Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

DAVID MAZA | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Ìṣẹ̀lẹ̀ Burúkú Kan Kó Ẹ̀dùn Ọkàn Bá Wa, àmọ́ A Pa Dà Láyọ̀

Ìṣẹ̀lẹ̀ Burúkú Kan Kó Ẹ̀dùn Ọkàn Bá Wa, àmọ́ A Pa Dà Láyọ̀

Mi ò mọ̀ pé èèyàn lè ní ìdílé aláyọ̀ àfìgbà ti mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí mo ṣe ń fi àwọn ohun tí mò ń kọ́ sílò, bẹ́ẹ̀ ni ìdílé mi túbọ̀ ń tòrò. Ní báyìí èmi, ìyàwó mi àtàwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń fayọ̀ sin Jèhófà pa pọ̀.

Àmọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan ṣẹlẹ̀ sí wa ní April 24, 2004. Kódà òjijì ló bá wa, a ò rò ó tì rárá.

 Mi ò rí àpẹẹrẹ tó dáa kọ́ látọ̀dọ̀ àwọn òbí mi nípa bí mo ṣe lè jẹ́ òbí rere torí gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń bára wọn jà, nígbà tó sì yá, wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀. Torí náà, nígbà tí Kaye ìyàwó mi bí Lauren ọmọbìnrin wa, mi ò mọ bí mo ṣe lè jẹ́ bàbá rere. Nígbà tó yá, a bí Michael ọmọ wa kejì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wù mí kí n jẹ́ bàbá rere, kí n má parọ́, mi ò mọ bí mo ṣe lè ṣe é.

 Mi ò tíì pé ọmọ ogún (20) ọdún tí mo ti ń mu ọtí ní ìmukúmu, bẹ́ẹ̀ ni mò ń lo oògùn olóró. Yàtọ̀ síyẹn, tẹ́tẹ́ títa wá di bárakú fún mi. Àwọn nǹkan tí mò ń ṣe yìí mú kí n ṣe àwọn ìpinnu tí ò dáa, ìgbésí ayé mi ò sì nítumọ̀. Ìwà mi burú débi pé mi ò ṣeé bá gbélé. Kódà, ṣe nìyàwó mi kó àwọn ọmọ wa méjèèjì, ó sì kúrò nílè. Ayé wá tojú sú mi.

 Kò wù mí bí mo ṣe dá nìkan wà, ni mo bá bẹ ìyàwó mi pé kó jọ̀ọ́ kó pa dà sílé. Lásìkò yẹn, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Gloria ti ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ìyàwó mi sọ pé kí n ṣe kó tó lè pa dà sọ́dọ̀ mi? Ṣe ló ní kí n lọ “kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó sọ ò yé mi, mo gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó lè pa dà wá sílé. Ìyẹn ló mú ki ń ní kí Gloria àti Bill ọkọ ẹ̀ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.

Ìjíròrò Tó Yí Ìgbésí Ayé Mi Pa Dà

 Nígbà tí Bill àti Gloria wá sílé wa, bí wọ́n ṣe ń ṣe síra wọn wú mi lórí gan-an. Àsìkò yẹn ni mo wá mọ̀ pé wọ́n ti bí àwọn ọmọ tó tó mi lọ́jọ́ orí, àwọn ọmọ náà sì ń gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀. Fúngbà àkọ́kọ́ láyé mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Bíbélì ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìdílé aláyọ̀.

 Bí wọ́n ṣe bẹ̀ wá wò ṣe mí láǹfààní gan-an, torí a jọ sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro tí mo ní. Wọ́n wá fi ohun tó wà ní Gálátíà 6:7 hàn mí tó sọ pé: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.” Mo wá rò ó lọ́kàn ara mi pé, ‘Ká ní mo ti ń fi ìlànà tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí sílò tí mo bá fẹ́ ṣèpinnu, ayé mi ì bá nítumọ̀ ju báyìí lọ, ìṣòro mi ì bá má sì pọ̀ tó yìí!’

