Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

CAMILLA ROSAM | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Pinnu Pé Màá Ṣègbọràn sí Jèhófà Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi

Mo Pinnu Pé Màá Ṣègbọràn sí Jèhófà Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi

 Ọdún 1906 làwọn òbí mi àgbà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àìsàn burúkú kan tí wọ́n ń pè ní diphtheria pa ọ̀kan lára ọmọ wọn lọ́dún yẹn. Dókítà wọn tó tójú ọmọ náà fi Bíbélì tù wọ́n nínú, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà máa jí àwọn tó ti kú dìde lọ́jọ́ iwájú. Àṣé Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni dókítà náà, ìyẹn orúkọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ lákòókò yẹn. Ọ̀rọ̀ tí dókítà náà sọ wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an. Bó ṣe di pé àwọn òbí mi àgbà, ìyá mi àti ẹ̀gbọ́n ìyá mi di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn.

 Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn mọ̀lẹ́bí mi fi fìtara sin Jèhófà. Kódà, àwọn obìnrin yìí wà lára àwọn tó ń bójú tó èrò nígbà tí wọ́n ṣàfihàn “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá” nílùú Chicago, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn mọ̀lẹ́bí mi láwọn ò sin Jèhófà mọ́, ló bá ku màámi nìkan tó ń sin Jèhófà. Ẹ̀yin náà mọ bó ṣe máa rí lára ìyá mi. Kò rọrùn fún wọn rárá torí gbogbo wọn mọwọ́ ara wọn gan-an nínú ìdílé wọn. Àmọ́ màámi ò fi ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn pè, wọ́n dúró lórí ìpinnu wọn, ohun tí wọ́n ṣe yẹn sì wú mi lórí gan-an. Àpẹẹrẹ bàbá mi náà ràn mí lọ́wọ́ torí pé àwọn náà ò kẹ̀rẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn Jèhófà.

Fọ́tò ìdílé wa lọ́dún 1948

 Ọdún 1927 ni wọ́n bí mi, èmi sì ni àkọ́bí nínú ọmọ mẹ́fà táwọn òbí mi bí. Gbogbo wa pátá là ń sin Jèhófà. Iṣẹ́ káfíńtà ni bàbá mi ń ṣe, ìgbèríko ìlú Chicago là ń gbé, ibẹ̀ sì tù wá lára gan-an. A ní ọgbà ńlá kan tá a gbin ewébẹ̀ àtàwọn nǹkan oko míì sí, a sì ń sin adìyẹ àti pẹ́pẹ́yẹ.

 Mo fẹ́ràn kí n máa ṣiṣẹ́. Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ilé tí mo sì máa ń ṣe ni kí n rán ìbọ̀sẹ̀. Àwọn èèyàn kì í sábà rán ìbọ̀sẹ̀ lónìí. Àmọ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún, wọn kì í sọ ìbọ̀sẹ̀ tó bá ti ya nù. Ńṣe ni wọ́n máa ń fi abẹ́rẹ́ àti òwú gán an pọ̀. Inú mi dùn pé mo kọ́ bí wọ́n ṣe ń ránṣọ nígbà yẹn torí pé iṣẹ́ yẹn wá pa dà wúlò fún mi nígbà tó yá.

Àwọn Òbí Mi Fi Àpẹẹrẹ Tó Dáa Lélẹ̀

 Bàbá mi rí i dájú pé a fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Jèhófà nínú ìdílé wa. Torí náà, gbogbo ìpàdé la máa ń lọ, a tún máa ń wàásù déédéé, a sì máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. Láwọn ìrọ̀lẹ́ Sátidé, a máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ la sì máa ń lò.

 Bàbá mi fi àpótí kan tó ń lo iná sójú wíńdò pálọ̀ wa ká lè máa fi jẹ́rìí fáwọn aládùúgbó wa. Àwọn ará kan ló ṣe é, ó sì máa ń polówó àsọyé kan tàbí ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde wa. Iná tó wà nínú àpótí náà máa ń ṣẹ́jú léraléra, ìyẹn sì máa ń pe àfiyèsí àwọn tó ń kọjá-lọ kọjá-bọ̀. Bàbá mi tún fi méjì lára ohun tí wọ́n ṣe yẹn sára ọkọ̀ wa.

