Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Ọ́fíìsì Àwọn Atúmọ̀ Èdè Ń Ṣe Ọ̀pọ̀ Láǹfààní

Ọ́fíìsì Àwọn Atúmọ̀ Èdè Ń Ṣe Ọ̀pọ̀ Láǹfààní

MARCH 1, 2021

 Èyí tó ju ìdá mẹ́fà nínú mẹ́wàá àwọn atúmọ̀ èdè ló ti ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè (RTO) báyìí dípò ẹ̀ka ọ́fíìsì. Báwo lètò tá a ṣe yìí ṣe ń ṣe wá láǹfààní? Àwọn nǹkan wo làwọn atúmọ̀ èdè nílò kíṣẹ́ wọn lè máa lọ dáadáa? Báwo nibi tí ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè wà ṣe lè mú kíṣẹ́ ìtúmọ̀ dáa sí i?

 Iṣẹ́ àwọn atúmọ̀ èdè ti túbọ̀ dáa sí i ní báyìí tó ti jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè wọn là ń kọ́ ọ́fíìsì wọn sí. Arábìnrin Karin, tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń túmọ̀ èdè Low German sọ pé: “Látìgbà tá a ti dé Cuauhtémoc, Chihuahua lórílẹ̀-èdè Mexico, ó ti rọrùn gan-an fún wa láti máa sọ èdè Low German. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń sọ ọ́ láàárín ara wa, òun la fi ń wàásù, òun la sì ń sọ tá a bá lọ sọ́jà. A ti túbọ̀ mọ èdè náà sọ dáadáa. A máa ń gbọ́ àwọn àkànlò èdè tá ò kì í gbọ́ ká tó débí, ìyẹn sì ń jẹ́ ká tètè mọ̀ táwọn ọ̀rọ̀ kan bá yí pa dà nínú èdè náà.”

 Arákùnrin James tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń túmọ̀ èdè Frafra lórílẹ̀-èdè Ghana sọ pé: “Òótọ́ ni pé mò ń ṣàárò àwọn ọ̀rẹ́ mi tá a jọ wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì. Àmọ́, mò ń gbádùn bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè yìí. Torí mo láǹfààní láti máa wàásù fáwọn èèyàn ní èdè ìbílẹ̀ wọn, inú mi sì ń dùn bí mo ṣe ń ráwọn tó mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́.”

 Àwọn nǹkan wo ló máa ń pinnu ibi tí ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè máa wà? Ẹ gbọ́ ohun tí Arákùnrin Joseph sọ, Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Kárí Ayé ló ti ń ṣiṣẹ́ ní Warwick, New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó ní: “Ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tá a máa ń ní ni pé láwọn ibì kan kì í fi bẹ́ẹ̀ sí iná, omi tàbí íńtánẹ́ẹ̀tì táwọn atúmọ̀ èdè lè fi ṣiṣẹ́. Torí náà, tá a bá fẹ́ kọ́ ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè, ó lè gba pé ká wo ọ̀pọ̀ ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè náà, ká sì fi wọ́n wéra, ká lè mọ ibi tó dáa jù láti kọ́ ọ́fíìsì náà sí.”

 Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa ń rọrùn jù tí ò sì ní ná wa lówó púpọ̀ ni láti kọ́ ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ, Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ilé àwọn míṣọ́nnárì, káwọn atúmọ̀ èdè lè máa tilé wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Àmọ́, tí ò bá sí ilé ètò Ọlọ́run èyíkéyìí nítòsí ibi tá a fẹ́ kí ọ́fíìsì náà wà, ètò Ọlọ́run lè fọwọ́ sí i pé ká ra ilé, káwọn atúmọ̀ èdè lè máa gbébẹ̀ kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Tó bá sì gba pé káwọn atúmọ̀ èdè kúrò níbẹ̀, ó máa rọrùn láti ta ilé náà ká sì fi owó ẹ̀ ṣe àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì.

Ohun Tí Wọ́n Nílò Kí Wọ́n Lè Máa Báṣẹ́ Lọ

 Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2020, a ná ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù márùn-ún náírà láti bójú tó ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ máa ń lo ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà, ètò orí kọ̀ǹpútà tá a dìídì ṣe fún iṣẹ́ náà, àwọn ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀, íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn nǹkan míì. Ó kéré tán, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́rùn-ún (290,000) náírà la fi ń ṣètò kọ̀ǹpútà atúmọ̀ èdè kọ̀ọ̀kan. A máa ń fi àwọn ètò orí kọ̀ǹpútà tá a sanwó fún àti Watchtower Translation System sórí kọ̀ǹpútà wọn, kó lè rọrùn fún wọn láti ṣiṣẹ́ àti láti ṣèwádìí.

 A tún fún àwọn atúmọ̀ èdè láwọn ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀ tó ṣe é gbé kiri, tí wọ́n lè lò nínú ọ́fíìsì wọn. Àwọn ẹ̀rọ yìí wúlò gan-an nígbà tí àrùn Corona bẹ̀rẹ̀, torí ọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè ló gbé e lọlé, kí wọ́n lè máa báṣẹ́ lọ.

 Àwọn tó wà nítòsí ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè tún máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n ti túmọ̀ àti láti bójú tó àyíká ọ́fíìsì náà. Arákùnrin Cirstin, tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè Afrikaans ní Cape Town lórílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn akéde àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé ló láǹfààní láti ṣiṣẹ́ níbí.”

 Àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn máa ń gbádùn àǹfààní tí wọ́n ní. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè kan sọ pé: “Iṣẹ́ tí mò ń ṣe níbẹ̀ mú kára tù mí gan-an.” Àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tó wà nítòsí máa ń wá sí ọ́fíìsì náà láti gbohùn sílẹ̀. Arábìnrin Juana, tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè Totonac ní Veracruz lórílẹ̀-èdè Mexico sọ pé: “Ní báyìí tá a ti wà níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè wa, ó rọrùn fún wa láti rí ọ̀pọ̀ àwọn ará tá a lè gbohùn wọn sílẹ̀.”

 Àmọ́ ṣé iṣẹ́ ìtúmọ̀ ti dáa sí i látìgbà táwọn atúmọ̀ èdè ti kó lọ sáàárín àwọn tó ń sọ èdè tí wọ́n ń túmọ̀? Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka àwọn ìtẹ̀jáde wa jẹ́ ká mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Arákùnrin Cédric, tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka atúmọ̀ èdè Kongo ní Democratic Republic of Congo sọ pé: “Nígbà kan, àwọn ará máa ń sọ pé èdè àwọ́n ajẹ́rìí là ń tú sínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, torí pé kì í ṣe báwọn tó ń sọ èdè Kongo ṣe sábà máa ń sọ ọ́ la ṣe ń túmọ̀ ẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, àwọn ará ti ń gbádùn àwọn ìtẹ̀jáde wa, torí pé èdè Kongo òde òní là ń túmọ̀.”

 Arákùnrin Andile, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè Xhosa sọ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn ará ní South Africa náà nìyẹn. Ó ní: “Ọ̀pọ̀ ló sọ pé àwọn ti rí ìyàtọ̀ nínú bá a ṣe ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa. Kódà, àwọn ọmọdé tó sábà máa ń ka Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì tẹ́lẹ̀ ti ń kà á lédè Xhosa báyìí. Wọ́n fẹ́ràn láti máa ka Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun torí pé ó rọrùn kà, ó sì rọrùn lóye.”

 Owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti kọ́ ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè, láti tún un ṣe àti láti tọ́jú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, títí kan èyí tẹ́ ẹ̀ ń fi ránṣẹ́ lórí ìkànnì donate.pr418.com.