Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká rí àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì tó wúlò fún ìdílé. * Kó o lè rí oríṣiríṣi àwọn àpilẹ̀kọ tó wà fún ìdílé, wo abala Ìgbéyàwó àti Ìdílé.
^ Nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí, a ti yí orúkọ àwọn kan pa dà.
Ìgbéyàwó
Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Ẹnì Kejì Ẹ Bá Hùwà Tó Ń Múnú Bí Ẹ
Dípò tí wàá fi jẹ́ kí ìwà tó ń múnú bí ẹ dá ìjà sílẹ̀, kọ́ bó o ṣe lè máa fi ojú tó yàtọ̀ wo nǹkan.
Bó O Ṣe Lè Máa Ní Sùúrù
Tí èèyàn aláìpé méjì bá fẹ́ra wọn, oríṣiríṣi ìṣòro ló máa yọjú. Sùúrù ṣe pàtàkì kí ìdílé tó lè ṣàṣeyọrí.
Tọkọtaya Aláyọ̀: Ẹ Máa Bọ̀wọ̀ Fúnra Yín
Bíbélì máa jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ara yín tó bá jẹ́ pé ẹ kì í ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Bó O Ṣe Lè Fi Ọ̀wọ̀ Hàn
Fífi ọ̀wọ̀ hàn nínú ìgbéyàwó kì í ṣe ohun téèyàn ń ṣé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ohun téèyàn gbọ́dọ̀ máa ṣe nígbà gbogbo ni. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ò ń bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì rẹ?
Bó O Ṣe Lè Mọyì Ẹnì Kejì Rẹ
Tí ọkọ àti ìyàwó bá ń sapá láti kíyè sí àwọn ànímọ́ tó dáa tí ẹnì kejí wọn ní, àjọgbé wọn máa tura. Báwo lo ṣe lè jẹ́ ẹni tó máa ń fi ìmọrírì hàn?
Ẹ Máa Fìfẹ́ Hàn Sí Ara Yín
Iṣẹ́, àtijẹ àtimu àtàwọn ìṣòro míì lè má jẹ́ kí tọkọtaya ráyè fún ara wọn mọ́. Kí làwọn tọkọtaya lè ṣe kí wọ́n lè máa fìfẹ́ hàn síra wọn bíi ti tẹ́lẹ̀?
Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Fìfẹ́ Hàn Síra Yín
Báwo ni tọkọtaya ṣe lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ara àwọn dénú? Wo àbá mẹ́rin tó dá lórí àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì.
Bí Ìfẹ́ Yín Ṣe Lè Jinlẹ̀ Sí I
Ṣé ìfẹ́ tó o ní fún ọkọ tàbí aya rẹ mú kí ìdílé yín dúró sán-ún?
Fi Iṣẹ́ Sílẹ̀ “Síbi Iṣẹ́”
Àbá márùn-ún tí kò ní jẹ́ kí iṣẹ́ ṣèdíwọ́ fún ìgbéyàwó rẹ.
Bo O Se Le Ni Ajose To Daa Pelu Awon Ana Re
Ohun meta ti ko ni je ki isoro to o ni pelu awon ana re da wahala sile laarin iwo ati oko tabi iyawo re.
Tí Èrò Yín Ò Bá Jọra
Tí tọkọtaya ò bá gbọ́ra wọn yé, báwo ni wọ́n ṣe lè yanjú ẹ̀, kí wọ́n sì wà lálàáfíà pẹ̀lú ara wọn?
Bó o Ṣe Lè Kápá Ìbínú Rẹ
Tó o bá ń gbaná jẹ, ó lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ, tó o bá tún lọ ń di ìbínú sínú ìyẹn náà máa ṣàkóbá fún ẹ. Torí náà kí lo lè ṣe tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ bá múnú bí ẹ gan-an?
Nígbà Tí Àwọn Ọmọ Bá Ti Kúrò Nílé
Kì í rọrùn rárá fún àwọn òbí kan tí àwọn ọmọ bá ti dàgbà tí wọ́n sì ti kúrò nílé. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè kojú àwọn ìṣòro tó máa wáyé nígbà tó bá ti ku àwọn nìkan nínú ilé?
Bí Ọ̀rẹ́ Ìwọ Àtẹnì Kan Bá Ti Ń Wọra Jù
Ṣé o máa ń sọ pé, ‘Ọ̀rẹ́ lásán ni wá?’ Tó bá rí bẹ̀, ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ kó o rí ìdí tí kò fi yẹ kí o ronú bẹ́ẹ̀.