Màmá mi mú wa lọ sóde ìwàásù, a sì gbé ẹ̀rọ giramafóònù dání

 Bàbá mi fi ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn kọ́ àwa ọmọ wọn pé ó ṣe pàtàkì ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà. Màmá mi náà sì tì wọ́n lẹ́yìn ní gbogbo ọ̀nà. Àbúrò mi obìnrin tó kéré jù ṣì wà lọ́mọ ọdún márùn-ún nígbà tí ìyá mi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà (ìyẹn àwọn tó máa ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wọn wàásù), wọ́n sì ṣiṣẹ́ náà jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fáwọn òbí tó fún mi.

 Bí nǹkan ṣe rí nígbà yẹn yàtọ̀ sí bó ṣe rí lóde òní. Torí pé a ò ní tẹlifísọ̀n, ńṣe lèmi àtàwọn àbúrò mi máa ń jókòó sílẹ̀, àá sì máa gbọ́ àwọn ètò alárinrin tí wọ́n ń ṣe lórí rédíò. Ní pàtàkì jù, ìdílé wa máa ń gbádùn àwọn ètò tó dá lórí Bíbélì tí ètò Jèhófà máa ń gbé jáde lórí rédíò.

Àpéjọ Agbègbè, Ẹ̀rọ Giramafóònù Àtàwọn Àkọlé Gàdàgbà

 A fẹ́ràn ká máa lọ sí àpéjọ agbègbè àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní àpéjọ agbègbè tá a ṣe lọ́dún 1935, wọ́n túbọ̀ tàn mọ́lẹ̀ sí ohun tó wà nínú Ìfihàn 7:9, 14. A wá kẹ́kọ̀ọ́ pé inú Párádísè orí ilẹ̀ ayé ni “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó la “ìpọ́njú ńlá” já máa gbé. Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn òbí mi máa ń jẹ búrẹ́dì, wọ́n sì máa ń mu wáìnù nígbà Ìrántí Ikú Kristi. Àmọ́ lẹ́yìn àpéjọ yẹn, màámi ò jẹ ẹ́ mọ́ torí wọ́n rí i pé àwọn ò sí lára àwọn tó máa bá Kristi jọba lọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, orí ilẹ̀ ayé làwọn nírètí láti máa gbé títí láé. Bó ṣe di pé bàbá mi nìkan ló ń jẹ ẹ́ nìyẹn.

 Ní àpéjọ agbègbè tá a ṣe nílùú St. Louis, ní ìpínlẹ̀ Missouri, lọ́dún 1941, Arákùnrin Joseph Rutherford tó ń bójú tó iṣẹ́ wa nígbà yẹn mú ìwé kan tá a ṣe fáwọn ọmọdé jáde, ìyẹn Children. Àtẹ́wọ́ táwọn ará pa lọ́jọ́ náà kúrò ní kèrémí! Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14) ni mí nígbà yẹn, ọdún kan ṣáájú sì ni mo ṣèrìbọmi. Mò ṣì máa ń rántí bí mo ṣe tò sórí ìlà pẹ̀lú àwọn ọmọ míì, tí mo sì ń lọ sórí pèpéle láti gba ẹ̀dà tèmi.

Èmi àti Lorraine lọ́dún 1944

 Bá a ṣe ń wàásù nígbà yẹn yàtọ̀ sí bó ṣe rí lóde òní. Láwọn ọdún 1930, a máa ń lo àwọn ẹ̀rọ giramafóònù kékeré láti gbé àwọn àsọyé Bíbélì sétígbọ̀ọ́ àwọn tá à ń bá sọ́rọ̀. Ká tó kan ìlẹ̀kùn ẹni tá a fẹ́ bá sọ̀rọ̀, àá kọ́kọ́ rí i dájú pé a gbé ọwọ́ abẹ́rẹ́ rẹ̀ síbi tó tọ́ gẹ́lẹ́ létí àwo náà. Tí onílé bá ti ṣílẹ̀kùn, a máa sọ̀rọ̀ ṣókí, a máa wá jẹ́ kó gbọ́ àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́rin àtààbọ̀ náà lórí àwo, lẹ́yìn náà, a máa fún un ní ìwé wa. Àwọn tó wà ládùúgbò wa máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. Mi ò rántí pé ẹnikẹ́ni tiẹ̀ sọ̀rọ̀ tí ò dáa sí wa. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), bàbá mi fún mi ní ẹ̀rọ giramafóònù tèmi. Inú mi máa ń dùn bí mo ṣe ń lò ó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Èmi àti arábìnrin àtàtà kan tó ń jẹ́ Lorraine la sì jọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

 Nígbà yẹn, a tún máa ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti wàásù lójú pópó. Ṣe la máa ń gbé àwọn àkọlé méjì sí èjìká, ọ̀kan máa kọjú síwájú ìkejì sì máa kọjú sẹ́yìn. Ohun tí wọ́n sì máa ń kọ sára àkọlé náà ni “Ìsìn Jẹ́ Ìdẹkùn àti Wàyó” àti “Sin Ọlọ́run àti Kristi Ọba.”

