Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ ńlá là ń ṣe láti ṣàtúnṣe sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Japan (òsì) àti èyí tó wà ní Àǹgólà (ọ̀tún)

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Iṣẹ́ Ìkọ́lé Tó Ń Jẹ́ Ká Lè Túbọ̀ Wàásù

Iṣẹ́ Ìkọ́lé Tó Ń Jẹ́ Ká Lè Túbọ̀ Wàásù

OCTOBER 20, 2023

 Ó ń wu Ìgbìmọ̀ Olùdarí gan-an láti fi owó tá a fi ń ṣètọrẹ kọ́ àwọn ilé tó máa jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù tẹ̀ síwájú. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2023, a lo àwọn ilé iṣẹ́ abánikọ́lé láti bá wa ra àwọn ohun èlò ìkọ́lé, láti kọ́ àwọn ilé kan, kí wọ́n sì bá wa ṣe àtúnṣe àwọn Ilé Ìpàdé àti àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan kárí ayé. Owó tá a sì ná tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) mílíọ̀nù owó dọ́là. a Owó tí àwọn ìjọ sì ná láti tún àwọn Ilé Ìpàdé wọn ṣe kárí ayé kò sí lára èyí tá a sọ yìí.

 A tún máa ń fi owó tá a fi ṣètọrẹ kọ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì, ká sì fi bójú tó wọn. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè wà ní ipò tó dáa láti bójú tó iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé. Bákan náà, a ti ṣe àtúnṣe sí àwọn iṣẹ́ kan tá à ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì ká lè dín ìnáwó kù, ìyẹn á jẹ́ ká lè fi owó náà kọ́ àwọn Ilé Ìpàdé àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ká sì tún àwọn kan ṣe. Síbẹ̀ náà, a ṣì nílò òbítíbitì owó fún àtúnṣe àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan, tàbí ká tiẹ̀ kọ́ wọn sí ibòmíì. Kí nìdí táwọn iṣẹ́ yìí fi ṣe pàtàkì? Báwo ni àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣe ń ti iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe lẹ́yìn? Ẹ jẹ́ ká wò ó ná.

Ó “Máa Jẹ́ Kó Lálòpẹ́”

 Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lati kọ́ ní nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sẹ́yìn! Nicholas tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Kárí Ayé sọ pé: “Ilé tá à ń tún ṣe nígbà gbogbo pàápàá máa ń gbó bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó sì lè di èyí tí kò bágbà mu mọ́. Àmó bá a ṣe ń tún àwọn ilé yìí ṣe máa jẹ́ kó lálòpẹ́.”

 Ó yẹ ká máa tún àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ṣe látìgbàdégbà kó lè wà ní ipò tó dáa láti bójú tó iṣẹ́ ìwàásù tó túbọ̀ ń gbòòrò sí i. Látìgbà tá a ti kọ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì yìí, iye àwọn akéde ti pọ̀ sí i kárí ayé. A tún máa nílò ọ̀pọ̀ àwọn tó máa yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Torí náà, àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà tẹ́lẹ̀ ti wá kéré jù fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó wá pọn dandan ká mú kí ọ̀pọ̀ wọn fẹ̀ sí i.

 Ìdí míì tá a fi máa ń tún àwọn ilé náà ṣe ni ọ̀rọ̀ ààbò. Bí ayé burúkú yìí ṣe ń lọ sópin, àjálù lè ṣẹlẹ̀ nígbàkigbà. (Lúùkù 21:11) Bá a ṣe ń lo ọ̀nà tuntun tí wọ́n gbà ń kọ́lé báyìí, ṣe là ń mú kí ọkàn àwọn ará balẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láìséwu. Bá a tún ṣe ń kọ́ wọn máa jẹ́ kó rọrùn láti lo ibẹ̀ fún ètò ìrànwọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, kí wọ́n sì fi máa ṣètò iṣẹ́ ìwàásù nìṣó lẹ́yìn àjálù náà.

“Jèhófà Ló Jẹ́ Kí Èyí Ṣeé Ṣe”

 Ní ọdún iṣẹ́ ìṣìn 2023, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí wọ́n tún mẹ́tàlélógójì (43) lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ṣe. Ìyẹn fi hàn pé, nǹkan bí ìdajì àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kárí ayé ni wọ́n máa tún ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ ká lè rí bí iṣẹ́ ìkọ́lé náà ṣe mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i.

