Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

A Túmọ̀ Àpéjọ Agbègbè “Ẹ Máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”! ti Ọdún 2020

A Túmọ̀ Àpéjọ Agbègbè “Ẹ Máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”! ti Ọdún 2020

JULY 10, 2020

 Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gbogbo àwọn ará kárí ayé máa gbádùn àpéjọ agbègbè láàárín àsìkò kan náà ní oṣù July àti August 2020. Kí èyí lè ṣeé ṣe, a ní láti túmọ̀ àwọn fídíò àpéjọ náà sí èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500). Ó yẹ kó gbà wá tó odindi ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láti ṣètò iṣẹ́ náà, ká túmọ̀ rẹ̀, ká sì gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. Àmọ́ torí bí nǹkan ṣe rí lákòókò àrùn corona yìí, àwọn atúmọ̀ èdè ní láti túmọ̀ Àpéjọ Agbègbè “Ẹ Máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”! ti ọdún 2020 láàárín oṣù mẹ́rin péré.

 Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtumọ̀ àti Ẹ̀ka Tó Ń Rajà Kárí Ayé ní Orílé-Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣètò àwọn nǹkan tá a nílò láti ṣe iṣẹ́ ńlá yìí. Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtumọ̀ rí i pé àwọn atúmọ̀ èdè máa nílò àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tó pọ̀ sí i ní pàtàkì makirofóònù, kí iṣẹ́ náà lè ṣeé ṣe. Ẹ̀ka Tó Ń Rajà Kárí Ayé wá ra ẹgbẹ̀rún kan (1,000) makirofóònù, wọ́n sì fi wọ́n ránṣẹ́ sáwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún méjì (200).

 Kí ètò Ọlọ́run lè ṣọ́wó ná, wọ́n ra makirofóònù tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, wọ́n sì ní kí ilé-iṣẹ́ náà kó o lọ́ síbì kan tá á jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti fi ránṣẹ́ sáwọn atúmọ̀ èdè kárí ayé. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gọ́rin (79,000) náírà ni wọ́n ń ta ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn makirofóònù náà. Àmọ́ torí pé a ra gbogbo ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùnlélọ́gọ́ta (65,000) náírà la rí i rà, ìyẹn sì fi hàn pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá (13,000) náírà ló dín lórí ìkọ̀ọ̀kan.

 Àárín oṣù April àti May 2020 ni Ẹ̀ka Tó Ń Rajà Kárí Ayé ra àwọn makirofóònù yìí, tí wọ́n sì fi ránṣẹ́. Kò rọrùn rárá láti fi nǹkan ránṣẹ́ lásìkò yẹn, ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ò sì ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́ torí àrùn corona. Àmọ́, nígbà tó fi máa di ìparí oṣù May, èyí tó pọ̀ jù lára ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì míì ló ti rí makirofóònù náà gbà.

 Jay Swinney tó ń bójú tó Ẹ̀ka Tó Ń Rajà Kárí Ayé sọ pé: “Gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ sí bá a ṣe ra àwọn ohun èlò náà ló fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka ọ́fíìsì kí ètò náà lè yọrí sí rere. Ó dájú pé ẹ̀mí Jèhófà nìkan ló mú kó rọrùn fún wa láti ṣe iṣẹ́ yìí lákòókò, ká sì ṣọ́wó ná, káwọn ará wa lè gbádùn àpéjọ ọdún yìí.”

 Nicholas Ahladis tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtumọ̀ sọ pé: “Àrùn corona ò jẹ́ káwọn atúmọ̀ èdè wà pa pọ̀, àmọ́ inú wọn dùn gan-an nígbà tí wọ́n gba àwọn makirofóònù náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò sí níbì kan náà, wọ́n ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan láti túmọ̀ àwọn àsọyé, fídíò àtàwọn orin sí èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500), wọ́n sì gbohùn wọn sílẹ̀.”

 Àwọn ohun tá a rà yìí wà lára ohun tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ará wa kárí ayé láti gbádùn Àpéjọ Agbègbè “Ẹ Máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”! ti ọdún 2020. Bẹ́ ẹ sì ṣe fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ṣètìlẹyìn lórí ìkànnì donate.pr418.com àtàwọn ọ̀nà míì ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ra àwọn nǹkan yìí.