Fọ́tò tá a yà níbi tá a ti ń wàásù pẹ̀lú àkọlé tá a gbé kọ́rùn

 Àwọn ohun tá à ń kọ́ nípàdé ti múra wa sílẹ̀ de àtakò tó ṣeé ṣe ká kojú àtohun tá a máa sọ ká lè gbèjà ìgbàgbọ́ wa. Kò sì pẹ́ tí àtakò náà fi bẹ̀rẹ̀. Mo rántí pé lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tá a lọ pín ìwé ìròyìn nílé ìtajà ńlá kan térò pọ̀ sí, àwọn ọlọ́pàá mú wa, wọ́n sì fi mọ́tọ̀ kó wa lọ sí àgọ́ wọn. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí, wọ́n dá wa sílẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí múnú wa dùn, torí àǹfààní là kà á sí pé wọ́n ṣenúnibíni sí wa torí pé à ń ṣègbọràn sí Jèhófà.

Mo Ṣègbéyàwó, Mo Lọ sí Gílíádì, Wọ́n sì Pe Ọkọ Mi fún Iṣẹ́ Ológun

Èmi àti Eugene lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa

 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Lorraine mú mi mọ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Eugene Rosam, àpéjọ kan tí wọ́n ṣe nílùú Minneapolis ìpínlẹ̀ Minnesota làwọn méjèèjì ti pàdé. Agbègbè Key West nílùú Florida ni Eugene dàgbà sí. Nígbà tó ku díẹ̀ kó parí ilé ẹ̀kọ́ girama, wọ́n lé e kúrò nílé ìwé torí pé ó kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ayẹyẹ kan tí wọ́n fi ń gbé orílẹ̀-èdè ẹni ga. Kò tiẹ̀ fàkókò ṣòfò, kíá ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lọ́jọ́ kan, ó pàdé ọmọbìnrin kan tí wọn ti jọ fìgbà kan rí wà ní kíláàsì. Ó ya ọmọbìnrin náà lẹ́nu pé bí ìwà Eugene ṣe dáa tó wọ́n lé e kúrò nílé ìwé. Àmọ́, bó ṣe fara balẹ̀ fi Bíbélì dá a lóhùn jẹ́ kí ọmọbìnrin náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn ò rẹyìn, ọmọbìnrin náà ṣèrìbọmi, ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Nígbà tá a wà ní Key West lọ́dún 1951

 Èmi àti Eugene ṣègbéyàwó lọ́dún 1948. A sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wa lọ nílùú Key West. Nígbà tó yá, wọ́n pè wá sí kíláàsì kejìdínlógún tí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. A sì kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1952. Wọ́n kọ́ wa ní èdè Sípáníìṣì ní ilé ẹ̀kọ́ náà. Torí náà, a ti ń retí pé orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì la ti máa lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Àmọ́, ibi tá a fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, àsìkò tá a wà ní ilé ẹ̀kọ́ yẹn gan-an ni wọ́n ń jagun ní Kòríà, wọ́n sì pe ọkọ mi pé kó wá wọṣẹ́ ológun. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí yà wá lẹ́nu torí ọkọ mi tí gba àṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba pé kò ní wọṣẹ́ ológun látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì. Torí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, wọ́n ní ká dúró sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìjákulẹ̀ ńlá lèyí jẹ́ fún mi, mo sunkún débi pé ojú mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yọ bọ́. Ọdún méjì kọjá kí ìjọba tó gbà láti yọ̀ǹda ọkọ mi lẹ́nu iṣẹ́ ológun. Ìjákulẹ̀ yìí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan pé tí ọ̀nà kan bá dí, Jèhófà lè la ọ̀nà míì, ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn. Ó kàn lè gba pé ká ní sùúrù.

Fọ́tò àwọn tá a jọ lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì

A Ṣiṣẹ́ Arìnrìn-Àjò, A sì Lọ sí Kánádà!