 Àǹgólà. Arákùnrin Matt tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ pé: “A láǹfààní láti rí bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Hágáì 2:7 ṣe ń ṣẹ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Láàárín ọdún mẹ́wàá péré, àwọn akéde wa ti pọ̀ gan-an! Ká lè bójú tó àwọn akéde tuntun yìí, a máa nílò ìlọ́po mẹ́ta àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́, torí pé àwọn yàrá tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ò pọ̀ tó, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ la lè pè wá ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ náà wá já lé ìwọ̀nba àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì léjìká, ìyẹn sì mú kí wọ́n máa ṣe àfikún iṣẹ́ gan-an.”

Àwọn ọ́fíìsì tuntun (ọ̀tún) jẹ́ káwọn ará túbọ̀ ráyè ṣe iṣẹ́ wọn dáadáa

 Wọ́n ní káwọn arákùnrin kan lọ wo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà tóbi sí i. Ohun tí wọ́n kọ́kọ́ rò ni pé kí wọn tún àwọn ilé tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ṣe. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa, wọ́n rí i pé owó tá a máa ná máa pọ̀ gan-an tí wọ́n bá fẹ́ tún àwọn ilé náà ṣe. Wọ́n wá dábàá pé kí wọ́n ra ilé kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí Bẹ́tẹ́lì kí wọ́n sì tún un ṣe. Arákùnrin Matt sọ pé: “Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ sọ fún Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka pé ṣe ni wọ́n fẹ́ ra ilé kan kí wọ́n sì tún un ṣe, ó ṣe wá bíi pé ilé náà ò lè dà bí èyí tá a fúnra wa kọ́. Àmọ́ ní báyìí, a rí i pé ilé náà lohun tá a nílò gẹ́lẹ́, Jèhófà ló jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe.”

Àwọn ilé tó ṣeé gbé kiri ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jẹ́ ká lè pe ọ̀pọ̀ wá ṣèrànwọ́ ní Bẹ́tẹ́lì, kí iṣẹ́ ìwàásù lè túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú

 Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀ka ọ́fíìsì Àǹgólà ṣì nílò ilẹ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ ní báyìí, ilé tá a rà náà àtàwọn ilé tó ṣeé gbé kiri tó wà nínú Bẹ́tẹ́lì títí kan àwọn ilé míì tá a rẹ́ǹtì síta ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti pé àwọn èèyàn wá sí Bẹ́tẹ́lì, kí wọ́n lè máa ṣèrànwọ́ bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń gbòòrò sí i.

Ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin gbádùn iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Àǹgólà

 Japan. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì (40) ọdún tá a ti kọ́ àwọn ilé tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Japan, ọ̀pọ̀ nínú ẹ̀ la ò tún ṣe rí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń bójú tó wọn dáadáa, iye ọdún tá a ti fi lo àwọn ilé náà ju iye ọdún tó yẹ ká fi lò ó. Torí náà, à ń tún àwọn ilé yẹn ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.

 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti yí pa dà ní Bẹ́tẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, ṣáájú ọdún 2015, ẹ̀ẹ̀mẹtà lójúmọ́ ni wọ́n máa ń se oúnjẹ fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì, torí náà ibi ìdáná kékeré ní wọ́n ṣe sínú àwọn yàrá tí wọ́n kọ́ sí Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́ ní báyìí, kálukú ló ń se ọ̀pọ̀ nínú oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ. Torí náà, lára àwọn àtúnṣe tá a ṣe ni pé, a ṣètò ibi ìdáná tó tóbi díẹ̀ sínú àwọn yàrá Bẹ́tẹ́lì. Ìyẹn á jẹ́ kó rọrùn fún àwọn tó wà níbẹ̀ láti máa dáná nígbà tó bá wù wọ́n. Arábìnrin Kumiko tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Japan sọ pé, “Ilé ìdáná tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe yìí jẹ́ kára tù mí gan-an nínú yàrá, ó sì jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún mi láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ètò tí wọ́n ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì.”

Ilé ìdáná tuntun (ọ̀tún) jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fáwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì láti máa se oúnjẹ wọn

 Ìṣẹ́ tá à ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Japan ṣe pàtàkì gan-an torí ó kan iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé. (Mátíù 28:19, 20) Ìdí ni pé ẹ̀ka ọ́fíìsì Japan wà lára ẹ̀ka ọ́fíìsì méjì péré tá a ti ń tẹ odindi Bíbélì kárí ayé. Torí náà, lára àwọn àtúnṣe tá à ń ṣe ni pé a ṣètò ẹ̀rọ kan táá máa sẹ́ ìdọ̀tí kúrò nínú afẹ́fẹ́, ká lè dáàbò bo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìtẹ̀wé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan owó dọ́là la ná láti ra ẹ̀rọ yìí, ká sì tò ó pọ̀, inú wa dùn pé ó ń jẹ́ kí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lè máa tẹ àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tá a nílò nìṣó.

