Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JAY CAMPBELL | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Ti Wá Dẹni Iyì

Mo Ti Wá Dẹni Iyì

 Ojú máa ń tì mí gan-an nígbà tí mo wà lọ́mọdé. Inú ilé ni mo máa ń jókòó sí kí àwọn èèyàn má bàa rí mi, ṣe ló sì máa ń ṣe mi bíi pé mi ò já mọ́ nǹkankan. Mi ò kì í fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba, ìdí ni pé ẹ̀rù máa ń bà mí torí mo gbà pé àwọn èèyàn ò ní bọ̀wọ̀ fún mi, wọn ò sì ní fojú èèyàn gidi wò mí. Ohun tó fà á rèé.

 Ní August 1967, ọmọ ọdún kan ààbọ̀ ni mí nígbà tí akọ ibà kọ lù mí. Kó tó dìgbà yẹn, koko lara mi le. Bí mo ṣe jí láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ẹsẹ̀ mi ti di jọwọrọ. Èsì àyẹ̀wò tá a ṣe nílé ìwòsàn nílùú Freetown, lórílẹ̀-èdè Sierra Leone fi hàn pé mo ti ní àìsàn rọpárọsẹ̀ tó máa ń ṣe àwọn ọmọ tọ́jọ́ orí wọn wà lọ́dún márùn-ún sísàlẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn dókítà tó ń to eegun ṣe gbogbo tí wọ́n lè ṣe kí n lè pa dà rìn, pàbó ló ni gbogbo ẹ̀ já sí. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ẹsẹ̀ mi bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ, mi ò sì lè dá dúró mọ́. Torí pé aláàbọ̀ ara ni mí, Bàbá mi sábà máa ń sọ pé, “Ṣé ọmọ nìwọ yìí ṣá?” Tí mo bá fẹ́ rìn, ìdí ni mo fi ń wọ́, èyí sì máa bà mí nínú jẹ́ gan-an, gbogbo nǹkan ló tojú sú mi.

Mò Ń Wọ́ Nílẹ̀ Bí Mo Ṣe Ń Dàgbà

 Agboolé tí àwọn tálákà bíi tiwa pọ̀ sí ni mo gbé dàgbà, èmi àti màámi la sì jọ ń gbé. Lóòótọ́ àwọn èèyàn fẹ́ràn mi, àmọ́ bàbá mi kì í fẹ́ rí mi sójú rárá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ṣe ló ń wù mí kí wọ́n máa kẹ́ mi lójú kẹ́ mi nímú. Èrò àwọn kan ni pé ọ̀rọ̀ mi kì í ṣojú lásán. Àwọn kan tún sọ pé kí màámi lọ jù mi sẹ́nu ọ̀nà àwọn tó ń tọ́jú àwọn ọmọ aláàbọ̀ ara. Ìdí tí wọ́n sì fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé màámi ò ní lè máa da ara wọn láàmú lórí mi mọ́. Àmọ́ màámi ò gbà fún wọn, wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tọ́jú mi.

 Ara mi máa ń bó yánna-yànna tí mo bá ń fìdí wọ́ torí pé mi ò lè rìn, mi ò sì lè dìde dúró. Torí kí n lè dín bí mo ṣe máa ń fara pa kù, mo máa ń wọ aṣọ tó nípọn. Mo tún máa ń wọ sílípáàsì sọ́wọ́ bí ìbọ̀wọ́ kí ọwọ́ mi má bàa bó. Nígbà tó yá, mò ń lo igi kan tó ṣeé kọwọ́ bọ láti fi wọ́. Kì í rọrùn fún mi láti wọ́ kiri, ńṣe ni ẹ̀yìn máa ń ro mí gan-an. Kí n tó wọ́ láti ibì kan síbòmíì ìnira ló jẹ́, bí ìgbà téèyàn ṣe iṣẹ́ àṣekára ni. Ńṣe ni apá àti èjìká máa ń ro mí bí mo ṣe ń wọ́ kiri, èyí sì máa ń jẹ́ kó nira fún mi láti máa lọ káàkiri ládùúgbò. Ìyẹn ni ò jẹ́ kí n lè lọ síléèwé tí mi ò sì lè báwọn ọmọdé bíi tèmi ṣeré. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń rò ó pé ká ní kì í ṣe pé màámi dúró tì mí ni, ayé ò bá nira fún mi gan-an.

 Mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́, kó má jẹ́ kí n máa tọrọ báárà. Mo mọ̀ pé tí mo bá ń sin Ọlọ́run bó ṣe tọ́, tí mo sì sún mọ́ ọn, ó máa bójú tó mi. Lọ́jọ́ kan lọ́dún 1981, mo sapá láti lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kan ládùúgbò wa. Àmọ́, ara mi ò balẹ̀ bí gbogbo èèyàn ṣe dojú bò mí. Ó yà mí lẹ́nu pé pásítọ̀ náà ò rí tèmi rò, ńṣe ló ń bú màámi torí pé mo jókòó sórí àga táwọn kan sanwó fún. Ni mo bá pinnu pé mi ò tún fẹsẹ̀ tẹ ibẹ̀ mọ́ láé!

Bí Mo Ṣe Wá Mọ Bàbá Mi Ọ̀run

 Láàárọ̀ ọjọ́ kan, mo lọ síbi tí mo sábà máa ń jókòó sí lójú wíńdò lókè ilé wa kí n lè máa wo ohun tó ń lọ níta. Mo rántí pé ọdún 1984 ni torí pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni mí nígbà yẹn. Nígbà tó yá, mo sọ̀ kalẹ̀ lọ sẹ́nu ọ̀nà ilé wa. Bí mo ṣe débẹ̀, mo ráwọn ọkùnrin méjì kan tó ń wàásù láti ilé dé ilé. Wọ́n ka Àìsáyà 33:24 àti Ìfihàn 21:3, 4 wọ́n sì ṣàlàyé fún mi pé láìpẹ́ Ọlọ́run máa mú ìṣòro mi kúrò. Lẹ́yìn náà, wọ́n fún mi ní ìwé pẹlẹbẹ aláwọ̀ mèremère náà Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! wọ́n sì sọ pé àwọn máa pa dà wá kí wọ́n lè kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ sí i.

 Nígbà tí wọ́n pa dà wá lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sọ pé àwọn máa mú míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Pauline tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé wá sọ́dọ̀ mi ká lè máa bá ìjíròrò wa lọ. Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn. Kò pẹ́ tí èmi àti Pauline fi mọwọ́ ara wa bí ìyá àtọmọ. Nígbà tí màámi ri bí “ìyá tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ní” yìí ṣe nífẹ̀ẹ́ mi, tó fi ara ẹ̀ jìn fún mi, tó ní sùúrù fún mi àti bó ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ mi jẹ ẹ́ lógún ló jẹ́ kí màámi gbà mí níyànjú pé kí ń máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ mi lọ pẹ̀lú rẹ̀. Pauline kọ́ mi bí màá ṣe kàwé, ó fi Iwe Itan Bibeli Mi kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ mo wá mọ Bàbá onífẹ̀ẹ́ tó ti wù mí kí n ní.

Pauline, tó jẹ́ míṣọ́nnárì ló kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

 Àwọn nǹkan tí mo kọ́ nínú Bíbélì múnú mi dùn gan-an. Lọ́jọ́ kan, mo bi Pauline bóyá mo lè lọ sí ìpàdé kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe tí wọ́n ń pè ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, a tí wọ́n ń ṣe nílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí ò jìnnà sílé wa. Pauline sọ pé mo lè lọ. Nígbà tó di ọjọ́ Tuesday tó tẹ̀ lé e, Pauline wá sílé wa, wọ́n dúró títí mo fi wẹ̀ tí mo sì múra tán ká lè jọ lọ sípàdé. Ẹnì kan ní kí n sọ fún Pauline pé kó bá mi ṣètò mọ́tò tó máa gbé mi lọ, àmọ́ mo sọ pé, “kí wọ́n má ṣèyọnu, màá lo igi tí mo fi máa ń wọ́.”

 Bá a ṣe ń lọ, màámi àtàwọn tá a jọ ń gbé ń wò mí, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n. Bá a ṣe dé àárín agboolé, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo mọ́ Pauline pé, “Ò ń fi tipátipá mú un lọ!”

 Ni Pauline bá rọra bi mí pé: “Jay, ṣé ó wù ẹ́ kó o lọ?” Mo wá rí i pé ìgbà tó yẹ kí n fi hàn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà gan-an nìyí. (Òwe 3:5, 6) Ni mo bá sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni! Ohun tí mo fẹ́ nìyẹn.” Làwọn tó ń pariwo bá dákẹ́, wọ́n sì ń wò wá bá a ṣe ń lọ. Bá a ṣe jáde síta lẹ́nu géètì ni gbogbo wọn bá bú sẹ́rìn-ín.