Ohun Táwọn Tọkọtaya Àgbàlagbà Lè Máa Ṣe Tí Wọn Ò Fi Ní Kọra Wọn Sílẹ̀
Kí ló fà á tí àwọn tọkọtaya àgbàlagbà fi ń kọra wọn sílẹ̀? Kí lo lè ṣe tí kò fi ní ṣẹlẹ̀ sí ẹ?
Tí Ẹnì Kan Nínú Ìdílé Bá Ń Mutí Lámujù
Kí lo lè ṣe tí ọtí bá fẹ́ da ìdílé yín rú?
Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Tí Owú Ò Fi Ní Dá Wàhálà Sílẹ̀ Láàárín Yín
Ìgbéyàwó ò lè láyọ̀ tí tọkọtaya bá ń fura síra wọn, tí wọn ò sì fọkàn tán ara wọn. Torí náà, kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa jowú láìnídìí?
Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe Lè Tú Ìgbéyàwó Rẹ Ká
Àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jáwọ́, ko o sì ṣe ohun táá jẹ́ kí àárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ̀ túbọ̀ gún régé.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀
Ẹ Máa Wáyè fún Ara Yín
Tọkọtaya lè wà nínú yàrá kan náà síbẹ̀ kí wọ́n má máa bára wọn sọ̀rọ̀. Báwo ni tọkọtaya ṣe lè máa lo àkókò tí wọ́n bá fi wà pa pọ̀ lọ́nà tó dára jù lọ?
Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Gbà Ẹ́ Lọ́kàn
Bó o ṣe ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lè ṣe ìgbéyàwó rẹ láǹfààní tàbí kó ṣàkóbá fún un. Kí ló ń ṣe fún ìgbéyàwó rẹ?
Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Yanjú Ọ̀rọ̀
Ọ̀nà tí ọkùnrin àti obìnrin ń gbà sọ̀rọ̀ yàtọ̀ síra. Tá a bá lóye àwọn ìyàtọ̀ yìí, aáwọ̀ ò ní máa ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.
Bí Ẹ Ṣe Lè Gbà Fún Ara Yín
Àwọn nǹkan mẹ́rin tó lè ràn ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ lọ́wọ́ láti paná àríyànjiyàn, kẹ́ ẹ sì jọ wá ojútùú sí ìṣòro yín.
Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Bíbá Ara Yín Yan Odì
Báwo làwọn tọkọtaya kan ṣe máa ń bá a débi tí wọn ò fi ní bá ara wọn sọ̀rọ̀, kí ni wọ́n lè ṣe láti yanjú èdèkòyédè náà?
Bí Ẹ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Bíbá Ara Yín Jiyàn
Ṣé ìwọ àti ẹnì kejì rẹ máa ń jiyàn ní gbogbo ìgbà? Wo bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ran ìdílé yín lọ́wọ́.
Bí Ẹ Ṣe Lè Yẹra Fún Sísọ Ọ̀rọ̀ Líle Síra Yín
Kí lo lè ṣe tí ọ̀rọ̀ líle bá ti nípa lórí àjọṣe àárín ìwọ àti ẹnìkejì rẹ?
Bó O Ṣe Lè Tọrọ Àforíjì
Tó bá jẹ́ èmi kọ́ ni mo jẹ̀bi ńkọ́?
Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Dárí Ji Ara Yín
Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún wa láti dárí jini? Wo bí àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́.
Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ
Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Jẹ́ Bàbá Rere
Irú ọkọ tó o bá jẹ́ báyìí náà ni irú bàbá tó o máa dà lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá bímọ.
Ohun Tó Yẹ Kí Àwọn Òbí Mọ̀ Nípa Jẹ́lé-Ó-Sinmi
Bí ara rẹ ní ìbéèrè mẹ́rin kó o fi lè mọ̀ bóyá ó yẹ kó o gbé ọmọ ẹ lọ sí jẹ́lé-ó-sinmi.
Ṣó Yẹ Kí Ọmọ Mi Ní Fóònù?
Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí kó o lè mọ̀ bóyá ìwọ àti ọmọ rẹ ti ṣe tán láti bójú tó ojúṣe náà.
Kọ́ Àwọn Ọmọdé Bí Wọ́n Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Fóònù
Àwọn ọmọdé tó mọ tìfun-tẹ̀dọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé nílò kí àwọn òbí kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè lo fóònù lọ́nà tó dára.
Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Ohun Tó Ń Mú Ọkàn Fà sí Ìṣekúṣe
Àwọn òbí kan rò pé ó máa ṣòro gan-an kí ọmọ kan tó lè rí àwòrán ìṣekúṣe, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ohun tó yẹ kó o mọ̀ àtohun tó yẹ kó o ṣe kó ò lè dáàbò bo ọmọ rẹ.
