Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

A Gbèjà Àwọn Ará Wa Kí Wọ́n Lè Ní Òmìnira Láti Jọ́sìn

A Gbèjà Àwọn Ará Wa Kí Wọ́n Lè Ní Òmìnira Láti Jọ́sìn

MAY 1, 2021

 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló wà ní Latin America, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù lára wọn ló sì ní èdè àti àṣà ìbílẹ̀ tiwọn. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn yìí ló jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin wa, wọn ò sì fojú kéré àṣà ìbílẹ̀ wọn. Kí wọ́n lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá mọ Ọlọ́run, wọ́n ti túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ohun tó ju àádóje (130) lára àwọn èdè àdúgbò tí wọ́n ń sọ ní Latin America. a Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ará yìí ló ń kojú àtakò tó le gan-an torí pé wọ́n ń sin Jèhófà, tí wọ́n sì kọ̀ láti lọ́wọ́ sí àwọn àṣà ìbílẹ̀ tí ò bá Bíbélì mu. Báwo la ṣe ń lo owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètọrẹ láti ran àwọn ará wa yìí lọ́wọ́?

A Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Pa Dà Sílé

 Lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ohun kan ṣẹlẹ̀ sáwọn ará tó ń gbé ní Huichol lápá ibi tí òkè wà ní ìpínlẹ̀ Jalisco. b Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi sọ fáwọn ará àdúgbò wọn pé àwọn ò ní lọ́wọ́ sí àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu, síbẹ̀ ohun tí wọ́n sọ yẹn bí àwọn ará àdúgbò nínú débi pé ní December 4, 2017, àwọn jàǹdùkú wá gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn míì tó wà pẹ̀lú wọn. Àwọn jàǹdùkú yẹn fipá lé àwọn ará wa kúrò nílùú, wọ́n ba àwọn nǹkan wọn jẹ́, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ wọn pé àwọn máà pa ẹnikẹ́ni tó bá pa dà sílùú nínú wọn.

 Àwọn ará tó wà nítòsí ìlú náà pèsè ohun táwọn ará yẹn nílò. Àmọ́, báwo ni wọ́n ṣe máa pa dà sílé? Arákùnrin Agustín sọ pé: “A ò lówó tá a lè fi gba lọ́yà, a ò sì lẹ́ni tó lè gbà wá nímọ̀ràn lórí ohun tó yẹ ká ṣe.”

 Ká lè ran àwọn ará wa yìí lọ́wọ́, ẹ̀ka ọ́fíìsì Central America gbé ìgbésẹ̀ ní kíá. Wọ́n kọ́kọ́ ní kí àwọn ọlọ́pàá bá wọn wádìí ọ̀rọ̀ náà. Lẹ́yìn ìyẹn, Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fọwọ́ sí i pé kí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin ní oríléeṣẹ́ gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́ lórúkọ àwọn ará wa tó ń gbé ní Huichol. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́ tó ga jù lọ lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.

 Àwọn lọ́yà láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí wọ́n lè múra bí wọ́n ṣe máa gbèjà àwọn ará wa nílé ẹjọ́. Wọ́n ṣàlàyé fún ilé ẹjọ́ náà pé òótọ́ ni pé ó yẹ káwọn èèyàn máa fọwọ́ pàtàkì mú àṣà ìbílẹ̀ ìlú kọ̀ọ̀kan, síbẹ̀ ó yẹ káwọn ará ìlú máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n torí gbogbo èèyàn ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó fẹ́, ibi gbogbo làwọn èèyàn sì ti lómìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n.

 Ní July 8, 2020, ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre. Ilé ẹjọ́ pàṣẹ fáwọn ará ìlú pé kí wọ́n jẹ́ káwọn tí wọ́n lé kúrò nílùú pa dà sílé. Arákùnrin Agustín tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára òun àtàwọn míì, ó ní: “Inú wa dùn gan-an nígbà tá a rí báwọn ará ṣe wá ràn wá lọ́wọ́, a mọyì ohun tí wọ́n ṣe fún wa. Ọpẹ́lọpẹ́ wọn, à bá má lè ṣe ohunkóhun.”

‘Wọ́n Ṣe Ohun Ribiribi Nítorí Ìwọ̀nba Èèyàn’

 Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa tó ń gbé lábúlé kan tí wọ́n ń pè ní San Juan de Ilumán lórílẹ̀-èdè Ecuador. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń gbébẹ̀ ló jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Otavalo Valley. Lọ́dún 2014, àwọn ará gbàṣẹ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sílùú náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àmọ́, àlùfáà kan kó àwọn jàǹdùkú tó ju ọgọ́rùn-ún kan (100) wá síbẹ̀ láti dá iṣẹ́ náà dúró. Nígbà tó yá, àwọn ará ìlú sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò gbọ́dọ̀ pàdé pọ̀ fún ìjọsìn mọ́ nílùú náà.

