Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MILES NORTHOVER | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Fi Èrè sí Iṣẹ́ Mi

Jèhófà Fi Èrè sí Iṣẹ́ Mi

 Inú ìdílé tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni mo dàgbà sí, gbogbo ìgbà ló sì máa ń wu àwọn òbí mi kí wọ́n ti ètò Ọlọ́run lẹ́yìn. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tí ètò Ọlọ́run ní kí wọ́n máa fún àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ní London ní mílíìkì. Bàbá mi fún wọn ní ọmọ màlúù kan, bẹ́ẹ̀ sì rèé ìyá màlúù kan ṣoṣo la ní nígbà yẹn. A tiẹ̀ fi máa ń ṣàwàdà pé ọmọ màlúù yìí ló kọ́kọ́ lọ sí Bẹ́tẹ́lì nínú ìdílé wa. Bó ṣe máa ń yá àwọn òbí mi lára láti ti ètò Ọlọ́run lẹ́yìn mú kémi náà pinnu pé Jèhófà ni màá fi gbogbo ayé mi sìn, mi ò ‘sì ní dẹwọ́’ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ (Oníwàásù 11:6) Ká sòótọ́, Jèhófà ti fèrè síṣẹ́ mi, ó sì ti fún mi làǹfààní láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tí mi ò lérò pé mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ìgbésí ayé mi fún yín.

 Àwọn òbí mi gba ilé kékeré sí àbúlè kan nítòsí ìlú Bicester ní United Kingdom, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti tọ́ èmi àtàwọn ègbọ́n mi dàgbà. Aṣáájú-ọ̀nà làwọn ẹ̀gbọ́n mi, nígbà témi náà sì pé ọmọ ọdún mọkàndínlógún (19) mo bẹ̀rẹ̀ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run sọ mí di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì rán mi lọ sí Scotland. Lọ́dún 1970, wọ́n pè mí sì Bẹ́tẹ́lì tó wà ní London, ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún (23) ni mí nígbà yẹn. Ibẹ̀ sì ni mo ti kọ́ èdè àwọn adití, èdè tí mo kọ́ yìí fún mi láǹfààní láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ètò Ọlọ́run, èyí ti jẹ́ kí ayé mi ládùn kó sì lóyin.

Mo Kọ́ Èdè Àwọn Adití

 Ìjọ Mill Hill ni mò ń dara pọ̀ mọ́ nígbà tí mo wà ní Bẹ́tẹ́lì, ọ̀pọ̀ àwọn ará tó jẹ́ adití ló sì wà níbẹ̀. Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè sún mọ́ àwọn ará yìí. Bí apẹẹrẹ, tí mo bá dé ìpàdé ṣe ni mo máa ń jókòó tì wọ́n, mi ò sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ èdè mú mi jìnnà sí wọn.

 Nígbà yẹn, kò sí ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití ní Britain. Torí náà ìjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì làwọn ara wa tó jẹ́ adití ń dara pọ̀ mọ́. Àwọn ara wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń gbìyànjù gan-an torí ṣe ni wọ́n máa ń tú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé sí èdè àwọn adití. Àmọ́ àwọn adití yìí ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tí wọ́n ń tú dáadáa. Nígbà táwọn ara tó jẹ́ adití ń kọ́ mi ní èdè wọn ni mo wá rí i pé wọ́n ń mú nǹkan mọ́ra torí bí àwọn adití ṣe ń hun ọ̀rọ̀ wọn pọ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ká sòótọ́, èdè àjèjì ni èdè Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ sí wọn. Nígbà tí mo rí i pé bọ́rọ̀ wọn ṣe rí nìyí, mo túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn, mo sì mọyì bí wọ́n ò ṣe fọ̀rọ̀ ìpàdé ṣeré. Ni mo bá túbọ̀ tẹra mọ́ kíkọ́ èdè náà.

 Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Gẹ̀ẹ́sì (BSL) ni wọ́n máa ń sọ ní Britain. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè yìí, òun ni wọ́n sì wá ń lò nípàdé dípò èyí tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀. Àtúnṣe yìí mú káwọn ará wa tó jẹ́ adití túbọ̀ máa gbádùn ìpàdé, ó sì jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará tó kù nínú ìjọ. Ní báyìí, ó ti lé ní àádọ́ta ọdún tàwọn ìjọ tó ń sọ èdè adití ti wà ní Britain, Jèhófà sì ti bù kún wa lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ní báyìí, ẹ jẹ́ kí n sọ àwọn nǹkan amóríyá tó ti ṣẹlẹ̀ àti bí Jèhófà fèrè síṣẹ́ mi.

Èdè Àwọn Adití Gbòòrò Sí I

 Lọ́dún 1973, ìyẹn ọdún kan lẹ́yìn tí mo di alàgbà, Arákùnrin Michael Eagers ronú pé ó máa dáa ká máa ṣe àwọn ìpàdé kan lédè àwọn adití lọ́nà ti Gẹ̀ẹ́sì. A fi tó ètò Ọlọ́run létí, wọ́n sì fọwọ́ sí i, wọ́n wá ní kémi àti alàgbà kan ṣètò lati máa ṣèpàdé lédè àwọn adití lóṣooṣù ní Deptford, tó wà ní apá gúúsù ìlà oòrùn ìlú London.

 Ó wú wa lórí pé àwọn ará wa tó jẹ́ adití wá láti ìlú London àti láwọn ìbòmíì ní apá gúúsù ìlà oòrùn England kí wọ́n lè gbádùn ìpàdé àkọ̀kọ́ tá a ṣe ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Gẹ̀ẹ́sì. Ní báyìí, ó ti wá ṣeé ṣe fáwọn ará wa tó jẹ́ adití láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà nínú Bíbélì ní èdè wọn, èyí ò sì yọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn náà sílẹ̀. Lẹ́yìn ìpàdé náà, a sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró, a sì jọ wá nǹkan panu. Mo tún láǹfààní láti bá lára àwọn ará wa yìí sọ̀rọ̀ kí n lè fún wọn níṣìírí.

 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèpàdé lédè àwọn adití nílùú Birmingham àti Sheffield. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n lè sọ̀rọ̀ tó sì wù kí wọ́n kọ́ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Gẹ̀ẹ́sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé yìí. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì lo èdè tí wọ́n kọ yìí láti wàásù fáwọn adití kaàkiri orílẹ̀-èdè náà.

Mo Pà Dé Ẹni Bí Ọkàn Mi

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa

 Lọ́dún 1974, mo pà dé arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó rẹwà, Stella Barker lórúkọ ẹ̀, ìjọ kan tí ò jìnnà sí Bẹ́tẹ́lì ló sì ti ń sìn. Ọkàn mi fà mọ́ ọn, a sì ṣègbéyàwó lọ́dún 1976. Lẹ́yìn ìyẹn, ètò Ọlọ́run ni káwa méjèèjì máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ìjọ tá a ti ń sìn wà ní Hackney, ní àríwá ìlú London. Mo mọrírì bí ìyàwó mi ọ̀wọ́n ṣe ń tì mí lẹ́yìn bá a ṣe ń fi èdè àwọn adití wàásù. Ṣe ni inú mi máa ń dùn tí mo bá ronú pa dà sẹyìn, torí mo wá rí i pé báwa méjèèjì ṣe jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wà lára ohun tó jẹ́ kí ìgbéyàwó dùn kó sì lóyin.

 Nígbà tó yá, èmi àtiyàwó mi láǹfààní láti lọ máa ṣiṣẹ́ láwọn ọjọ́ kan ní Bẹ́télì. Kò mọ síbẹ̀ o, mo ṣe adelé aláàbójútó àyíká, mo bojú tó ilé ẹ̀kọ́ àwọn alàgbà mo tún ṣèrànwọ́ láti bójú tó bá a ṣe máa tu àpéjọ agbègbè sí èdè àwọn adití. Torí náà, ọwọ́ wa máa ń dí gan-an. Ka sòótọ́, ó máa ń rẹ̀ wá, àmọ́ à ń láyọ̀, a sì gbádùn iṣẹ́ náà.​—Mátíù 11:28-30.