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Ọmọdé Máa Kàwé—Apá Kìíní: Ìwé Kíkà Tàbí Ìran Wíwò?
Ọ̀pọ̀ ọmọdé máa ń fẹ́ wo fídíò. Báwo làwọn òbí ṣe lè mú káwọn ọmọ túbọ̀ máa kàwé?
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Ọmọdé Máa Kàwé—Apá 2: Ti Orí Ẹ̀rọ Tàbí Tinú Ìwé?
Ṣé ìwé orí ẹ̀rọ ló dá a káwọn ọmọ máa kà, tàbí torí bébà? Méjèèjì ló láǹfààní.
Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Ìròyìn Tó Ń Jáni Láyà
Kí ni àwọn òbí lè ṣe tí ìròyìn ò fi ní máa dẹ́rù ba àwọn ọmọ wọn?
Bi O Se Le Salaye Ohun Ti Iku Je fun Omo Re
Ohun merin to o le se lati dahun ibeere won, ta a si mu ki won fara da a ti eni ti won feran ba ku.
Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ilé Bá Sú Ọmọ Mi?
Tí ọmọ ẹ ò bá jáde nílé, tí kò sì rí nǹkan ṣe, wo àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́.
Àǹfààní Tó Wà Nínú Eré Táá Mú Kí Ọmọdé Ronú
Àǹfààní tó wà níbẹ̀ pọ̀ ju ti àwọn nǹkan téèyàn dìídì ṣètò tàbí kéèyàn kan máa fi tẹlifíṣọ̀n dára yá.
Iṣẹ́ Ilé Ṣe Pàtàkì
Ẹ̀yin òbí, ṣé ó máa ń ṣe yín bíi pé kẹ́ ẹ má ṣe yan iṣẹ́ ilé kankan fún àwọn ọmọ yín? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ kà nípa bí iṣẹ́ ilé ṣe máa mú kí àwọn ọmọ yín ní ìwà àgbà tó sì máa mú kí wọ́n láyọ̀.
Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Máa Ṣe Nǹkan Láṣeyanjú
Tó o bá rí i tíṣẹ́ kan le fún ọmọ ẹ láti ṣe, ṣé wàá sáré lọ bá a ṣe é àbí wàá fìyẹn kọ́ ọ bó ṣe lè borí ohun bá nira?
Bí A Ṣe Lè Ran Awọn Ọmọ Lọ́wọ́ Láti Borí Ìjákulẹ̀
Gbogbo èèyàn ló máa ń ní ìjákulẹ̀. Kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti fojú tó dáa wo ìjákulẹ̀, kó o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ojútùú.
Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Máàkì Rẹ̀ Lè Gbé Pẹ́ẹ́lí
Wo bó o ṣe lè mọ ohun tó fà á gan-an tí ọmọ rẹ fi ń gbòdo wálé, kó o sì jẹ́ kó máa wù ú láti kẹ́kọ̀ọ́.
Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Ọmọ Mi?
Wo ohun mẹ́rin tó o lè ṣe láti kọ́ ọmọ ẹ bó ṣe lè kápá ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ọn.
Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Máa Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ
Àwọn kan ronú pé táwọn bá kọ ara wọn sílẹ̀, ìyẹn á ṣe àwọn ọmọ wọn láǹfààní. Àmọ́ ìwádìí fi hàn pé àkóbá ńlá ló máa ń ṣe.
Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Tó Ń Bàlágà Lọ́wọ́
Ìmọ̀ràn márùn-ún pàtàkì tá a mú látinú Bíbélì lè mú kí àsìkò ìbàlágà náà rọrùn.
Kọ́ Ọmọ Rẹ Nípa Ìbálòpọ̀
Àwọn ọmọdé ti wá ń kó sínú ewu ìbálòpọ̀ ju àtẹ̀yìnwá lọ. Kí ni ohun tó yẹ kó o mọ̀, kí lo sì lè ṣe láti dáàbò ọmọ rẹ̀?
Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Ẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ọtí
Ìgbà wo ló yẹ káwọn òbí bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí, báwo ló sì ṣe yẹ kí wọ́n bá wọn sọ ọ́?
Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà
O máa dáàbò bo ọmọ rẹ tó o bá bá a sọ̀rọ̀ nípa ìkórìíra tí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà máa ń fà ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ orí rẹ̀.
Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kó má sì ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.
Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Moore
Ẹ lè kọ́ àwọn ọmọdé pàápàá láti máa dúpẹ́ bí ẹnì kan bá fún wọn lẹ́bùn tàbí tó ṣe wọ́n lóore.
Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Máa Gbọ́ràn
Tó bá ṣẹlẹ̀ pé gbogbo ìgbà ni ọmọ rẹ máa ń kọ ọ̀rọ̀ sí ẹ lẹ́nu, kí lo lè ṣe? Ohun márùn-ún wà tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Bó O Ṣe Lè Bójú Tó Ọmọ Tó Ń Ṣe Ìjọ̀ngbọ̀n
Kí lo lè ṣe tí ọmọ rẹ bá bẹ̀rẹ̀ ìjọ̀ngbọ̀n? Àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yìí.
Tí Ọmọ Rẹ Bá Ń Purọ́
Kí ló yẹ kó o ṣe bí ọmọ rẹ bá ń purọ́? Àpilẹ̀kọ yìí fún wa ní ìmọ̀ràn Bíbélì lórí bó o ṣe lè kọ́ ọmọ rẹ láti máa sọ òtítọ́.
Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Tó Ti Ń Dàgbà
Bó O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Tó Ti Ń Bàlágà Sọ̀rọ̀
Ṣé ó máa ń sú ẹ tó o bá ń bá ọmọ rẹ tó tí ń bàlágà sọ̀rọ̀? Kí ló máa ń mú kó nira gan-an?
Tí Ọmọ Kan Bá Fẹ́ Pa Ara Rẹ̀
Kí làwọn òbí lè ṣe tí ọmọ wọn bá ń ronú láti para rẹ̀?
Tí Ọmọ Rẹ Bá N Tàpa sí Àṣẹ Rẹ
Má ṣe fi ìwàǹwára sọ pé ọlọ̀tẹ̀ ni ọmọ rẹ. O lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti máa pa àṣẹ rẹ mọ́.
Bí Òbí Ṣe Lè Tọ́ Ọmọ Sọ́nà
Kí nìdí tó fi máa ń rọrùn fáwọn ọmọdé láti ní àjọṣe tó lágbára pẹ̀lú àwọn ojúgbà wọn, tí wọ́n ò sì ní ká ìtọ́sọ́nà àwọn òbí wọn sí?
Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Rẹ Wí
Ara ẹ̀kọ́ ní ìbáwí jẹ́. Àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kọ ọmọ rẹ kó lè máa gbọ́ràn kàkà kó máa ṣe agídí.
Bó O Ṣe Lè Máa Fi Òfin Lélẹ̀ Fún Ọmọ Rẹ Tó Ti Ń Bàlágà
Kí lo lè ṣe tí ọmọ rẹ bá sọ pé òfin rẹ ti le jù
Ṣé Ó Yẹ Kí Ọmọ Mi Lo Ìkànnì Àjọlò?
Àwọn ìbéèrè mẹ́rin tó máa jẹ́ kó o lè ṣe ìpinnu tó dáa.
Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò
Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó má bàa kó sínú ewu ìkànnì àjọlò.
Àwọn Ọ̀dọ́
Bi O Se Le Sakoso Ibinu Re
Ilana Bibeli marun-un to le ran e lowo lati sakoso ibinu re.
Ohun To O Le Se To Ba N Se E Bi I Pe O Ko Ni Ore
Ti inu re ba n baje tori pe o ko loree, nse lo maa n da aisan si e lara, o maa dabi eni to n mu siga meedogun lojumo. Ki lo le se ko ma baa maa se e bi i pe won pa e ti tabi pe o ko loree?
Ìgbà Tó Yẹ Kó O Pa Dà Sọ́dọ̀ Àwọn Òbí Rẹ
Ṣé nǹkan ṣòro fún ẹ nígbà tó filé lẹ̀ láti lọ máa dá gbé? Àwọn ìmọ̀ràn yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Ohun tó o lè ṣe tí àyípadà bá ṣẹlẹ̀
Ìyípadà gbọ́dọ̀ wáyé. Wo ohun tí àwọn kan ti ṣe láti fara dà á.
Nígbà Tí Òbí Ẹnì Kan Bá Kú
Ohun tí kò bára dé ni kí èèyàn pàdánù òbí ẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn náà kì í sì kúrò lọ́kàn bọ̀rọ̀. Kí ló lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti tètè gbé ìbànújẹ́ náà kúrò lọ́kàn?
Kí Làwọn Èèyàn Ń Rí Nínú Eré Tó Léwu?
Inú àwọn ọ̀dọ́ máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá ń ṣe irú àwọn eré báyìí, wọ́n máa ń fẹ́ fi hàn pé koko lara àwọn le bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń ṣe lè pa wọ́n lára. Ṣé ó máa ń wu ìwọ náà láti ṣe irú àwọn eré bẹ́ẹ̀?