 Ẹ̀ka tó ń bójú tó ọ̀ràn òfin ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Ecuador ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú èyí tó wà lóríléeṣẹ́ wa láti gbèjà àwọn ará wa yìí, kí wọ́n má bàa fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n. Wọ́n gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn mú káwọn ará ìlú náà fún àwọn ará wa lómìnira láti máa pàdé pọ̀ fún ìjọsìn, kí wọ́n sì parí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Àmọ́ kí wọ́n má bàa tún fi ẹ̀tọ́ àwọn ará wa dù wọ́n lọ́jọ́ iwájú, àwọn aṣojú ètò Ọlọ́run ní káwọn ilé ẹjọ́ gíga ronú lórí ìbéèrè pàtàkì kan, wọ́n ní: Ṣé dandan ni káwọn ará ìlú fara mọ́ òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn kárí ayé?

 Ní July 16, 2020, ilé ẹjọ́ gíga jù lọ lórílẹ̀-èdè Ecuador gbọ́ ẹjọ́ yìí. Àwọn ará tó jẹ́ lọ́yà lórílẹ̀-èdè Ecuador ló ṣojú fún àwọn ará. Bákan náà, àwọn arákùnrin mẹ́rin míì dá sí ẹjọ́ náà láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn arákùnrin yìí nírìírí nídìí iṣẹ́ amòfin, wọ́n sì níwèé àṣẹ láti ṣiṣẹ́ lọ́yà níbikíbi kárí ayé. Àrùn Corona ò jẹ́ kí wọ́n lè wá sílé ẹjọ́, torí náà wọ́n sọ̀rọ̀ látorí íńtánẹ́ẹ̀tì. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tílé ẹjọ́ máa gbà káwọn amòfin ṣojú fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nírú ọ̀nà yìí. c Àwọn agbẹjọ́rò náà lo ohun tí àjọ tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn kárí ayé sọ láti jẹ́rìí sí i pé kò yẹ káwọn ará ìlú fọwọ́ rọ́ ẹ̀tọ́ tí ẹnì kan ní lábẹ́ òfin sẹ́yìn torí àṣà ìbílẹ̀ wọn.

Àwọn agbẹjọ́rò láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń gbèjà àwọn ará wa látorí ẹ̀rọ alátagbà

 Àwọn ará wa ní Otavalo Valley ò mọ ìpinnu tílé ẹjọ́ gíga jù lọ máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́, inú wọn dùn gan-an pé àwọn ará ràn wọ́n lọ́wọ́. Alàgbà kan tó ń jẹ́ César, níjọ Ilumán Quichua sọ pé: “Jèhófà àti ètò ẹ̀ nìkan ló lè ṣerú iṣẹ́ ribiribi bí èyí lórí ìwọ̀nba èèyàn.”

 Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni gbogbo àwọn agbẹjọ́rò tó ṣojú fún àwọn ará níbi ìgbẹ́jọ́ yìí, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi yọ̀ǹda ara wọn, tí wọ́n sì lo ìrírí wọn lẹ́nu iṣẹ́ amòfin láti ran àwọn ará lọ́wọ́ láìgba ohunkóhun. Síbẹ̀, owó kékeré kọ́ ni wọ́n fi gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́, ọ̀pọ̀ àkókò ni wọ́n sì fi gbèjà àwọn ará wa. Bí àpẹẹrẹ, ohun tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ọgọ́rin wákàtí (380) làwọn agbẹjọ́rò ètò Ọlọ́run àtàwọn arákùnrin míì fi múra ohun tí wọ́n máa sọ nílé ẹjọ́ sílẹ̀, wọ́n sì lo ọgọ́rùn-ún méjì àti ogójì (240) wákàtí láti fi túmọ̀ àwọn ìsọfúnni náà kó lè ṣe é lò fún wọn níbi ìgbẹ́jọ́ tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí làwọn lọ́yà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì (40) lò látibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kárí ayé láti gbèjà àwọn ará lórílẹ̀-èdè Ecuador. Ibo la ti rówó tá a fi bojú tó ẹjọ́ yìí, ká lè gbèjà ẹ̀tọ́ àwọn ará wa? Owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètìlẹyìn ló mú kó ṣe é ṣe, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọrẹ yìí lẹ sì ń fi ránṣẹ́ láti ọ̀kan lára àwọn apá tó wà lórí ìkànnì donate.pr418.com. A mọyì ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín.

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún máa ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sí ọ̀pọ̀ èdè míì tí wọ́n ń sọ ní Latin America àtàwọn èdè adití tó jẹ́ pé apá ibẹ̀ nìkan ni wọ́n ti ń sọ ọ́.

b Wọ́n tún máa ń pe àwọn Huichol ní Wixáritari, wọ́n sì sábà máa ń pe èdè wọn ní Wixárika.

c Bó tiẹ̀ jẹ́ pé orúkọ àwọn ará kárí ayé kọ́ la fi gbé ẹjọ́ náà lọ sílé ẹjọ́, síbẹ̀ àwọn adájọ́ gbà káwọn ará wá síbi ìgbẹ́jọ́ náà, wọ́n pè wọ́n ní amicus curiae tó túmọ̀ sí “ọ̀rẹ́ ilé ẹjọ́.”