Kaye àti David

 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, tí mo sì ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìyípadà tó jẹ́ káyé mi dáa sí i. Bí àpẹẹrẹ, èmi àtìyàwó mi ò mu sìgá mọ́, kódà mo jáwọ́ pátápátá nínú gbogbo ìwà burúkú tó ti mọ́ mi lára. Lọ́dún 1985, a bí David ọmọ wa kẹta. Ó sì ti mọ́ wa lára láti máa pè é ní Davey. Ní báyìí, mo ti mohun tí mo lè ṣe láti jẹ́ bàbá gidi.

A Jọ Ń Sin Jèhófà Pa Pọ̀

 Èmi àtìyàwó mi rí i pé táwa òbí bá ń sapá láti kọ́ àwọn ọmọ wa kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwa náà á túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run ló ràn wá lọ́wọ́ irú bí ìwé Fifetisilẹ si Olukọ Nla Na! Kò tán síbẹ̀ o, àwọn ìdílé tó wà nínú ìjọ wa jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fún àwa àtàwọn ọmọ wa.

Michael àti Diana ìyàwó ẹ̀

 Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ọmọ wa di aṣáájú-ọ̀nà. Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2004, Lauren wà ní ìjọ tó ń sọ èdè Sípáníìṣì. Nígbà tí Michael fẹ́ gbéyàwó, ó fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀, òun àti Diana ìyàwó ẹ̀ sì ń múra láti lọ sí Guam kí wọ́n lè lọ ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Lásìkò yẹn, Davey ti pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19), òun náà sì ti ń sìn ní Dominican Republic.

 Inú èmi àtìyàwó mi dùn gan-an sí ohun táwọn ọmọ wa yàn láti fayé wọn ṣe. Ọ̀rọ̀ inú 3 Jòhánù 4 ṣẹ sí wa lára tó sọ pé: “Kò sí ohun tó ń mú inú mi dùn bíi kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.” A ò mọ̀ pé ìpè kan péré ló máa yí ìgbésí ayé wa pa dà.

Ìṣẹ̀lẹ̀ Burúkú Kan Tó Bà Wá Lọ́kàn Jẹ́

 Ní April 24, 2004, èmi àti ìyàwó mi lọ jẹ oúnjẹ alẹ́ nílé oúnjẹ kan pẹ̀lú tọkọtaya méjì míì. Mọ́tò mi làwa mẹ́fẹ̀ẹ̀fà gbé lọ torí pé ilé oúnjẹ náà jìnnà ju ọgọ́rùn-ún kìlómítà síbi tá a wà. Lẹ́yìn tá a kúrò níbẹ̀, a lọ sílé oúnjẹ míì ká lè jẹ ìpápánu, bí mo ṣe já àwọn tó kù sílẹ̀, tí mo sì ń wá ibi tí máa gbé mọ́tò mi sí. Ni fóònù mi bá dún, ọ̀rẹ́ mi kan ló pè. Bó ṣe sọ̀rọ̀ jẹ́ kí n mọ̀ pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀.

 Ó sọ pé: “Wàhálà ti ṣẹlẹ̀ o! Ìjàǹbá kan ti ṣẹlẹ̀ sí Davey.”

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọkàn mi ò balẹ̀, mo bi í pé: “Báwo ló ṣe le tó?”

 Kò kọ́kọ́ fẹ́ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún mi. Àmọ́, ó pa dà sọ fún mi pé Davey ti kú.

 Lẹ́yìn tá a sọ̀rọ̀ tán, mo bẹ Jèhófà pé kó fún mi lókun. Ni mo bá wọlé lọ sọ fáwọn tó kù pé ká máa lọ sílé torí ó jọ pé ó fẹ́ rẹ̀ mí díẹ̀. Mi ò fẹ́ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Kaye títí dìgbà tí èmi àti ẹ̀ bá dá wà.

 Ìbànújẹ́ dorí mi kodò ní gbogbo wákàtí kan ààbọ̀ tí mo fi wakọ̀ pa dà sílé. Mò ń wo bí inú ìyàwó mi ṣe ń dùn nígbà tó ń sọ fáwọn tó kù pé Davey ń bọ̀ wá kí wa láìpẹ́. Ní gbogbo àsìkò yẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì mọ̀ pé ọmọ wa ti kú, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti gbọ́, tí wọ́n sì ń fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí mi lórí fóònù láti tù wá nínú.