 Kò pẹ́ sígbà yẹn ni iṣé ńlá míì já lé wa léjìká, òun sì ni ọmọ títọ́. Ní 1979 a bí Simon ọmọkùnrin wa àkọ́kọ́ nígbà tó sì di 1982 a bí Mark ọmọkùnrin wa kejì. Ọgbọ́n wo la wá dá sí i, tí iṣẹ́ kan ò fi pa èkejì lára? Èmi àtìyàwó mi pinnu pé nígbàkigbà tí ètò Ọlọ́run bá ní kí n lọ bójú tó iṣẹ́ kan tíyẹn sì máa gba pé kí n kúrò nílé, gbogbo wa la jọ máa lọ, ìyẹn sì máa jẹ́ ká lè ráyè wà pa pọ̀ ká sì gbádùn ara wa. Ìdí tá a sì fi ṣe irú ìpinnu yẹn ni pé, a fẹ́ káwọn ọmọ wa rí i pé téèyàn bá ń sin Jèhófà ó máa láyọ̀. Kí lèyí wá mú kawọn ọmọ wa ṣe nígbà tí wọ́n dàgbà? Yàtọ̀ sí pé wọ́n gbọ́ èdè àwọn adití, wọ́n tún ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ẹ jẹ́ mọ̀ pé, lẹ́yìn ogójì (40) ọdún tí màlúù àwọn òbí mi lọ sí Bẹ́tẹ́lì, àwọn ọmọ mi náà lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Ẹ ò lè mọ bínú wa ṣe dùn tó!

Èmí, Stella ìyàwó mi àtàwọn ọmọ wa méjèèjì lọ́dún 1995

Ètò Ọlọ́run Bójú Tó Àìní Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Adití

 Láwọn ọdún 1990, a láwọn arákùnrin tó jẹ́ adití tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àmọ́ kò sí ìkankan nínú wọn tó jẹ́ alàgbà. Torí náà, àwọn alàgbà tí ò gbọ́ èdè àwọn adití wá ronú pé ṣé àwọn lè rí lára àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí tó máa “kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni” kó sì di alàgbà. (1 Tímótì 3:2) Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó jẹ́ adití ni Arákùnrin Bernard Austin, ìjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń dara pọ̀ mọ́. Àwọn ará bọ̀wọ̀ fún arákùnrin yìí torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà. Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo gbọ́ pé Arákùnrin Bernard Austin di alàgbà. Kódà òun ni aditi àkọ́kọ́ tó di alàgbà ní Britain.

 Ní 1996, ohun àgbàyanu kan ṣẹlẹ̀, ètò Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé ká dá ìjọ àkọ́kọ́ táá máa fi èdè àwọn adití ṣèpàdé sílẹ̀ ní Britain. Ìjọ náà sì wà ní Ealing, lápá ìlà oòrùn ìlú London. Ọ̀pọ̀ nnkan rere míì bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀.

À Ń Ṣe Gbogbo Ìpádé Kristẹni

 Láwọn ọdún 1980 sí 1990, mo láǹfààní láti ṣiṣẹ́ láti ilé pẹ̀lú Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn ní Bẹ́télì. Mo sì ń dáhùn ìbéèrè táwọn èèyàn bá fi ránṣẹ́ nípa àwọn tó ń sọ èdè àwọn adití. Torí pé èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń sọ láwọn ìjọ tó wà nígbà yẹn, àwọn ará wa kan kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ófíìsì kí wọ́n lè béèrè bí wọ́n ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó jẹ́ adití kó lè ṣeé ṣe fáwọn náà láti lóye ohun tí wọ́n ń sọ láwọn ìpàdé ìjọ, àwọn àpéjọ àyíká àti agbègbè. Ìdí tọ́rọ̀ sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé wọn kì í tú àwọn àpéjọ wa sí èdè àwọn adití, kò sì sí ìwé ètò Ọlọ́run kankan tí wọ́n ṣe sí èdè wọn. Ohun kan tí mo máa ń ṣe nígbà yẹn ni pé mo máa ń sọ fáwọn ará tọ́rọ̀ yìí kan pé kí wọ́n ní sùúrù kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dá sí i.

