Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Ẹ̀rọ Kékeré Tó Ń Mú Kí Ìgbàgbọ́ Àwọn Èèyàn Túbọ̀ Lágbára

Ẹ̀rọ Kékeré Tó Ń Mú Kí Ìgbàgbọ́ Àwọn Èèyàn Túbọ̀ Lágbára

SEPTEMBER 1, 2020

 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti túbọ̀ ń ṣe àwọn ìtẹ̀jáde àtàwọn fídíò sórí ẹ̀rọ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni ò láǹfààní láti gbádùn àwọn nǹkan yẹn, torí pé wọn ò ní owó tí wọ́n máa fi lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn míì ń gbé níbi tí Íńtánẹ́ẹ̀tì ò ti ṣiṣẹ́ dáadáa, láwọn ibòmíì sì rèé, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ló máa ń wá tàbí kó má tiẹ̀ sí rárá.

 Àmọ́ láìka àwọn ìṣòro yìí sí, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ti ń wa àwọn ìwé àtàwọn fídíò jáde lórí ìkànnì báyìí láìlo Íńtánẹ́ẹ̀tì! Báwo nìyẹn ṣe ṣeé ṣe?

 A fi ẹ̀rọ kékeré kan tó ń jẹ́ JW Box ránṣẹ́ sáwọn ìjọ tó wà níbi tí kò ti rọrùn fáwọn ará láti lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ilé iṣẹ́ kan ló bá wa ṣe ẹ̀rọ yìí, wọ́n ṣe é lọ́nà tí àwọn ẹ̀rọ míì á fi lè gba ìsọfúnni látorí ẹ̀. Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Kọ̀ǹpútà ní Bẹ́tẹ́lì wá ṣe ètò ìṣiṣẹ́ kan sórí ẹ̀, wọ́n sì kó àwọn ìtẹ̀jáde àti fídíò tó wà lórí ìkànnì jw.org sí i. A ra ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀rọ yìí ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29,000) náírà.

 Àwọn ará máa ń lo ẹ̀rọ yìí nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n máa ń fi Wi-Fi gba àwọn ìtẹ̀jáde àti fídíò látorí ẹ̀ sínú fóònù wọn. Gbogbo àwọn ará ló ń jàǹfààní ẹ̀rọ yìí, títí kan àwọn tó ń lo fóònù tí kò wọ́nwó àtàwọn tí ètò ìṣiṣẹ́ orí fóònù wọn ti pẹ́. Àmọ́, báwo làwọn ìjọ tó wà láwọn ibi tí kò ti sí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe máa rí àwọn ìtẹ̀jáde tuntun lórí JW Box wọn? Lóòrèkóòrè, ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń kó àwọn ìtẹ̀jáde àtàwọn fídíò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde sórí USB kí wọ́n lè fi ránṣẹ́ sírú àwọn ìjọ bẹ́ẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan USB yìí tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àtààbọ̀ (1,500) náírà.

 Báwo ni JW Box ṣe ń ṣe àwọn ará wa láǹfààní? Bàbá kan tó ń jẹ́ Nathan Adruandra, tó ń gbé ní Democratic Republic of Congo sọ pé: “Ó ti pẹ́ tí mo ti ń gbìyànjú láti ní fídíò ‘Jèhófà, . . . Ìwọ Ni Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé’ àti Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì sórí fóònù mi. Àmọ́ mi ò rí i ṣe, ìyẹn ò sì múnú mi dùn. Ní báyìí, mo ti wa àwọn fídíò yẹn sórí fóònù mi, ìyẹn sì ti jẹ́ kó rọrùn fún èmi àti ìyàwó mi láti túbọ̀ kọ́ àwọn ọmọ wa.”

 Arákùnrin kan tó ti ran ọ̀pọ̀ ìjọ lọ́wọ́ láti lo JW Box lórílẹ̀-èdè Nigeria sọ pé: “Àwọn ará gbà pé ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà ni JW Box jẹ́. Inú wọn dùn gan-an pé ó ti wá rọrùn fún wọn láti wa àwọn ìtẹ̀jáde àtàwọn fídíò tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.”

 Ní báyìí, JW Box tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méje (1,700) la ti fi ránṣẹ́ sáwọn ìjọ tó wà ní Áfíríkà, Oceania àti Amẹ́ríkà ti gúúsù, a sì ti ń ṣètò bá a ṣe máa fi ránṣẹ́ sáwọn ìjọ míì. Ibo la ti ń rówó tá à ń ná sórí àwọn nǹkan yìí? Àwọn ọrẹ tẹ́ ẹ fi ń ti iṣẹ́ kárí ayé lẹ́yìn ló mú kó ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì jẹ́ pé orí ìkànnì donate.pr418.com lẹ ti ń fi ránṣẹ́. Ẹ ṣeun gan-an fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín.