BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ
Bá A Ṣe Ń Bójú Tó Àwọn Ilé Ìpàdé Wa
APRIL 1, 2024
Arábìnrin Nicole tó jẹ́ ọ̀dọ́ tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Ilé Ìpàdé wa gan-an torí ibẹ̀ lèmi àtàwọn ará mi ti máa ń wà pa pọ̀ tá a sì máa ń fún ara wa níṣìírí.” Ṣé bó ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn?
Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gọ́ta (63,000) Ilé Ìpàdé làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn kárí ayé. Àwọn Ilé Ìpàdé yìí jẹ́ ibi tó tura láti jọ́sìn Ọlọ́run. Àmọ́ ohun tó wà fún tún ju ìyẹn lọ. David tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà sọ pé: “Àwọn Ilé Ìpàdé wa ń buyì kún ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Ẹnu máa ń ya àwọn àlejò tó bá wá síbẹ̀ tí wọ́n bá rí bó ṣe wà ní mímọ́ tónítóní.” Kò ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ torí iṣẹ́ àṣekára là ń ṣe ká lè bójú tó àwọn Ilé Ìpàdé wa. Àmọ́, báwo la ṣe ń ṣe é?
Bá A Ṣe Ṣètò Iṣẹ́ Àtúnṣe Láwọn Ilé Ìpàdé Wa
Ojúṣe àwọn ará tó ń lo Ilé Ìpàdé kan ni láti bójú tó o kó lè wà ní mímọ́. Torí náà, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń tún Ilé Ìpàdé wọn ṣe déédéé. Wọ́n tún máa ń ṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, wọ́n sì máa ń ṣàbójútó àwọn ohun tó wà níbẹ̀ kó má bàa bà jẹ́.
Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ (ìyẹn ẹ̀ka LDC) máa ń yan arákùnrin kan láti lọ dá àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe máa bójú tó Ilé Ìpàdé wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin yìí máa ń bójú tó Ilé Ìpàdé mẹ́fà sí mẹ́wàá. Arákùnrin yìí á ṣèbẹ̀wò sáwọn Ilé Ìpàdé yẹn, á sì dá àwọn akéde lẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n á ṣe máa bójú tó Ilé Ìpàdé wọn. Lọ́dún mẹ́ta-mẹ́ta, ó máa wá sí Ilé Ìpàdé náà láti yẹ̀ ẹ́ wò yí ká, á sì tọ́ka sí àwọn ohun tó bá rí tó lè wu ẹ̀mí èèyàn léwu àtàwọn nǹkan tó nílò àtúnṣe.
Àwọn ará máa ń mọyì bí arákùnrin tí ẹ̀ka LDC rán wá ṣe máa ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Arábìnrin Indhumathi tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Íńdíà sọ pé: “Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn ti lọ wà jù. Inú wa dùn pé wọ́n kọ́ wa bá a ṣe lè máa bójú tó Ilé Ìpàdé wa kó lè dùn ún wò.” Arákùnrin Evans tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kenya náà sọ pé: “A ti kọ́ bá a ṣe lè máa tètè ṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, kó tó di pé nǹkan máa bà jẹ́ pátápátá. Ìyẹn ń jẹ́ ká lè máa ṣówó ná.”
Bá A Ṣe Ń Bójú Tó Ìnáwó
Lọ́dọọdún, owó kékeré kọ́ là ń ná láti ṣe àbójútó àti àtúnṣe àwọn Ilé Ìpàdé wa. Ohun tó sì máa pinnu bí owó ọ̀hún ṣe máa pọ̀ tó ni ibi tí Ilé Ìpàdé náà wà, iye ọdún tá a ti kọ́ ọ àti iye ìjọ tó ń lò ó. Ibo la ti ń rí owó tá à ń ná yìí?
Owó táwọn èèyàn fi ṣètọrẹ la fi ń bójú tó àwọn àtúnṣe yìí. Arákùnrin Alexander tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kazakhstan sọ pé: “A máa ń lò lára àwọn ọrẹ yìí láti fi ra dátà, láti fi san owó iná àtowó omi. A tún máa ń lò lára ẹ̀ láti fi ra ọ̀dà, ìgbálẹ̀, ọṣẹ àtàwọn nǹkan míì tá a fi ń ṣe ìmọ́tótó àti àtúnṣe àwọn Ilé Ìpàdé wa.” A máa ń fi owó tó bá kù ṣe ọrẹ fún àwọn iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé, lára ẹ̀ ni àwọn iṣẹ́ ìkólé míì tó gbòòrò tá à ń ṣe.
Àwọn Iṣẹ́ Àtúnṣe Tó Gbòòrò
Tí Ilé Ìpàdé kan bá nílò àtúnṣe, àmọ́ tí owó tó máa ná ìjọ tó ń lo ibẹ̀ ju owó tí wọ́n fi ń bójú tó o fún oṣù méjì tàbí mẹ́ta, àwọn alàgbà máa kàn sí arákùnrin tí ẹ̀ka LDC yàn pé kó máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Tí ẹ̀ka LDC bá fọwọ́ sí i pé kí wọ́n ṣe àtúnṣe ilé yẹn, a máa lò lára owó táwọn ará fi ṣètọrẹ fún àwọn iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé. Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2023, iṣẹ́ àtúnṣe àti àbójútó tá a ṣe jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ, ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún (8,793), ó sì ná wa ní ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gọ́rin owó dọ́là a ($76.6 million). Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa méjì nínú iṣẹ́ yẹn.