Ẹ̀rọ tó ń sẹ́ ìdọ̀tí kúrò nínú afẹ́fẹ́ máa dáàbò bo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìtẹ̀wé

 Ohun kan tó ṣe pàtàkì sí wa ni bí iṣẹ́ títẹ Bíbélì ò ṣe ní dáwọ́ dúró lásìkò tá à ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Arákùnrin Trey tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Japan sọ pé: “Lásìkò tá à ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà, ọ̀pọ̀ Bíbélì ni ètò Ọlọ́run mú jáde, Bíbélì táwọn ará sì nílò kárí ayé ń pọ̀ sí i. Oníruurú ẹ̀ka ní Bẹ́tẹ́lì títí kan àwọn agbaṣẹ́ṣe ló ṣiṣẹ́ pọ̀ láti rí i dájú pé iṣẹ́ ìtẹ̀wé ò dáwọ́ dúró bí iṣẹ́ ìkọ́lé náà ṣe ń lọ.” Láìka bí gbogbo àwọn iṣẹ́ yìí ṣe ń forí gbárí, Bíbélì tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn méjì àti ogún (220,000) là ń tẹ̀ lóṣooṣù láti oṣù March sí August 2023, àsìkò yẹn la sì ṣiṣẹ́ jù nígbà tá à ń tún ilé ìtẹ̀wé náà ṣe. Ohun tó dùn mọni jù ni pé iye tá a pinnu láti ná sórí iṣẹ́ náà la ná.

 Ohun míì tá a fẹ́ ṣe ni pé a máa ṣètò àwọn ohun táá jẹ́ ká dín iye tá à ń ná lórí iná mọ̀nàmáná kù. A máa ṣètò iná solar, ìyẹn sì máa jẹ́ ká lè tọ́jú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà (120,000) owó dọ́là lórí iye tá à ń ná lórí ọ̀rọ̀ iná lọ́dọọdún. A tún máa ṣe àwọn wíńdò alápá mẹ́ta táá jẹ́ ká dín iye iná tá à ń lò kù, kódà àá lè máa tọ́jú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) owó dọ́là lọ́dọọdún. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tá a fẹ́ ṣe yìí máa jẹ́ kí iye tá a máa ná láti tún àwọn ilé náà ṣe pọ̀ sí i, tó bá fi máa dìgbà tá a lo solar àti wíńdò náà gbó, iye tá a ti máa tọ́jú máa ju mílíọ̀nù mẹ́ta ààbọ̀ owó dọ́là lọ. Bákan náà, àwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe yìí kò ní ba àyíká jẹ́.

Wíńdò alápá mẹ́ta máa dín iná tá à ń lò ní Bẹ́tẹ́lì kù

“Iṣẹ́ Tó Wà Nílẹ̀ ṣì Pọ̀ Gan-an”

 Ohun tá à ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì méjèèjì yìí jẹ́ ká rí i pé iṣẹ́ kékeré kọ́ là ń ṣe kí Bẹ́tẹ́lì lè wà ní ipò tó dáa, ká lè lò ó láti fi ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn. Àmọ́, ó kù ni ìbọn ń ró. Arákùnrin Aaron tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Kárí Ayé sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti ṣe, àmọ́ iṣẹ́ tó wà nílẹ̀ ṣì pọ̀ gan-an.” Kí lá jẹ́ ká lè ṣe iṣẹ́ yìí? Ó sọ pé: “Owó táwọn ará fi ń ṣètìlẹyìn ń jẹ́ ká lè ṣe àwọn iṣẹ́ yìí. Àmọ́ ohun míì tá a mọrírì ni báwọn ará ṣe yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe àwọn iṣẹ́ yìí, tí wọ́n sì tún ń múra láti yọ̀ǹda ara wọn fún èyí tá a máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Bí àwọn ará ṣe ń yọ̀ǹda ara wọn, tí wọ́n sì ń fowó ṣètìlẹyìn jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà ló ń bù kún iṣẹ́ náà.”​—Sáàmù 110:3.

 Ọrẹ tá a fi ń ṣètìlẹyìn la fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ìkọ́lé àti àtúnṣe tá à ń ṣe kárí ayé. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọrẹ yìí ló jẹ́ pé orí ìkànnì donate.pr418.com la ti ṣe é. Ẹ ṣeun gan-an, a mọrírì bẹ́ ẹ ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́.

a Gbogbo dọ́là tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí ló jẹ́ dọ́là ti Amẹ́ríkà.