 Inú wa dùn pe sùúrù wa ò já sí asán! Torí kò pẹ́ rárá tí ẹ̀ka ọ̀fíìsì fi ṣètò pé, tí wọ́n bá ṣèpàdé àtàwọn àpéjọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, kí wọ́n máa tú u sì èdè awọn adití. Ohun míì tó tún wú wa lórí ni pé wọ́n fún àwọn ará wa tó jẹ́ adití láǹfààní láti jókòó sọ́wọ́ iwájú kí wọ́n lè rí ẹni tó ń sọ àsọyé àtẹni tó ń túmọ̀ ẹ̀ sí èdè wọn. Ètò yìí wá jẹ́ káwọn ará wa tó jẹ́ adití rí i pé apá kan ìdílé Jèhófà ni wọ́n àti pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn kò sì fọ̀rọ̀ wọn ṣeré.

 Ní April 1, 1995, wọ́n ṣe àpéjọ àkànṣe àkọ́kọ́ lédè àwọn adití ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní Dudley ní ìwọ̀ oòrùn Midlands. Inú mi dùn láti bá Arákùnrin David Merry, tí wọ́n jẹ́ aláàbójútó àyíka tẹ́lẹ̀ ṣiṣẹ́ ká lè jọ ṣètò àpéjọ náà. Ohun tó yà wá lẹ́nu ni pé àwọn ará wa tó jẹ́ adití wá látàwọn ibi tó jìnnà gan-an bí apá àríwá ìlú Scotland àti apá gúúsù ìwọ̀ ooòrun ìlú Cornwall kí wọ́n lè gbádùn àpéjọ náà. Mo ṣì ń rántí bí inú àwọn ará wa tó ju ẹgbẹ̀rún (1,000) tó pẹ́sẹ̀ sí àpéjọ yìí ṣe dùn tó. Mánigbàgbé ni àpéjọ náà.

Èmi àti Arákùnrin David Merry ní àpéjọ àkọ́kọ́ tá a ṣe lédè àwọn adití lọ́nà ti Britain lọ́dún 1995

 Ní 2001, ẹ̀ka ọ́fíìsì ní kí èmi àti Arákùnrin Merry ṣe ètò tó bá yẹ ká lè ṣe àpéjọ agbègbè lọ́dún tó tẹ̀ lé e ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀pọ̀ nǹkan lèyí sì máa gba pé ká ṣe ká lè múra sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló yọ̀ǹda ara wọn. Apéjọ agbègbè náà dùn ó lárinrin! A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi láǹfààní láti bójú tó àwọn àpéjọ àyíká àti agbègbè ní èdè àwọn adití. Mo mọyì bí Jèhófà ṣe ń dá àwọn ọ̀dọ́kùnrin lẹ́kọ̀ọ́, torí èyí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa bá iṣẹ́ náà lọ níbi tí mo bá a dé.

Fídíò Tó Wà Fáwọn Adití

 Inú wa dùn lọ́dún 1998, nígbà tí ètò Jèhófà mú fídíò ìwé àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe sórí kásẹ́ẹ̀tì jáde ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Gẹ̀ẹ́sì. Àkòrí ẹ̀ ni Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn la sì fi fídíò ìwé yìí kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

 Àpéjọ agbègbè ọdún 2002 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa tú orin Ìjọba Ọlọ́run sí èdè àwọn adití lọ́nà ti Gẹ̀ẹ́sì. Inú wa dùn gan-an pé àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin yìí láǹfààní láti kọ orin Ìjọba Ọlọ́run ní èdè wọn, wọ́n sì gbádùn ẹ̀ gan-an. Mo ṣì rántí dáadáa bí alàgbà kan tó jẹ́ adití ṣe ń da omi lójú bó ṣe ń kọ orin náà fúngbà àkọ́kọ́.

 Ohun míì tún ṣẹlẹ̀ ní àpéjọ agbègbè ọdún 2002 tá ò lè gbàgbé. Wọ́n ní kí ìjọ tó ń sọ èdè adití ní London wá ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan sí kásẹ́ẹ̀tì, iṣẹ́ ńlá sì nìyẹn máa jẹ́. Iṣẹ́ yìí kà wá láyà torí pé a ò ṣerú ẹ̀ rí. Àmọ́ bí Jèhófà ṣe máa ń ṣe, ó tún gbọ̀nà àrà yọ, torí ó jẹ́ ká rí àwọn arákùnrin tó mọ bí wọ́n ṣe ń ya fíìmù, tí wọ́n sì ń tò ó lẹ́sẹẹsẹ. Jèhófà jẹ́ ká lè ṣàṣeyọrí iṣẹ́ náà, àwọn ohun tá a sì kọ́ nígbà yẹn ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbà tí mo láǹfààní láti lọ ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì láàárín ọdún 2003 sí 2008. Ká lè ṣe àwọn fídíò tá a máa lò láwọn àpéjọ agbègbè tá a máa ṣe lédè àwọn adití lọ́nà ti Gẹ̀ẹ́sì.

 Èmi àti Stella ìyàwó mi gbádùn àkókò tá a lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ní Bẹ́tẹ́lì. Ká sòótọ́ iṣẹ́ yìí gbomi mu gan-an. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tá a fi múra silẹ̀ tá a sì ya fíìmù náà, ó rẹ gbogbo wa tẹnutẹnu, àtàwọn tó kópa nínú ẹ̀ àtàwọn tó bá wa ká a sórí ẹ̀rọ̀. Àmọ́ a dúpẹ́ pé gbogbo làálàá wa ò já sásán, torí inú wa dùn kọ́ja sísọ nígbà tá a rí i báwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó jẹ adití ṣe ń fojú ara wọn rí báwọn ìtàn inú Bíbélì ṣe sẹlẹ̀ gẹ́lẹ́, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń da omijẹ́ ayọ̀ lójú.

 Ṣe làwọn ìpèsè tẹ̀mí kàn ń rọ́ wọlé lóríṣiríṣi. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 2015, a gba fídíò ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Gẹ̀ẹ́sì. Nígbà tó di ọdún 2019, ètò Ọlọ́run mú fídíò ìwé Mátíù jádè. Ní báyìí, a ti ní odinndin Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, iṣẹ sì ń lọ ní pẹrẹu lórí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ṣe ni inú àwọn ará wa tó jẹ́ adití ń dùn torí gbogbo oore tí Jèhófà ń ṣe fún wọn.

 Ìdílé kan náà ni gbogbo àwọn ará wa kárí ayé, a sì ń fara wé Jèhófà Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn. (Ìṣe 10:34, 35) Ìyàlẹ́nu ńlá ló máa ń jẹ́ fún èmi àti ìdílé mi tá a bá ń ronú lórí ohun tí etò Ọlọ́run ń ná láti bójú tó onírúurú èèyàn títí kan àwọn adití àtàwọn tí ò ríran. a

 Jèhófà ti bù kún gbogbo ohun tá a ṣe, torí ní báyìí ìjọ mélòó kan ti wà ní Britain tí wọ́n ń fi Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Gẹ̀ẹ́sì ṣèpàdé. Tí mo bá ń ronú nípa àwọn àṣeyọrí tá a ti ṣe, inú mi máa ń dùn gan-an pé mo láǹfààní láti kópa láwọn “ọjọ́ tí nǹkan bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́.” (Sekaráyà 4:10) Àmọ́ ká sòótọ́, Jèhófà ni gbogbo ọpẹ́ yẹ torí òun ló ń darí àwọn èèyàn ẹ̀, tó ń pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò kí wọn lè mú kí ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ oníruúrú èèyàn. Òun náà ló sì ń mú kí irúgbìn òtítọ́ dàgbà lọ́kàn àwọn ẹni yíyẹ.

Èmi àti ìyàwó mi lọ́dún 2023