 Mo mà gbádùn ìpàdé yẹn o! Ó tù mí lára gan-an! Gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ló wá kí mi. Kò sẹ́ni tó fojú pa mí rẹ́. Ṣe lọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé déédéé. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo béèrè bóyá mo lè máa lọ sáwọn ìpàdé ńlá míì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ní Ilé Ìpàdé wọn. Torí pé tálákà ni wá, mi ò ní ju aṣọ méjì àti bàtà kan lọ. Àmọ́, inú mi dùn, ọkàn mi sì balẹ̀ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ò ní lé mi dànù.

 Tí n bá fẹ́ lọ sí ìpàdé, ó máa gbà pé kí n fi ìdí wọ́ la àdúgbò wa kọjá. Lẹ́yìn náà, máa wá wọ ọkọ̀ lọ sí ibi tí Ilé Ìpàdé wa wà ní ìsàlẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè kan. Láti ibẹ̀ làwọn arákùnrin ti máa ń gbé mi wọlé.

 Torí pé mo ti tọ́ Jèhófà wò tí mo sì rí i pé ó jẹ́ ẹni rere, ló jẹ́ kí n pinnu pé màá fi ṣe ibi ààbò mi. Mi ò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun dí mi lọ́wọ́ láti máa lọ sípàdé déédéé. (Sáàmù 34:8) Kì í rọrùn rárá lákòókò òjò, torí ṣe ni ara mi máa tutù tí ẹrẹ̀ sì máa wà ní gbogbo aṣọ mi. Tí mo bá wá dé ìpàdé, ṣe ni mo máa ń pààrọ̀ aṣọ mi, àmọ́ mi ò jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi rárá.

 Ìrírí mi jáde nínú Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 1985. Ìrírí náà wọ arábìnrin Josette tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Switzerland lọ́kàn nígbà tó kà á nínu Ìwé Ọdọọdún náà, ó sì pinnu láti ra kẹ̀kẹ́ arọ tó ṣeé fọwọ́ tì, tí kò sì ní jẹ́ kí ẹrẹ̀ ta sí mi lára ránṣẹ́ sí mi. Bí kẹ̀kẹ́ náà sì ṣe rí fani mọ́ra gan-an. Bí mi ò ṣe rìnrìn ìdọ̀tí mọ́ nìyẹn. Kódà, ṣe làwọn ọmọdé máa ń kan sárá sí mi tí mo bá ń wa kẹ̀kẹ́ mi, wọ́n sì máa ń sọ bí inú wọn ṣe dùn tó pé mo ti wá ní kẹ̀kẹ́ tí mo lè máa lò báyìí. Bo ṣe di pé, mi ò fi ìdí wọ́ nílẹ̀ mọ́ nìyẹn. Ní báyìí, àwọn èèyàn ń bọ̀wọ̀ fún mi, wọn ò sì pẹ̀gàn mi mọ́. Kódà, ṣe ló ń ṣe mi bíi pé ọmọ ọba ni mí.

Jèhófà Tún Gbé Mi Ga

 Torí pé mi ò kì í lọ́wọ́ nínú ìwà àìmọ́ èyíkéyìí tò sì jẹ́ pé ìgbé ayé ṣe-bó-o-ti-mọ ni mò ń gbé tẹ́lẹ̀, èyí mú kó rọrùn fún mi gan-an láti sin Jèhófà. Kẹ̀kẹ́ tí mò ń lò jẹ́ kí n lè máa wàásù, mo sì ṣèrìbọmi ní August 9, 1986. Ìgbésí ayé mi ti yí pa dà látìgbà tí mo ti ṣèrìbọmi, ìyẹn sì jẹ́ kí n ṣe kọjá ohun tí mo rò pé mo lè ṣe. Ní báyìí, mo ti wá rí i pé Jèhófà tó jẹ́ Bàbá mi nífẹ̀ẹ́ mi, mo sì wúlò fún un. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi ló yí mi ká, wọ́n sì ń bójú tó mi. Ìyẹn ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀, mo sì ń láyọ̀.

