Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Ohun Tuntun Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ohun Tuntun Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

APRIL 1, 2022

 Ní January 2021, Ìgbìmọ̀ Olùdarí kéde pé a ti mú ìwé tuntun kan tí àá fi máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde, ìyẹn ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! a Báwo ni ìfilọ̀ yìí ṣe rí lára ẹ? Matthew láti orílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé: “Inú mi dùn gan-an! Nígbà tí mo tún wá gbọ́ àsọyé àti fídíò tí wọ́n fi ṣàlàyé ìwé náà títí kan bí wọ́n ṣe lò ó láti mọ bó ṣe gbéṣẹ́ tó, ayọ̀ mi kọjá sísọ. Ṣe ló ń ṣe mí bíi kí n ti rí ìwé yìí, kí n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó.”

 Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! máa mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀nà tuntun kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, ìyẹn nìkan kọ́ ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìwé tuntun yìí àtàwọn ìwé tá à ń lò tẹ́lẹ̀. Tó bá jẹ́ pé ẹ̀dà ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! tá a tẹ̀ sórí ìwé lò ń lò, wàá rí i pé ó yàtọ̀ lọ́wọ́. Ká lè mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo bí wọ́n ṣe ṣe ìwé náà.

Ìwé Tuntun Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀

 Bébà tó nípọn la fi tẹ̀ ẹ́. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé ká lo bébà tó nípọn? Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! ní oríṣiríṣi àwòrán mèremère tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600), ìyẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po mẹ́wàá àwòrán tó wà nínú ìwé Bíbélì Kọ́ Wa! Gbogbo ojú ìwé rẹ̀ ló sì ní àwọn àlàfo tó máa ń wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìwé. Téèyàn ò bá ṣọ́ra, àwọn nǹkan méjì yìí lè fa ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, tí bébà bá fẹ́lẹ́, àwọn àwòrán tó wà lójú ìwé kan á máa hàn lódì kejì ìwé náà. Kí ìṣòro yìí má bàa wáyé, àwọn arákùnrin tó wà ní Ẹ̀ka Ìtẹ̀wé Kárí Ayé (ìyẹn IPD), ní Wallkill, New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lo oríṣi bébà mẹ́rin tá a fi ń tẹ̀wé, kí wọ́n lè mọ èyí tó dáa jù. Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá ṣàyẹ̀wò bébà kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì yan èyí tí àwòrán rẹ̀ ò hàn lódì kejì. Ohun kan ni pé owó bébà yìí wọ́n tá a bá fi wé èyí tá a fi ń tẹ ọ̀pọ̀ àwọn ìwé wa, síbẹ̀ ó máa jẹ́ kó rọrùn fáwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti ka ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kí àwọn àwòrán tó wà lódì kejì bébà má sì dí wọn lọ́wọ́.

Àwòrán tó wà lápá ọ̀tún jẹ́ ká rí irú bébà tí wọ́n fi tẹ ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!

 Èèpo ìwé tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Èèpo ìwé tuntun yìí yàtọ̀ sí tàwọn ìwé wa míì torí pé oríṣí láílọ́ọ̀nù kan tó máa tọ́jọ́ la lẹ̀ mọ́ ọn. Dípò ká lo láílọ́ọ̀nù gloss tá a sábà máa ń lò, oríṣi láílọ́ọ̀nù míì tí wọ́n ń pè ní matte tó máa jẹ́ kí àwòrán tó wà lára èèpo ìwé náà jáde dáadáa la lò. Láílọ́ọ̀nù yìí tún máa jẹ́ kó lálòpẹ́, kò sì ní tètè ṣá torí bá a ṣe ń lò ó lóòrèkóòrè. Àmọ́, ìlọ̀po márùn-ún ni owó láílọ́ọ̀nù matte yìí fi wọ́n ju gloss lọ. Torí náà, àwọn ẹ̀ka bíi mélòó kan pawọ́ pọ̀ ra láílọ́ọ̀nù yìí kí wọ́n lè rà á ní ẹ̀dínwó.

Wọ́n fi láílọ́ọ̀nù fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo èèpo ìwé náà

 Kí nìdí tá a fi lo àwọn ohun èlò ìtẹ̀wé tó wọ́n gan-an yìí? Arákùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka IPD sọ pé: “A fẹ́ kí ìwé yìí lálòpẹ́ gan-an, a sì fẹ́ kí àwọ̀ ẹ̀ wà bá a ṣe tẹ̀ ẹ́ láìka bá a ṣe ń lò ó déédéé sí.” Eduardo tó ń ṣiṣẹ́ ní Ọ́fíìsì Ìtẹ̀wé ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Brazil sọ pé: “Inú wa dùn gan-an pé ètò Jèhófà lo àwọn ohun èlò ìtẹ̀wé tó jẹ́ ojúlówó kí ìwé yìí lè rẹwà, kó lálòpẹ́, kó sì rọrùn lò. Lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n tún fọgbọ́n lo owó táwọn èèyàn fi ń ṣètìlẹ́yín.”