 A gbé àwọn tọkọtaya tó kù pa dà sílé, àwa náà sì pa dà sílé. Bí ìyàwó mi ṣe wojú mi, ó rí i pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀. Ó wá bi mí pé: “Kí ló ṣe yín?” Mo mọ̀ pé ohun tí màá sọ fún un máa bà á lọ́kàn jẹ́ bó ṣe ba èmi náà lọ́kàn jẹ́ láti nǹkan bíi wákàtí méjì tí mo ti gba ìpè lórí fóònú.

Bá A Ṣe Fara Da Ikú Ọmọ Wa

 Ọ̀pọ̀ ìṣòro ni èmi àtìyàwó mi ti kojú tẹ́lẹ̀ nígbèésí ayé wa, a sì rí bí Jèhófà ṣe ń tu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú. (Àìsáyà 41:10, 13) Àmọ́, tọ̀tẹ̀ yìí yàtọ̀ gan-an. Èrò tó ṣáà ń wá sí mi lọ́kàn ni pé, ‘Kí nìdí tí irú nǹkan báyìí fi ṣẹlẹ̀ sí Davey, ẹni tó ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan fún Jèhófà? Kí nìdí tí Jèhófà ò fi dáàbò bò ó?’

 Ọ̀rọ̀ yìí ba àwọn ọmọ wa tó kù náà nínú jẹ́. Ikú Davey ká Lauren lára gan-an torí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì mú un bí ọmọ. Inú Michael náà bà jẹ́ gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó nǹkan bí ọdún márùn-ún tí Michael ti kúrò nílé, ó mọyì bí àbúrò ẹ̀ ṣe níwà àgbà.

 Àwọn ará ìjọ ò fi wá sílẹ̀ rárá, gbàrà tí ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀rọ̀ náà ṣì gbóná lára ìyàwó mi, àwọn ará ìjọ wá sílé wa láti ṣèrànwọ́, kí wọ́n sì tù wá nínú. (Òwe 17:17) Mi ò lè gbàgbé ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí wa láé!

 Ohun tó ran èmi àti Kaye lọ́wọ́ láti fara da ẹ̀dùn ọkàn wa ni bá a ṣe ń gbàdúrà, tí à ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń lọ sí ìpàdé déédéé. Àwọn nǹkan yìí ò mú ẹ̀dùn ọkàn wa kúrò, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé wọ́n ṣe pàtàkì kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára.​—Fílípì 3:16.

Lauren àti Justin ọkọ ẹ̀

 Nígbà yẹn, Michael àti Diana kó wá sí tòsí wa, Lauren náà sì pa dà sí ìjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì tá a jọ wà tẹ́lẹ̀. Bí gbogbo wa ṣe wà pa pọ̀ fún ọdún mélòó kan jẹ́ ká lè máa gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lára díẹ̀díẹ̀. Nígbà tó yá, Lauren ṣègbéyàwó, Justin tó jẹ́ ọkọ ẹ̀ náà sì ràn wá lọ́wọ́ gan-an.

Ìrìn Àjò Tó Le Gan-an

 Láìpẹ́ sígbà tí Davey kú, ìdílé wa ṣe nǹkan kan ká lè gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lára. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, ohun tá a ṣe yẹn ló ràn wá lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí ìyàwó mi sọ ọ́ fún yín.

 “Nígbà tí ọkọ mi sọ fún mi pé Davey ti kú, gbogbo nǹkan tojú sú mi. Ẹ̀dùn ọkàn mi lágbára gan-an débi pé mi ò lè ṣe àwọn nǹkan tí mo máa ń ṣe lójoojúmọ́. Ẹkún ni ṣáá. Kódà nígbà míì, inú máa ń bí mi sí Jèhófà, mo sì máa ń kanra mọ́ gbogbo èèyàn. Ó wá dà bíi pé mi ò mọ ohun tí mò ń ṣe mọ́.

 “Ó wù mí kí n lọ sí Dominican Republic. Ibẹ̀ ni Davey ń gbé, tó sì ti ń sin Jèhófà kó tó kú. Àmọ́, ọ̀rọ̀ yẹn ṣì gbóná lára mi nígbà yẹn, mi ò sì lágbára láti rìnrìn àjò náà.

