rin (80) èèyàn ló sì máa ń wà níbẹ̀ tá a bá fẹ́ ṣe apá kọ̀ọ̀kan. a A máa ń pèsè oúnjẹ ọ̀sán àti oúnjẹ alẹ́ títí kan ìpápánu fún gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀. Kó tó di ọjọ́ yẹn la ti máa ń ṣètò ohun táwọn tó wà níbẹ̀ máa jẹ. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Esther tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Oúnjẹ sọ pé: “Ká lè rí oúnjẹ tó dáa rà ní ẹ̀dínwó, a máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́jà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bákan náà, àtìgbàdégbà la máa ń yí ọ̀nà tá à ń gbà se oúnjẹ pa dà ká má bàa fi oúnjẹ ṣòfò.” Lójoojúmọ́, a máa ń ná ohun tó tó dọ́là mẹ́rin lórí oúnjẹ ẹnì kọ̀ọ̀kan.

 Kì í ṣe oúnjẹ nìkan làwọn tó wà níbẹ̀ nílò, ó tún yẹ ká dáàbò bò wọ́n. Àmọ́, dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ kí ni? Oòrùn máa ń mú gan-an ní Ọsirélíà, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ooru pọ̀ gan-an. Kí ooru má bàa pa àwọn tó wà níbẹ̀ lára, àwọn tó ń bá ẹ̀ka tó ń ṣe fídíò ṣiṣẹ́ máa ń ṣe àwọn tẹ́ǹtì àtàwọn yàrá kéékèèké tó ní ẹ̀rọ amúlétutù síbi tí wọ́n ti ń ṣe fídíò náà. Bákan náà, wọ́n tún máa ń pèsè omi, agbòjò àtàwọn ìpara tó máa ń dáàbò boni lọ́wọ́ oòrùn. Kevin tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Gbé Ohùn àti Àwòrán Sáfẹ́fẹ́ sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ yìí ló máa ń tilé wá sí Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n nírẹ̀lẹ̀, wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ yìí àtàwọn iṣẹ́ míì tí wọ́n bá ní kí wọ́n ṣe, inú wọn sì máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń ṣe é. Igi lẹ́yìn ọgbà ni wọ́n jẹ́ fún wa.”

Àwọn Ibi Tá A Ti Ń Gba Àwòrán Sílẹ̀

 Tá a bá ní ká ṣe àwọn apá kan fídíò náà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì bóyá ní yàrá tá a ti ń gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀ tàbí ní ìta gbangba, kò ní dà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Nírú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, a máa ń lọ sáwọn ibi tó jìnnà. Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìtàn inú Bíbélì, a máa ń lọ sáwọn ìgbèríko níbi tí kò ti sí òpó iná, títì ọlọ́dà àti àwọn ilé ìgbàlódé. Wọ́n máa wọ aṣọ tó máa jẹ́ kí wọ́n dà bí àwọn èèyàn tó gbé láyé àtijọ́. Ẹnì kan máa kó aṣọ àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò lọ sí ibi tí wọ́n ti máa ṣe fídíò náà, á sì rí i pé gbogbo ẹ̀ wà nípò tó yẹ. Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀, ẹni tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ náà máa rí i dájú pé omi tó dáa, àwọn jẹnẹrétọ̀, àtàwọn ilé ìtura wà ní sẹpẹ́. Àwọn tó ń ṣe fídíò náà máa ń dé sílé àwọn ará tó wà nítòsí, a sì máa ń fi àwọn míì sínú òtẹ́ẹ̀lì, àwọn ilé tí wọ́n ń gbé rìn tàbí àwọn ilé kéékèèké.