 Nígbà tí mo ro gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún mi, ó wù mí kí n ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, àmọ́ mi ò mọ bí mo ṣe fẹ́ ṣe é. (Sáàmù 116:12) Mo wá gbàdúrà sí Jèhófà nípa ẹ̀, mo sì pinnu láti gbìyànjú ẹ̀ wò. Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní January 1, 1988 mi ò sì fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ látìgbà yẹn. Mo ṣì ń gbádùn ẹ̀ gan-an. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń bá mi ṣiṣẹ́, ìyẹn sì ń jẹ́ kí n lè máa rí wákàtí mi pé lóṣooṣù. Jèhófà náà ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa bá iṣẹ́ náà lọ.​—Sáàmù 89:21.

 Bí mo ṣe ń wàásù láti ibì kan sí ibòmíì ń jẹ́ kí ẹsẹ̀ mi lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa ju ìgbà tí mo kàn ń jókòó sójú kan lọ bí ò tiẹ̀ rọrùn. Nígbà tó yá, mo lọ sílé ìwòsàn kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀, kí n lè wò ó bóyá wọ́n á lè bá mi to ara mi kí wọ́n sì ṣètò fún mi láti máa ṣe eré ìmárale. Àmọ́, nọ́ọ̀sì kan tí mo rí níbẹ̀ sọ pé kí n má dara mi láàmù tórí mi ò ní pẹ́ kú. Nígbà tí nọ́ọ̀sì míì tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ tún sọ ohun kan náà fún mi, ọkàn mi bà jẹ́ gan-an. Torí náà, nígbà tí mo pa dà sílé, mo bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fara dà á, kó sì tún jẹ́ kí n rí ọ̀nà míì tí mo lè máa gbà to ara mi.

 Ọ̀nà kan tó dáa jù tí ara mi fi máa ń tò ni bí mo ṣe ń lo ara mi dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Torí ṣe ló dà bí ìgbà tí mò ń ṣeré ìmárale. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ọ̀kan lára àwọn nọ́ọ̀sì tó sọ fún mi pé mi ò ní pẹ́ kú gba Ilé Ìpàdé wa kọjá, ó sì rí mi. Ó yà á lẹ́nu gan-an pé mo ṣì wà láyé!

 Mo ṣì máa ń kópa déédéé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà láìka àìlera mi sí. Àwọn ará máa ń gbóríyìn fún mi torí pé mo nítara mo sì máa ń tètè dé sípàdé. Ìdí tí mo sì fi ń tètè dé ni pé kí n lè kí àwọn ará kí n sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ mí lógún.

 Jèhófà ti bù kún mi jìgbìnnì torí pé mo gbẹ́kẹ̀ lé e. Àwọn mẹ́ta ló ṣèrìbọmi lára àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀kan lára wọn lọ sí kíláàsì kẹtàdínlógóje (137) ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, Amelia lorúkọ ẹ̀. Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí mo ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti mo gbà níbẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run. Jèhófà ti jẹ́ kí n rí i pé mo wúlò, mi ò sì wo ara mi bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan mọ́, ayọ̀ mi sì kọjá àfẹnusọ. Mo ti ń fojú tó tọ́ wo ara mi, àwọn èèyàn sì ń pọ́n mi lé. Ní báyìí ibi gbogbo láyé ni mo ti láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, kì í ṣe nílùú Freetown tí mò ń gbé nìkan.

 Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì ọdún (40) tí mo ti gbọ́ nípa ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí níbi tí kò ti ní sí ẹni kankan tó máa jẹ́ aláàbò ara. Ìlérí yìí múnú mi dùn, ṣe ni mò ń fojú sọ́nà dìgbà tó máa ṣẹ. Mò ń dúró de ìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run mi máa mú ìlérí yìí ṣẹ, ó sì dá mi lójú pé kò ní fi falẹ̀. (Míkà 7:7) Ọ̀pọ̀ ìbùkún ni mo ti gbádùn torí pé mi ò jẹ́ kó sú mi. Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fara da onírúurú ìṣòro tí mo ní. Kò já mi kulẹ̀ rí. Mò ń láyọ̀ tó tọkàn wá, gbogbo ìgbà ni inú mi sì ń dùn torí pé Jèhófà gbé mi dìde láti ilẹ̀, ó sì gbé mi sí ibi tí mi ò rò pé mo lè dé láé.

a Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ ni wọ́n ń pè é báyìí.