Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Ohun Tó Ṣẹ́ Kù Níbì Kan Ń Dí Àìtó Àwọn Míì

Ohun Tó Ṣẹ́ Kù Níbì Kan Ń Dí Àìtó Àwọn Míì

OCTOBER 1, 2020

 Iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ní ilẹ̀ tó ju ọgọ́rùn-ún méjì (200) lọ. Àmọ́, nǹkan bí ilẹ̀ márùndínlógójì (35) péré lára wọn ló ń rí ìtìlẹyìn tó pọ̀ tó láti bójú tó ohun tí wọ́n nílò. Báwo la ṣe wá ń rówó tá a fi ń bójú tó ohun táwọn ilẹ̀ tó kù nílò?

 Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń ṣàyẹ̀wò ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílò kárí ayé, kó lè rọrùn fún wa láti jọ́sìn Jèhófà ká sì ṣiṣẹ́ ìwàásù. Wọ́n máa ń fara balẹ̀ ṣètò bí wọ́n ṣe máa náwó, ohun tí wọ́n bá sì ti pinnu láti fi owó ṣe ni wọ́n máa ń lò ó fún. Tí owó tó wọlé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì kan bá pọ̀ ju iye tí wọ́n nílò lọ, wọ́n máa fi ohun tó ṣẹ́ kù ránṣẹ́ sáwọn ilẹ̀ tí ò lówó tó pọ̀ tó. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí bá ohun táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe nígbà tí wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́ “kí nǹkan lè dọ́gba.” (2 Kọ́ríńtì 8:14) Wọ́n fi ohun tó ṣẹ́ kù lọ́dọ̀ wọn dí àìtó àwọn Kristẹni tó jẹ́ aláìní.

 Báwo ló ṣe rí lára àwọn ará nígbà tí wọ́n gba owó táwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì míì fi ránṣẹ́ sí wọn? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Tanzania jẹ́ ká mọ bó ṣe rí lára wọn, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń gbébẹ̀ ló jẹ́ pé owó tí wọ́n ń rí ná lójúmọ́ ò tó ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) náírà. Owó táwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì míì fi ránṣẹ́ sí wọn ni wọ́n fi ṣàtúnṣe sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí Ìjọ Mafinga ń lò. Àwọn ará ìjọ yẹn kọ̀wé láti dúpẹ́, wọ́n ní: “Iye àwọn tó ń wá sípàdé ti pọ̀ sí i látìgbà tí wọ́n ti ṣàtúnṣe sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa! A mọyì ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí ètò Jèhófà àtàwọn ará kárí ayé fi hàn sí wa, ìyẹn ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti ní ibi ìjọsìn tó rẹwà yìí.”

 Àrùn Corona ti mú kó nira fún àwọn kan lára àwọn ará wa ní Sri Lanka láti rí oúnjẹ tó máa tó wọn. Imara Fernando àti Enosh ọmọkùnrin ẹ̀ kékeré wà lára wọn. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ìtìlẹyìn tá a rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì míì, ìyẹn ló jẹ́ ká lè pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Nínú káàdì tí wọ́n ṣe láti dúpẹ́, wọ́n sọ pé: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará tó fìfẹ́ hàn sí wa lásìkò tí nǹkan nira yìí. Inú wa dùn gan-an pé a wà lára ìdílé tó kárí ayé yìí, a sì ń gbàdúrà pé kí Jèhófà túbọ̀ máa ran àwọn ará wa lọ́wọ́ lákòókò òpin yìí.”

Imara and Enosh Fernando

 Kò sí bí nǹkan ṣe lè nira tó fáwọn ará wa níbikíbi tí wọ́n bá wà, wọ́n máa ń múra tán láti fi ohun tí wọ́n ní ran àwọn míì lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, Enosh ṣe àpótí kékeré kan tó máa ń fowó sí kóun náà lè rí ohun tó máa fi ṣètìlẹyìn fáwọn ìdílé tó jẹ́ aláìní. Ohun tí Guadalupe Álvarez ṣe náà nìyẹn. Lápá ibi tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mexico, owó táṣẹ́rẹ́ ni wọ́n máa ń san fáwọn kan lára àwọn òṣìṣẹ́, àwọn míì sì wà tí kì í rí owó oṣù gbà déédéé. Síbẹ̀, ó máa ń ṣètìlẹyìn bí agbára ẹ̀ ṣe gbé e tó. Ó kọ̀wé láti dúpẹ́, ó ní: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó máa ń ṣoore fún mi, ó sì ń fìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi. Mo mọ̀ pé tí wọ́n bá fi máa pa ìtìlẹyìn mi pọ̀ mọ́ tàwọn míì, wọ́n á lè fi pèsè ohun táwọn arákùnrin àti arábìnrin mi tó jẹ́ aláìní nílò.”

 Inú àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì tó ń fowó ránṣẹ́ sáwọn míì máa ń dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Arákùnrin Anthony Carvalho tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ pé ìtìlẹyìn táwọn míì ṣe la fi ń gbéra, torí nǹkan ò rọrùn. Ìrànlọ́wọ́ yìí ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i lórílẹ̀-èdè wa. Ní báyìí tí nǹkan ti yí pa dà fún wa, àwa náà ti wá láǹfààní láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Torí náà, tá a bá wo bí nǹkan ṣe ń lọ sí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé, ó máa ń yá wa lára láti ran àwọn míì lọ́wọ́.”

 Kí lohun tó dáa jù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ṣe tí wọ́n bá fẹ́ ran àwọn ará wọn tó jẹ́ aláìní lọ́wọ́? Kì í ṣe pé wọ́n máa fowó ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè míì, àmọ́ wọ́n máa ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé. Wọ́n lè fowó sínú àpótí tá a kọ “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé” sí nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí kí wọ́n fi ránṣẹ́ lórí ìkànnì donate.pr418.com. A mọyì àwọn ìtìlẹyìn yín gan-an ni.