Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Ìwé Tó Ṣe Pàtàkì Jù Nínú Gbogbo Ìwé

Ìwé Tó Ṣe Pàtàkì Jù Nínú Gbogbo Ìwé

JANUARY 1, 2021

 Arákùnrin kan sọ pé: “Ó ti tọ́dún mọ́kàndínlógún (19) tí mo ti ń retí ẹ̀!” Kí ni arákùnrin yìí ń retí? Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Bengali ni. Bó ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn náà nìyẹn tá a bá mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè wọn. Àmọ́, ṣé o ti ronú lórí ohun tó máa ń ná wa ká tó lè túmọ̀ àwọn Bíbélì yìí, ká sì tẹ̀ wọ́n jáde?

 A máa ń kọ́kọ́ yan àwọn atúmọ̀ èdè tó máa ṣiṣẹ́ náà, wọ́n á sì ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Báwo ló ṣe máa ń pẹ́ tó káwọn atúmọ̀ èdè tó parí iṣẹ́ lórí ìtúmọ̀ Bíbélì kan? Arákùnrin Nicholas Ahladis, tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtúmọ̀ ní Warwick, New York sọ pé: “Onírúurú nǹkan ló máa ń pinnu báwọn atúmọ̀ èdè ṣe máa pẹ́ tó lórí iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, iye àwọn atúmọ̀ èdè mélòó ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó? Báwo lèdè náà ṣe nira tó? Ṣé àwọn tó ń sọ èdè náà lóye àwọn àṣà ayé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì? Àti pé, ṣé bí wọ́n ṣe ń sọ èdè náà níbì kan yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́ níbòmíì? Ní ìpíndọ́gba, ó máa ń gba àwọn atúmọ̀ èdè ní ọdún kan sí ọdún mẹ́ta láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gírí ìkì nìkan, ó sì máa ń gbà wọ́n ní ọdún mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láti túmọ̀ odindi Bíbélì. Kódà, ó máa ń pẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ tó bá jẹ́ pé Bíbélì àwọn adití ni wọ́n ń tú.”

 Àwọn atúmọ̀ èdè nìkan kọ́ ló máa ń ṣiṣẹ́ lórí ìtúmọ̀ Bíbélì. Àwọn míì tí àṣà wọn tàbí orílẹ̀-èdè wọn yàtọ̀ síra tún máa ń ṣàyẹ̀wò ìtúmọ̀ Bíbélì náà, wọ́n sì máa ń ṣe iṣẹ́ yìí láìgba nǹkan kan. Àyẹ̀wò táwọn yẹn bá ṣe máa ń ran àwọn atúmọ̀ èdè lọ́wọ́ láti tú Bíbélì náà lọ́nà tó péye, tó rọrùn lóye, tó sì nítumọ̀. Arákùnrin kan tó máa ń dá àwọn tó ń túmọ̀ Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́ lórílẹ̀-èdè South Africa, sọ pé: “Àwọn atúmọ̀ èdè gbà pé iṣẹ́ kékeré kọ́ niṣẹ́ yìí, torí Jèhófà ni wọ́n ń ṣe é fún, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe é lọ́nà táwọn tó ń kà á máa fi lóye ẹ̀ dáadáa.”

 Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí ìtúmọ̀ Bíbélì, wọ́n máa tẹ̀ ẹ́ síwèé, wọ́n á sì dì í pọ̀. Ẹ̀ka tó ń tẹ̀wé máa ń lo oríṣiríṣi nǹkan kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ yìí, irú bíi bébà, yíǹkì, awọ tí wọ́n máa fi bò ó, gọ́ọ̀mù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lọ́dún 2019 nìkan, ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù mẹ́jọ náírà la ná lórí àwọn nǹkan yìí. Ohun tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) wákàtí làwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìtẹ̀wé fi ṣiṣẹ́ láàárín ọdún yẹn kí wọ́n lè tẹ Bíbélì, kí wọ́n sì pín in kiri.

 Kí nìdí tá a fi ń lo àkókò àti owó tó pọ̀ tó yẹn lórí iṣẹ́ yìí? Arákùnrin Joel Blue tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ̀kan lára àwọn ilé ìtẹ̀wé wa sọ pé: “Bíbélì ló ṣe pàtàkì jù nínú gbogbo ìwé tá à ń tẹ̀ jáde. Ìdí nìyẹn tá a fi fẹ́ kó dùn-ún wò, kó lè fògo fún Ọlọ́run tá à ń sìn, kó sì buyì kún iṣẹ́ ìwàásù wa.”

 Yàtọ̀ sí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó wà fún gbogbo èèyàn, a tún máa ń ṣe èyí tó wà fáwọn tó nílò àbójútó àrà ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, a ti ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó wà fáwọn afọ́jú ní èdè mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ká tó lè tẹ odindi Bíbélì yìí jáde, ó máa ń gbà tó wákàtí mẹ́jọ, àá wá ṣe é ní ìdìpọ̀-ìdìpọ̀, tá a bá sì to gbogbo ẹ̀ lórí ará, á ga tó ẹsẹ̀ bàtà méje ààbọ̀ (7.5 ft). Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń ṣe Bíbélì ẹlẹ́yìn bébà fáwọn ẹlẹ́wọ̀n, torí pé wọn kì í gba ìwé tí wọ́n fi awọ bò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

 Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ gan-an. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ nílùú Tombe tó wà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan máìlì sí Kinshasa, tó jẹ́ olú ìlú Democratic Republic of the Congo. Ìjọ kan wà níbẹ̀ tó ń sọ èdè Kiluba, Bíbélì kan ṣoṣo làwọn ará ìjọ yẹn ní, èdè Kiluba àtijọ́, tó ṣòro lóye ni wọ́n sì fi túmọ̀ ẹ̀. Ṣe làwọn ará máa ń pín Bíbélì yẹn lò láàárín ara wọn tí wọ́n bá fẹ́ múra ìpàdé. Àmọ́ láti August 2018, gbogbo àwọn ará ìjọ yẹn ló ti ní Bíbélì tiwọn, torí a ti ṣe odindi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Kiluba tó rọrùn lóye.

 Arábìnrin kan tó ń sọ èdè Jámánì sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe, ó ní: “Dípò tí màá fi máa lé àti ka Bíbélì, ṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé kí n má gbé e sílẹ̀ tí mo bá ti ń kà á.” Ẹlẹ́wọ̀n kan sọ pé: “Ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí i ka Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ni ìgbésí ayé mi ti ń yí pa dà. Nínú gbogbo ìtúmọ̀ Bíbélì tí mo ti ń kà, ìtúmọ̀ Bíbélì yìí ló tíì yé mi jù lọ. Mo fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, á sì wù mí kí n di ọ̀kan lára wọn.”

 Gbogbo àwọn tó ń ka Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ló mọyì ìtìlẹyìn tẹ́ ẹ ṣe ká lè mú Bíbélì náà jáde. Orí ìkànnì donate.pr418.com lẹ sì ti ń fi àwọn ọrẹ yìí ránṣẹ́ láti ti iṣẹ́ kárí ayé lẹ́yìn. Ẹ ṣeun gan-an fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín.

“Bíbélì ló ṣe pàtàkì jù nínú gbogbo ìwé tá à ń tẹ̀ jáde”