 Lẹ́yìn tá a ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Ṣípáníìṣì ní ìlú Tucson, ní ìpínlẹ̀ Arizona, wọ́n ní ká lọ ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká lọ́dún 1953. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká nílùú Ohio, California àti New York City. Nígbà tó wá di ọdún 1958, ètò Ọlọ́run sọ pé ká lọ ṣiṣẹ́ alábòójútó agbègbè a nílùú California àti Oregon. Ní gbogbo ìgbà yẹn, ilé àwọn ará la máa ń dé sí. Nígbà tó di ọdún 1960, a lọ sí orílẹ̀-èdè Kánádà, wọ́n sì ní kí Eugene ọkọ mi máa ṣe olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ fáwọn alábòójútó nínú ìjọ. Ibẹ̀ la sì wà títí di ọdún 1988.

 Ọ̀kan lára àsìkò tí mi ò lè gbàgbé nígbà tá a wà ní Kánádà ni ìgbà tí èmi àti arábìnrin kan pàdé ìdílé kan bá a ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé. Gail tó jẹ́ ìyá wọn la kọ́kọ́ pàdé, ó sì sọ fún wa pé àwọn ọmọ òun ń bínú pé bàbá ìyá wọn kú. Wọ́n bi ìyá wọn pé: “Kí nìdí tí wọ́n fi kú?” “Ibo sì ni wọ́n lọ?” Gail ò mohun tó fi máa dá wọn lóhùn. A wá fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn, a sì tù ú nínú.

 Lásìkò yẹn, ọkọ mi ń bẹ ìjọ tó wà níbẹ̀ wò, torí náà ọ̀sẹ̀ kan péré la lò níbẹ̀. Àmọ́, arábìnrin tá a jọ ṣiṣẹ́ pa dà lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Gail. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Gail àti Bill ọkọ ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn ọmọkùnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà, ìyẹn Christopher, Steve àti Patrick sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Alàgbà ni Chris lórílẹ̀-èdè Kánádà. Olùkọ́ ni Steve ní ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run nílùú Palm Coast, ní ìpínlẹ̀ Florida. Patrick sì jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní orílẹ̀-èdè Thailand. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ làwa àti ìdílé yẹn. Inú mi sì dùn pé Jèhófà jẹ́ kémi náà lọ́wọ́ sí bí wọ́n ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́!

A Ṣèbẹ̀wò Sáwọn Ilé Ìwòsàn, A sì Bẹ̀rẹ̀ Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn

 Bá a ṣe ń báṣẹ́ wa lọ ní Kánádà, Jèhófà fún ọkọ mi ní ànfààní iṣẹ́ kan tó méso jáde. Ẹ jẹ́ kí ń sọ fún yín nípa ẹ̀.

 Láwọn ọdún kan sẹ́yìn, àwọn èèyàn ò lóye ìdí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í gbẹ̀jẹ̀, ìyẹn sí mú kí wọ́n máa sọ ohun tí ò dáa nípa wa. Àwọn oníròyìn káàkiri Kánáda bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa wa pé àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kú torí pé àwọn òbí wọn ò jẹ́ kí wọ́n gbẹ̀jẹ̀. Ọkọ mi wà lára àwọn tí ètò Ọlọ́run lò láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé irọ́ gbuu làwọn ẹ̀sùn yẹn.

 Ká tó lọ sí àpéjọ àgbáyé tá a ṣe ní Buffalo, New York lọ́dún 1969, ọkọ mi àtàwọn arákùnrin mélòó kan lọ sáwọn ilé ìwòsàn kan lágbègbè yẹn. Wọ́n ṣàlàyé fáwọn dókítà tó wà níbẹ̀ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000) àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti orílẹ̀-èdè Kánádà àti Amẹ́ríkà máa wá sí àpéjọ yẹn. Ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, tí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀, àwọn dókítà náà á ti mọ̀ pé a kì í gbẹ̀jẹ̀, àlàyé tí wọ́n ṣe sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìpinnu yẹn bọ́gbọ́n mu. Àwọn arákùnrin yìí tún fún àwọn dókítà náà láwọn ìwé ìròyìn táwọn dókítà mọyì gan-an. Àwọn ìwé yìí sọ bá a ṣe lè tọ́jú aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀. Inú àwọn dókítà náà dùn sí ìsọfúnni yìí, bí ọkọ mi àtàwọn arákùnrin míì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ilé ìwòsàn tó wà ní Kánádà nìyẹn. Wọ́n sì tún dá àwọn alàgbà lẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí wọ́n lè ṣe tí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀.