 “Obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ wa sọ fún mi pé àwọn ọ̀rẹ́ Davey tó wà ní Dominican Republic náà ń ṣọ̀fọ̀ ẹ̀, wọ́n á sì fẹ́ mọ àwọn ará ilé Davey. Ohun tó sọ yẹn fún mi lókun láti rìnrìn àjò náà.

 Bí ìdílé wa ṣe lọ sí Dominican Republic yẹn ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Ohun tá a gbọ́ nípa Davey jẹ́ ká mọ̀ pé tọkàntọkàn ló sin Jèhófà. Alàgbà kan ṣoṣo tó wà ní ìjọ tí Davey tí sìn sọ pé gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n bá fún un ló máa ń ṣe.

 “Nígbà tá a lọ sí àdúgbò tí Davey gbé, àwọn kan wá bá wa, wọ́n sì sọ àwọn nǹkan dáadáa tó ti ṣe fáwọn. Mo mọ̀ pé èèyàn dáadáa ni, àmọ́ àwọn nǹkan tí mo tún gbọ́ jẹ́ kí n mọ̀ pé ọmọ mi sapá gan-an láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù.

Nígbà tí Davey ń sìn ní Dominican Republic

 “A tún lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin kan tí Davey ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àìsàn ò jẹ́ kí ọkùnrin náà lè dìde lórí bẹ́ẹ̀dì, inú yàrá kékeré kan ló sì ń gbé. Ọkùnrin náà ò ní nǹkan kan, àwọn ará ìjọ sọ fún wa pé Davey ò fọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣeré, ó sì bọ̀wọ̀ fún un. Ìyẹn mórí mi wú gan-an!

 “Ìrìn àjò yìí ló le jù nínú gbogbo èyí tí mo ti rìn. Àmọ́, ó jẹ́ kí ìdílé wa lè ṣọ̀fọ̀ Davey pẹ̀lú àwọn tó mọ̀ ọ́n, ká sì fi ìrètí ọjọ́ iwájú tu ara wa nínú. Ìyẹn jẹ́ kára tù wá dé ìwọ̀n àyè kan.”

Àwọn Tí Ìrírí Davey Ràn Lọ́wọ́

 Àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn Ji! March 8, 2005 sọ̀rọ̀ nípa ikú Davey àti bó ṣe sìn ní Dominican Republic. Nígbà tí àpilẹ̀kọ yẹn jáde, ìdílé wa ò mọ bó ṣe máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tó. Bí àpẹẹrẹ, ní May 2019, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Nick kàn sí wa, ó sì sọ pé:

 “Ní ìparí ọdún 2004, mo wà nílé ẹ̀kọ́ gíga, mi ò sì ronú àtifáyé mi ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Inú mi ò dùn rárá. Mo wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè lo ìgbà ọ̀dọ́ mi lọ́nà tó dára jù. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo ka ìrírí Davey nínú ìwé ìròyìn Jí! Mo sì rí i pé ohun tí mo nílò gan-an nìyẹn!

 Ni mo bá fi ilé ẹ̀kọ́ gíga sílẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Mo tún pinnu pé màá kọ́ èdè Sípáníìṣì, kí n sì lọ sìn nílẹ̀ àjèjì. Kò pẹ́ kò jìnnà, mo lọ sìn ní orílẹ̀-èdè Nicaragua, èmi àtìyàwó sì lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere. Tí wọ́n bá bi mí nípa ohun tó jẹ́ kí n di aṣáájú-ọ̀nà, ìrírí Davey ni mo máa ń sọ.”

 Ohun kan tún ṣẹlẹ̀ tó yà wá lẹ́nu. Nígbà Àpéjọ Àgbáyé tá a ṣe nílùú Buenos Aires lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà lọ́dún 2019, a pàdé arábìnrin kan tó ń jẹ́ Abi. Inú òtẹ́ẹ́lì kan náà la jọ wà. Ìfẹ́ tí arábìnrin yìí fi hàn sí wa wú wa lórí gan-an. Ìyẹn sì jẹ́ kí èmi àtìyàwó mi rántí àwọn ìwà tó dáa tí Davey ní.

