Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

A Ṣètò Ìrànwọ́ Fáwọn Ará Kárí Ayé Nígbà Àjàkálẹ̀ Àrùn

A Ṣètò Ìrànwọ́ Fáwọn Ará Kárí Ayé Nígbà Àjàkálẹ̀ Àrùn

JULY 1, 2021

 Ní March 2020, Àjọ Ìlera Àgbáyé kéde pé àrùn Corona ti di àjàkálẹ̀ àrùn tó gba ayé kan, ọ̀pọ̀ ni ò sì mọ̀ pé àrùn náà á ṣì máa bá aráyé fínra fún ohun tó lé ní ọdún kan lẹ́yìn náà. Ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àjàkálẹ̀ àrùn náà ti hàn léèmọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ti ṣàkóbá fún ìlera àwọn kan, ó ti fa ẹ̀dùn ọkàn fáwọn míì, ó sì ti mú káwọn nǹkan gbówó lórí. Báwo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ṣètò ìrànwọ́ lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn náà?.

A Ṣètò Ìrànwọ́ Fáwọn Tó Nílò Rẹ̀

 Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé ètò kan kalẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn náà hàn léèmọ̀. Wọ́n ṣètò Ìgbìmọ̀ tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti àádọ́ta (950) táá ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá kárí ayé. Láwọn ibì kan, wọ́n ṣètò báwọn ará tó wà ládùúgbò ṣe lè ṣèrànwọ́, àwọn ibòmíì sì wà táwọn ará jàǹfààní ètò ìrànwọ́ tí ìjọba ṣe. Ìgbìmọ̀ yìí tún máa ń ṣètò ìrànwọ́ láwọn agbègbè tí nǹkan ti ṣòro gan-an fáwọn ará wa.

 Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Paraguay. Ìwé ìròyìn kan sọ pé, “ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Paraguay ni ò rí oúnjẹ jẹ” torí àjàkálẹ̀ àrùn náà. Ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ ní Paraguay wá pín ohun táá kájú àìní ìdílé ọlọ́mọ méjì fún ọ̀sẹ̀ méjì. Lára ohun tí wọ́n fún wọn ni oúnjẹ, ọṣẹ àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò. Tá a bá ṣírò ohun tí wọ́n fún ìdílé kọ̀ọ̀kan, á tó ọgbọ̀n (30) owó dọ́là, ìyẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìlá àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún owó náírà (12,500)

 Báwo làwọn tó ń pèsè ìrànwọ́ ṣe ń dáàbò bo ara wọn àtàwọn míì lọ́wọ́ àrùn Corona? Wọ́n máa ń lo ìbòmú, wọ́n sì máa ń jìnnà sáwọn míì. Wọ́n tún máa ń rí i pé àwọn iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń ra oúnjẹ ń tẹ̀ lé òfin tí ìjọba ṣe nípa béèyàn ṣe lè dáàbò bo ara ẹ̀ lọ́wọ́ àrùn Corona, àti pé ibi tó mọ́ ni wọ́n ti ń ṣètò oúnjẹ náà. Lára ohun tí wọ́n retí pé kí iléeṣẹ́ náà ṣe ni pé káwọn òṣìṣẹ́ wọn máa wọ aṣọ tó ń dáàbò boni lọ́wọ́ kòkòrò àrùn, kí wọ́n sì máa fi ọṣẹ apakòkòrò fọ ọkọ̀ wọn àti ibi tí wọ́n ń tọ́jú oúnjẹ pa mọ́ sí. Yàtọ̀ síyẹn, tí wọ́n bá kó àwọn ohun èlò náà lọ fáwọn ará tó máa gbà á, wọ́n gbọ́dọ̀ jìnnà sí wọn.

Bá A Ṣe Ń Ṣọ́wó Ná

 Látìgbà tí Corona ti bẹ̀rẹ̀ títí di January 2021, Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí ti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n ná ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) owó dọ́là fún ètò ìrànwọ́. Àwọn ìgbìmọ̀ ẹ̀ka àtàwọn tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù máa ń ṣọ́ owó táwọn ará fi ń ṣètọrẹ ná, wọ́n sì máa ń rí i pé àwọn ra àwọn nǹkan táwọn ará nílò ní ẹ̀dínwó. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tàwọn ará tó ń ṣètò ìrànwọ́ lórílẹ̀-èdè Chile fẹ́ ra ẹ̀wà lẹ́ńtìlì tó ń lọ bí àpò mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) fáwọn ará. Láàárín oṣù kan péré, ẹ̀wà náà fi ìlọ́po méjì gbówó lórí! Lẹ́yìn wákàtí méjì tí wọ́n ti gbà láti ra ẹ̀wà náà níye tó gbówó lórí yẹn, ẹni tó ń tà á pè wọ́n, ó sì sọ fún wọn pé ẹnì kan tó ti ra ẹ̀wà kó tó wọ́nwó ti dá ẹ̀wà tó rà pa dà. Torí náà, dípò tí ẹni tó ń ta ẹ̀wà náà á fi tà á níye tó gbówó lórí fáwọn ará, ṣe ló gbà láti tà á fún wọn níye tí wọ́n ń tà á kó tó wọ́n!