 Ohun tí wọ́n ṣe yẹn ran àwọn ará lọ́wọ́ gan-an. Kódà, ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ló wá bí ohun kan tá ò lérò rárá. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ẹ̀ fún yín?

Mo gbádùn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń ránṣọ

 Láwọn ọdún 1980, Arákùnrin Milton Henschel tó wà ní oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn, New York pe ọkọ mi. Ó ṣàlàyé fún ọkọ mi pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí fẹ́ kí ètò kan tí wọ́n ti ń ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dé àwọn ibòmíì. Ètò náà dá lé bí wọ́n ṣe máa fún àwọn dókítà ní ìsọfúnni sí i lórí bí wọ́n ṣe lè tọ́jú aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀. Torí náà, èmi àti ọkọ mi kó wá sí Brooklyn. Nígbà tó sì di January 1988 Ìgbìmọ̀ Olùdarí dá ẹ̀ka kan sílẹ̀ ní oríléeṣẹ́ tí wọ́n ń pè ní Ẹ̀ka Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, wọ́n ní kí ọkọ mi àti àwọn arákùnrin méjì míì dá àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nígbà tó sì yá wọ́n lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì. Bó ṣe di pé wọ́n dá Ẹ̀ka Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn sílẹ̀ làwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nìyẹn, tí wọ́n sì tún dá àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn sílẹ̀ láwọn ìlú káàkiri. Ká sòótọ́, àwọn ara àtàwọn ọmọ wọn tó ti jàǹfààní ètò yìí kò ṣeé kà! Ṣe ni Jèhófà fi ètò onífẹ̀ẹ́ yìí bù kún àwọn èèyàn rẹ̀. Tí ọkọ mi bá ń ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó sì ń bẹ àwọn ilé ìwòsàn wo ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tá a bá lọ, èmi máa ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń ránṣọ tàbí ní ilé ìdáná.

Kíláàsì kan tí wọ́n ṣètò fún àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn ní Japan

Ìṣòro Tó Le Jù Tí Mo Dojú kọ

 Ní ọdún 2006, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó kó ẹ̀dùn ọkàn bá mi, Eugene ọkọ mi àtàtà kú, ó sì dùn mi wọra gan-an. Àdánù ńlá ló jẹ́ téèyàn tó o nífẹ̀ẹ́, tẹ́ ẹ sì jọ mọwọ́ ara yín bá kú! Ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro yìí. Bí àpẹẹrẹ, mo máa ń gbàdúrà mo sì máa ń ka Bíbélì déédéé, ìyẹn ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà dáadáa. Mo máa ń gbádùn ìjọsìn òwúrọ̀ tá à ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì. Mo tún máa ń ka orí Bíbélì tá a gbé ẹ̀kọ́ ojúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan kà. Àǹfààní ni mo ka iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi ní Bẹ́tẹ́lì sí, ìyẹn láti máa ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń ránṣọ. Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, mo láǹfààní láti máa fi aṣọ ṣe ẹ̀ṣọ́ láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní New Jersey àti New York. Àmọ́ ní báyìí, Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Fishkill lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni mo ti ń sìn, àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ni mo sì ń ṣe níbẹ̀. b

 Ohun tí mo ti rí ni pé, kò sóhun tó ṣe pàtàkì tó kéèyàn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kó sì máa ṣègbọràn sí òun àti ètò rẹ̀. (Hébérù 13:17; 1 Jòhánù 5:3) Inú mi sì dùn pé ohun tí èmi àti ọkọ mi gbájú mọ́ nígbèésí ayé wa nìyẹn. Ní báyìí, ó dá mi lójú pé Jèhófà máa fi ìyè ayérayé san wá lẹ́san, èmi àti ọkọ mi sì tún máa pa dà rí ara wa lẹ́ẹ̀kan sí i.​—Jòhánù 5:28, 29.

a Alábòójútó àyíká ló máa ń bẹ àwọn ìjọ wò, ṣùgbọ́n alábòójútó agbègbè máa ń bẹ àyíká wò, ó sì máa ń sọ àsọyé ní àwọn àpéjọ àyíká.

b Ní March 2022, Arábìnrin Camilla Rosam kú lẹ́ni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún (94) nígbà tí à ń kọ àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́.