Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Àwọn Míṣọ́nnárì Ń Wàásù ní “Ibi Tó Jìnnà Jù Lọ ní Ayé”

Àwọn Míṣọ́nnárì Ń Wàásù ní “Ibi Tó Jìnnà Jù Lọ ní Ayé”

JUNE 1, 2021

 Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fìtara ṣiṣẹ́ yìí. Àmọ́, iṣẹ́ ìwàásù náà ò tíì dé àwọn ibì kan láyé, títí kan àwọn ibi térò pọ̀ sí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò sì pọ̀ láwọn orílẹ̀-èdè míì. (Mátíù 9:37, 38) Báwo la ṣe ń ṣe é ká lè wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn?

 Ká lè ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa yìí, Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yan àwọn míṣọ́nnárì láti wàásù níbi tí àìní wà kárí ayé. Ní báyìí, a ti ní àwọn míṣọ́nnárì tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti àádọ́rùn-ún (3,090) kárí ayé. a Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run tàbí àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run míì. Wọ́n múra tán láti fi ilé wọn sílẹ̀ láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì. Àwọn míṣọ́nnárì yìí nírìírí, òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, wọ́n sì ti gba ìdálẹ́ẹ̀kọ́, torí náà wọ́n máa ń fìtara wàásù, wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn míì.

Àwọn míṣọ́nnárì máa ń wàásù láwọn ibi tí àìní wà

À Ń Bójú Tó Àwọn Míṣọ́nnárì Kí Wọ́n Lè Ran Àwọn Míì Lọ́wọ́

 Ní ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ̀ọ̀kan, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwọn Òjíṣẹ́ Tó Ń Sìn ní Pápá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka láti bójú tó ohun táwọn míṣọ́nnárì nílò. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń ṣètò bí wọ́n á ṣe gbàtọ́jú nílé ìwòsàn, bí wọ́n á ṣe rílé tó mọ níwọ̀n gbé, wọ́n sì máa ń fún wọn ní owó táṣẹ́rẹ́ láti fi bójú tó àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2020, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ́nù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n owó dọ́là láti bójú tó àwọn míṣọ́nnárì. Ohun tí ètò Ọlọ́run ń ṣe yìí mú kó rọrùn fáwọn míṣọ́nnárì láti pọkàn pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kí wọ́n sì lo àkókò wọn láti ran àwọn ará lọ́wọ́.

Àwọn míṣọ́nnárì máa ń ran àwọn ará lọ́wọ́ nínú ìjọ

 Ipa wo làwọn míṣọ́nnárì ń kó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Arákùnrin Frank Madsen tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Màláwì sọ pé: “Torí pé àwọn míṣọ́nnárì nígboyà, tí wọ́n sì jáfáfá, ìyẹn ti ran ọ̀pọ̀ ìjọ lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tó ṣòro, irú bí àwọn agbègbè tó ní géètì àtàwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè míì. Bákan náà, bí wọ́n ṣe máa ń sapá láti kọ́ èdè àti àṣà ìbílẹ̀ ibi tí wọ́n wà máa ń wú àwọn míì lórí, wọ́n sì máa ń fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí láti fayé wọn ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn míṣọ́nnárì yìí jẹ́.”

 Arákùnrin kan tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè míì sọ pé: “Bí àwọn míṣọ́nnárì ṣe múra tán láti lọ sìn ní agbègbè míì fi hàn pé àwa èèyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan kárí ayé. Kódà àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé a ò lẹ́mìí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà pé àwọn ìlànà Bíbélì ti mú ká wà níṣọ̀kan láìka ibi tá a ti wá sí.”

 Báwo làwọn míṣọ́nnárì ṣe ń ran àwọn tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́? Arákùnrin Paulo tó ń gbé ní Timor-Leste mọyì àwọn míṣọ́nnárì tó wá sìn ní ìjọ wọn. Ó sọ pé: “Ojú ọjọ́ máa ń gbóná gan-an nílùú wa. Àmọ́ agbègbè tó tutù làwọn míṣọ́nnárì yẹn ti wá, síbẹ̀ wọ́n máa ń fìtara wàásù láìka ojú ọjọ́ tó gbọ́ná sí. Wọn kì í pa ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá jẹ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń rí wọn lọ́sàn-án gangan nígbà tóòrùn mú ganrí ganrí níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, wọ́n sì máa ń lọ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ nígbà míì. Wọ́n ti kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kódà míṣọ́nnárì lẹni tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́. Bí wọ́n ṣe ń fìtara lo gbogbo okun wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà máa ń mú kó wu àwọn míì nínú ìjọ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.”

 rábìnrin Ketti, tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Màláwì sọ bí tọkọtaya kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì ṣe ran ìdílé ẹ̀ lọ́wọ́, ó ní: “Èmi nìkan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ìdílé mi nígbà tí ètò Ọlọ́run rán àwọn míṣọ́nnárì yẹn wá síjọ wa. Tọkọtaya yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an, wọ́n sì mú àwọn tó kù nínú ìdílé mi lọ́rẹ̀ẹ́. Àpẹẹrẹ wọn ti jẹ́ káwọn ọmọ mi rí i pé téèyàn bá fayé ẹ̀ sin Jèhófà, á láyọ̀, ìgbésí ayé ẹ̀ á sì nítumọ̀. Ní báyìí àwọn ọmọbìnrin mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti di aṣáájú-ọ̀nà déédé, ọkọ mi sì ti ń wá sípàdé. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó fi àwọn míṣọ́nnárì yìí jíǹkí wa.”

 Ibo la ti ń rówó tá a fi ń bójú tó àwọn míṣọ́nnárì yìí? Owó táwọn ará fi ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé la fi ń ṣe é. Ọ̀pọ̀ lára ẹ̀ ni wọ́n sì ń fi ránṣẹ́ láti ọ̀kan lára àwọn apá tó wà lórí ìkànnì donate.pr418.com. A mọyì ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí wọ́n ń fi hàn.

a Ètò Ọlọ́run máa ń rán àwọn míṣọ́nnárì yìí lọ sáwọn ìjọ, kí wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míṣọ́nnárì míì tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ẹyọ kan (1,001) ló jẹ́ alábòójútó àyíká.