Ohun tí Davey ṣe ló mú kí Abi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, kó sì lọ sìn níbi tí àìní wà

 Nígbà tá a pa dà sí yàrá òtẹ́ẹ̀lì wa, a fi ìlujá àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn Ji! nípa Davey ránṣẹ́ sí Abi. Kò pẹ́ rárá tó fi fèsì. Ó wù ú láti bá wa sọ̀rọ̀ ní kíákíá, a wá pàdé níbì kan. Bá a ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ báyìí ni Abi bú sẹ́kún, ó sọ fún wa pé ìrírí Davey ló mú kóun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní September 2011, ẹ̀yìn ìyẹn lòun lọ sìn ní ìpínlẹ̀ kan tó wọnú gan-an. Ó sọ pé: “Mo máa ń ka ìrírí Davey lákàtúnkà nígbàkigbà tí mo bá ní ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ mi.” Ohun tó tiẹ̀ tún yà wá lẹ́nu ni pé ó ní ẹ̀dà àpilẹ̀kọ náà lọ́wọ́!

 Àwọn ìrírí tá a ní yìí jẹ́ ká rí i pé a wà lára ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé. Ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà ṣàrà ọ̀tọ̀, kò sí ibi tá a tún ti lè rí irú ẹ̀ láyé!

 Bá a ṣe mọ̀ pé ìrírí Davey ọmọ wa ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní tu èmi àtìyàwó mi nínú gan-an. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn fáwọn ọ̀dọ́ tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Lọ́nà kan tàbí òmíì, bí wọ́n ṣe ń lo gbogbo okun wọn fún Jèhófà ń fún àwọn míì níṣìírí kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn. Àpẹẹrẹ àtàtà ní wọ́n jẹ́.

“Lójú Rẹ̀, Gbogbo Wọn Wà Láàyè”

 Jésù fa ọ̀rọ̀ Jèhófà yọ ní Lúùkù 20:37 nígbà tó sọ pé òun jẹ́ “Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù.” Jèhófà ò sọ pé ìgbà tí wọ́n ṣì wà láàyè nìkan lòun jẹ́ Ọlọ́run wọn, àmọ́ òun ṣì jẹ́ Ọlọ́run wọn kódà nígbà tí wọ́n ti kú! Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Jésù jẹ́ kó ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tó sọ ní ẹsẹ kejìdínlógójì pé: “Torí lójú rẹ̀, gbogbo wọn wà láàyè.”

 Òótọ́ kan ní pé, Jèhófà ń wo gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti kú bíi pé wọ́n ṣì wà láàyè; ìyẹn sì jẹ́ ká gbà pé dájúdájú ó máa jí wọn dìde! (Jóòbù 14:15; Jòhánù 5:28, 29) Torí náà, ó dá mi lójú pé ohun tí Jèhófà máa ṣe fún Davey àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ tó ti kú náà nìyẹn.

 Bó tíẹ̀ jẹ́ pé ó wù mí kí n tún pa dà rí Davey, ohun tó wù mí jù ni pé kí òun àti Kaye tún jọ wà pa pọ̀. Ìbànújẹ́ ńlá ni ikú ọmọ wa fà fún ìyàwó mi, mí ò tíì rí ẹni tó ní irú ẹ̀dùn ọkàn tó lé kenkà bíi tiẹ̀ láyé mi. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ tó wà nínú Lúùkù 7:15 tó sọ pé: “Ọkùnrin tó ti kú náà wá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, Jésù sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.

 Nígbà tó di September 2005, èmi náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ní báyìí, èmi, ìyàwó mi àtàwọn ọmọ wa títí kan àwọn ẹnì kejì wọn la jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àǹfààní ńlá sì nìyẹn jẹ́ fún mi. Inú mi dùn pé èmi àti ìdílé mi jọ ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, a jọ ń ran ara wa lọ́wọ́, a sì ń fojú sọ́nà fún ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí níbi tá a ti máa wà pẹ̀lú Davey ọmọ wa ọ̀wọ́n.