Bá A Ṣe Tẹ̀wé Lásìkò Àjàkálẹ̀ Àrùn Kòrónà

 A bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! ní March 2021. Àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà ń jà ràn-ìn nígbà yẹn, èyí sì fa ọ̀pọ̀ ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, torí pé a ti Bẹ́tẹ́lì pa, kò ṣeé ṣe fáwọn tó ń tilé wá ṣiṣẹ́ láti wá ṣèrànwọ́ láwọn ilé ìtẹ̀wé wa ní Bẹ́tẹ́lì, a ò sì lè pe àwọn ẹni tuntun wá sí Bẹ́tẹ́lì. Torí náà, a ò láwọn tó pọ̀ tó láti ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ìtẹ̀wé kan, a sì ti àwọn ẹ̀ka ìtẹ̀wé míì pa fúngbà díẹ̀ torí òfin ìjọba.

 Báwo la ṣe borí àwọn ìṣòro yìí? Nígbà tá a láǹfààní láti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀wé, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin láti ẹ̀ka míì ní Bẹ́tẹ́lì wá ràn wá lọ́wọ́ fúngbà díẹ̀. Joel tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka IPD sọ pé: “Bí àwọn ará yìí ṣe yọ̀ǹda ara wọn àti bí wọ́n ṣe múra tán láti kọ́ nǹkan tuntun wà lára ohun tó mú kí iṣẹ́ yìí ṣeé ṣe.”

 Ní báyìí, a ti tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ẹ̀dà ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! láìka àwọn ìṣòro náà sí. Onírúurú àwọn ohun èlò ìtẹ̀wé bíi láílọ́ònù, bébà, yíǹkì, gọ́ọ̀mù àtàwọn nǹkan míì la lò ká lè tẹ ìwé yìí. Láàárín oṣù márùn-ún àkọ́kọ́ tá a bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ ẹ́, a ná ohun tó ju mílíọ̀nù méjì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta owó dọ́là lórí ohun èlò nìkan. Ká lè dín ìnáwó kù, iye ìwé táwọn ìjọ bá nílò nìkan la máa ń tẹ̀.

“Ìwé Yìí Mà Dáa Gan-an O”

 Báwo ni ìwé tuntun yìí ṣe rí lára àwọn akéde tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́? Arákùnrin Paul tó ń gbé ní Ọsirélíà sọ pé: “Inú mi máa ń dùn ní gbogbo ìgbà tí mo bá fẹ́ fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kọ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí pé ó rọrùn lò gan-an. Ìwé yìí fani mọ́ra, ó sì dáa fún ìjíròrò. Àlàyé tó wà nínú ẹ̀ ṣe kedere, ó tún láwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó láwọn fídíò, àwòrán, àtẹ ìsọfúnni àti ohun tó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe. Bí wọ́n ṣe ṣe ìwé yìí mà dáa gan-an o, kódà ó ń jẹ́ kó wù mí láti sunwọ̀n sí i nínú bí mo ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.”

 Ẹnì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Mo fẹ́ràn ìwé tuntun yìí gan-an. Àwọn àwòrán tó wà nínú ẹ̀ máa ń jẹ́ kí n lóye àwọn kókó pàtàkì inú ìwé náà. Àwọn fídíò inú ẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn, ó sì máa ń jẹ́ kí n ṣiṣẹ́ lórí ohun tí mò ń kọ́.” Ẹ̀ẹ̀méjì lọ́sẹ̀ lẹni yìí ń kẹ́kọ̀ọ́, ó sì máa ń wá sípàdé déédéé.

 A ṣì máa tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! jáde ní ọ̀pọ̀ èdè. Kódà ní báyìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti fọwọ́ sí i pé ká tẹ ìwé yìí ní ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́wàá (710) èdè, èyí fi ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ogójì (340) ju iye èdè tá a fi tẹ ìwé Bíbélì Kọ́ Wa lọ!

 Ibo la ti ń rí owó tá a fi ń ṣiṣẹ́ yìí? Àwọn ọrẹ tẹ́ ẹ fi ń ti iṣẹ́ kárí ayé lẹ́yìn ló mú kó ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì jẹ́ pé orí ìkànnì donate.pr418.com lẹ ti fi ránṣẹ́. A mọrírì àwọn ọrẹ tẹ́ ẹ fi ń ṣe ìtìlẹyìn. Àwọn ọrẹ yìí ń jẹ́ ká lè tẹ àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn tó fẹ́ mọ̀ nípa Jèhófà, kí wọ́n lè ‘gbádùn ayé wọn títí láé.’​—Sáàmù 22:26.

a A mú ìwé yìí jáde nígbà ìpàdé ọdọọdún tá a gbé jáde nínú ètò Tẹlifíṣọ̀n JW.