Téèyàn bá ń ṣe fídíò níta gbangba, ó máa ń kojú àwọn ìṣòro kan

 Tá a bá ní ká ṣe fídíò náà níta gbangba, ó máa ná wa lówó tó pọ̀, á gba àkókò tó pọ̀, á sì tún tán wa lókun. Torí náà lọ́dún 2023, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká ra ẹ̀rọ kan tó ń gbé fídíò jáde lọ́nà táá fi dà bíi pé a wà ní ibòmíì, ẹ̀rọ yìí ni wọ́n ń pè ní video wall. Ẹ̀rọ yìí ná wa ní mílíọ̀nù méjì àtàbọ̀ dọ́là ($2,500,000). Àǹfààní wo ni ẹ̀rọ yìí máa ṣe wá gan-an? Ó máa jẹ́ kí fídíò tá a bá ṣe hàn dáadáa, á sì tún jẹ́ kó dà bíi pé ìta gbangba la ti ń ṣe fídíò náà. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa jẹ́ ká dín owó tá à ń ná kù. Darren tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Australasia ṣàlàyé pé: “Ẹ̀rọ yìí kì í jẹ́ kó tètè rẹ àwọn tó ń ṣe fídíò, ó tún máa ń jẹ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn apá fídíò kan láṣetúnṣe títí tó fi máa bọ́ sójú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé à ń ṣe fídíò níta gbangba tá a sì nílò oòrùn tó ń wọ̀, ìṣẹ́jú díẹ̀ la ní láti gbà á sílẹ̀ torí pé ká tó ṣẹ́jú pẹ́, oòrùn ti wọ̀. Àmọ́, pẹ̀lú ẹ̀rọ yìí, a lè ṣe ohun tó dà bíi pé oòrùn ń wọ̀, a sì lè tún un ṣe títí tó fi máa rí bá a ṣe fẹ́.”

À ń yẹ video wall tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ rà wò, ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀

‘Kò Jọ Pé Mo Yááfì Nǹkan Kan’

 Nínú abala kọ̀ọ̀kan fídíò Ìhìn Rere, a nílò ọ̀pọ̀ èèyàn tó máa kópa nínú fídíò náà, a sì tún nílò àwọn tó pọ̀ gan-an to máa gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀. Ṣé àwọn arákùnrin àti arábìnrin yìí mọyì gbogbo ohun tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì ṣe fún wọn?

 Ìrìn àjò tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje (700) kìlómítà ni Amber rìn láti ìlú ẹ̀ ní Melbourne kó lè kópa nínú fídíò náà. Ó sọ pé: “Gbàrà tí mo ti sọ̀ kalẹ̀ látinú ọkọ̀ òfuurufú làwọn ará tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti ń bójú tó mi. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló pè mí pé kí n wá sọ́dọ̀ wọn ká jọ jẹun tàbí ká jọ mu tíì. Níbi tá a ti ń ṣe fídíò náà, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ló fìfẹ́ hàn sí mi, ara sì tù mí. Mo dúpẹ́ pé mo wá torí ọ̀pọ̀ ìbùkún ni mo rí. Kò tiẹ̀ jọ pé mo yááfì nǹkan kan!”

 Ẹlòmíì tó sọ bó ṣe rí lára ẹ̀ ni Derek tó wà lára àwọn tó ń gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀. Ó sọ pé: “Àtìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà ni onírúurú ẹ̀ka tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ti ń ràn wá lọ́wọ́. Ìgbàkigbà tí mo bá rántí bí àwọn arákùnrin àti arábìnrin yìí ṣe yọ̀ǹda ara wọn, àkókò wọn, okun wọn àtohun ìní wọn, ṣe ni inú mi máa ń dùn. Wọn ò dá wa dá iṣẹ́ náà, wọ́n tì wá lẹ́yìn, wọ́n sì mára tù wá, kódà wọn ò jẹ́ ká màlá. Ẹ̀gàn ni hẹ̀, Jèhófà bù kún wọn, ó sì bù kún àwa náà. Ó dá mi lójú pé kì í ṣe bóyá a ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ kan ló ṣe pàtàkì sí Jèhófà bí kò ṣe ẹ̀mí tá a fi ṣe iṣẹ́ náà.”

 A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún owó tẹ́ ẹ fi ṣètìlẹyìn, èyí tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti ṣe fídíò yìí. A mọyì ẹ̀ gan-an títí kan èyí tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́ lórí ìkànnì donate.pr418.com.

a Ẹ̀ka ọ́fíìsì Australasia ló ń bójú tó iṣẹ́ wa ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè títí kan Ọsirélíà àti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tó wà ní South Pacific. Ẹ̀ka ọ́fíìsì yìí wà lẹ́yìn ìlú Sydney tó wà ní Ọsirélíà.