 Àmọ́, nígbà táwọn ará fẹ́ lọ gbé ẹ̀wà náà, ṣe lẹni tó ń tà á lóun ò tà á fún wọn mọ́. Ó sọ pé wọ́n máa ṣojúsàájú bí wọ́n ṣe ń pín oúnjẹ náà bíi tàwọn àjọ àtàwọn iléeṣẹ́ míì. Lẹ́yìn tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin wa gbàdúrà ráńpẹ́, ó sọ fún ẹni tó ń ta ẹ̀wà náà pé àwọn ti ṣèwádìí nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan láti mọ iye àwọn tó nílò oúnjẹ náà lóòótọ́. Wọ́n tún ṣàlàyé fún ẹni náà pé, torí pé àṣà ìbílẹ̀ àwọn ará tí wọ́n fẹ́ kó oúnjẹ náà fún yàtọ̀ síra, wọ́n máa fún ìdílé kọ̀ọ̀kan ní oúnjẹ ìlú wọn. Wọ́n tún jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé tinútinú làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń fowó ṣètìlẹyìn ká lè bójú tó ohun tá à ń ṣe yìí. Ìyẹn yà á lẹ́nu gan-an. Torí náà, yàtọ̀ sí pé ó gbà láti ta ẹ̀wà náà ní ẹ̀dínwó, ó tún fínnúfíndọ̀ fi nǹkan bí àpò ẹ̀wà mẹ́jọ kún iye àpò ẹ̀wà tí wọ́n rà nígbà míì.

“Ìfẹ́ Tó Dénú Ni Wọ́n Ní Síra Wọn”

 Ìyá àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Lusu ń gbé ní Liberia, opó ni, ó sì ń gbé pẹ̀lú márùn-ún lára àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀. Láàárọ̀ ọjọ́ kan tí wọ́n ń jẹun tí wọ́n sì ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́, ọmọ-ọmọ Lusu kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méje rí i pé kò sí oúnjẹ mọ́ nílé, ló bá sọ pé, “Kò mà sí oúnjẹ tá a máa jẹ lọ́sàn-án yìí.” Lusu wá sọ fún un pé òun ti gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì dá òun lójú pé Jèhófà máa pèsè ohun táwọn máa jẹ. Lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn gangan, àwọn alàgbà pe Lusu pé kó wá gba oúnjẹ tóun àti ìdílé ẹ̀ máa jẹ. Lusu wá sọ pé: “Ọmọ-ọmọ mi sọ pé òun ti wá mọ̀ pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà, torí pé ó gbọ́ tèmi.”

Àwọn ọmọdé tó ń gbé ní Democratic Republic of Congo ya àwòrán láti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará fún oúnjẹ tí wọ́n gbé wá fún wọn

 Obìnrin kan tó ń gbé ní Democratic Republic of Congo ń gbé nítòsí ìdílé kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó rí i pé àwọn ará gbé oúnjẹ wá fún ìdílé yẹn, ó sọ pé, “Lẹ́yìn àjàkálẹ̀ àrùn yìí, a máa di Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ran ara wọn lọ́wọ́ lásìkò tí nǹkan nira yìí.” Ọkọ ẹ̀ wá bi í pé, “Ṣé torí àpò ìrẹsì kan lo ṣe fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Kì í kúkú ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ àpò ìrẹsì yẹn jẹ́ kí n rí i pé ìfẹ́ tó dénú ni wọ́n ní síra wọn.”

 Ọrẹ àtinúwá tẹ́ ẹ̀ ń ṣe ló ń jẹ́ ká lè máa bójú tó ohun táwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin nílò lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn yìí. A mọyì bẹ́ ẹ ṣe ń lo onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà ṣètọrẹ lórí donate.pr418.com, ẹ ṣeun gan-an.