Lórílẹ̀-èdè Àǹgólà, Ilé Ìpàdé kan tí wọ́n ti ń lò láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sẹ́yìn nílò àtúnṣe gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ohun tó ń gbé iná wọnú Ilé Ìpàdé náà ti dẹnu kọlẹ̀, ògiri ẹ̀ ti sán, àwọn ará àdúgbò sì ń ṣàròyé pé omi ń ṣàn láti ibẹ̀ wọnú ilé àwọn. Torí náà, ẹ̀ka LDC ṣètò láti tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe. Owó tá a ná sórí iṣẹ́ yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án, ọgọ́rùn-ún méjì àti márùnlélọ́gọ́rin owó dọ́là ($9,285). Inú àwọn tó ń gbé ládùúgbò náà dùn sí àtúnṣe yẹn, ọ̀nà tá a sì gbà ṣiṣẹ́ yẹn wú wọn lórí gan-an.
Lórílẹ̀-èdè Poland, òrùlé Ilé Ìpàdé wa kan ń jò, rọ́ọ̀gì tí wọ́n tẹ́ síbẹ̀ sì ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Torí náà, ẹ̀ka LDC fọwọ́ sí i pé ká tún òrùlé yẹn ṣe lọ́nà tí omi ò fi ní lè bà á jẹ́, ká sì ra rọ́ọ̀gì míì. Owó tá a ná sórí iṣẹ́ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án, ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàdínlọ́gọ́ta owó dọ́là ($9,757). Torí àtúnṣe tá a ṣe yìí, a ò ní ṣe àwọn àtúnṣe tó gbòòrò nínú Ilé Ìpàdé náà fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Iṣẹ́ Tá À Ń Ṣe Ń Fògo fún Jèhófà
Àwọn àtúnṣe tá à ń ṣe sáwọn Ilé Ìpàdé ń dín ìnáwó kù, ó ń jẹ́ ká lè fọgbọ́n ná owó táwọn ará fi ń ṣètọrẹ, ó sì tún ń fògo fún Jèhófà. Arákùnrin Shaun, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Tonga sọ pé: “Bá a ṣe ń tún àwọn Ilé Ìpàdé wa ṣe ń jẹ́ ká lè máa jọ́sìn Jèhófà níbi tó mọ́, tó wà létòlétò, tó sì bójú mu, èyí sì ń mú káwọn èèyàn ládùúgbò ibi tí Ilé Ìpàdé wà máa fògo fún Jèhófà. Gbogbo ìgbà ló máa ń yá wa lára láti pe àwọn èèyàn wá sí Ilé Ìpàdé wa.”
Bó O Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
Gbogbo wa la lè kọ́wọ́ ti àtúnṣe àti àbójútó àwọn Ilé Ìpàdé wa. Marino, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ẹ̀ka LDC yàn láti máa dá àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́ lórílẹ̀-èdè Australia sọ pe: “Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti máa bójú tó àwọn Ilé Ìpàdé wa, gbogbo wa la sì lè kópa níbẹ̀. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká lè ṣọ́ owó táwọn ará fi ń ṣètọrẹ ná, àá sì lè lo owó náà fáwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì jù.”
Inú Arákùnrin Joel tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Íńdíà máa ń dùn tó bá ń tún Ilé Ìpàdé wọn ṣe. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá àwọn ará ṣiṣẹ́ ń jẹ́ kí n lè fojú inú wo bí ayé tuntun ṣe máa dùn tó.” Nicole tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Láìpẹ́ yìí táwọn arákùnrin kan ń ṣàtúnṣe ibi tó ń jò nínú ilé ìtura tó wà nílé ìpàdé wa, ńṣe lèmi ń nu omi tó ń jò sílẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èmi kọ́ ni mò ń tún ibi tó bà jẹ́ ṣe, omi tí mò ń nù yẹn ò ní jẹ́ káwọn ará yọ̀ ṣubú.”
Tó o bá fẹ́ yọ̀ǹda ara ẹ láti tún Ilé Ìpàdé yín ṣe, sọ fáwọn alàgbà ìjọ ẹ. Yàtọ̀ síyẹn, o lè fowó ṣètọrẹ fún iṣẹ́ náà. Àwọn owó yẹn la fi ń bójú tó Ilè Ìpàdé tó wà ládùúgbò rẹ àtàwọn Ilé Ìpàdé míì kárí ayé. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ fowó ṣètọrẹ, ẹ lè fi sínú àwọn àpótí tó wà ní Ilé Ìpàdé yín tàbí kẹ́ ẹ fi ránṣẹ́ lórí ìkànnì donate.pr418.com. Ẹ ṣeun gan-an, a mọrírì yín bẹ́ ẹ ṣe ń fi ohun tẹ́ ẹ ní ṣètọrẹ.
a Gbogbo dọ́là tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí ló jẹ́ owó dọ́là ti Amẹ́ríkà.