Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

PHYLLIS LIANG | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Ti Bù Kún Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ̀

Jèhófà Ti Bù Kún Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ̀

Nígbà tí wọ́n bi Rèbékà bóyá ó máa fẹ́ ṣe ìyípadà kan tí ò rọrùn. Ṣe ló dáhùn pé òun ṣe tán láti ṣe ohun tó bá ti bá ìfẹ́ Jèhófà mu. (Jẹ́nẹ́sísì 24:50, 58) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò ka ara mi sẹ́ni tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tó bá ti kan ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, èmi náà múra tán láti ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu. Òótọ́ ni pé mo kojú àwọn ìṣòro kan, síbẹ̀ mo ti rí i pé Jèhófà máa bù kún wa tá a bá ṣe tán láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Kódà, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ láwọn ọ̀nà tá ò lérò.

Bàbá Àgbàlagbà Kan Fún Wa Ní Ìṣúra Pàtàkì Kan

 Kò pẹ́ tá a kó lọ sí ìlú Roodeport ní South Africa ni bàbá mi kú. Nǹkan ò rọrùn rárá fún wa nígbà yẹn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) lọ́dún 1947, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ ìjọba tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ tẹlifóònù. Lọ́jọ́ kan tí mo wà nílé, bàbá àgbàlagbà kan wá sílé wa, ó sì sọ fún wa pé a lè máa san àsansílẹ̀ owó ká lè máa gba Ilé Ìṣọ́ bó bá ṣe ń jáde. A gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé àgbàlagbà ni.

 Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ohun tá à ń kà yẹn ń wọ̀ wá lọ́kàn, ó sì wù wá ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àtìgbà tí màmá mi ti wà ní kékeré ni wọ́n ti ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Dutch Reform. Àmọ́ wọ́n rí i pé ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì náà fi ń kọ́ni yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Bíbélì fi ń kọ́ni. Bó ṣe di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, kò sì pẹ́ sígbà yẹn la bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé. Nígbà tó di ọdún 1949, mo ṣèrìbọmi. Èmi sì lẹni àkọ́kọ́ tó ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìdílé wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò dáwọ́ iṣẹ́ tí mò ń ṣe dúró fáwọn ọdún mélòó kan, ó wù mí kí n ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà.

Ó Wù Mí Kí N Lọ Sìn Níbi Tí Àìní Wà

FomaA/stock.adobe.com

Koeksisters

 Mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé lọ́dún 1954, lẹ́yìn náà mo kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì South Africa pé kí wọ́n sọ ibi tí mo ti lè lọ sìn. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wá sọ pé mo lè lọ sí ìlú Pretoria, wọ́n sì ṣètò pé kí arábìnrin míì tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wá síbẹ̀ ká lè jọ máa ṣiṣẹ́. Ilé tá a gbà dáa, ó sì tù wá lára. Kódà, mo ṣì máa ń rántí oúnjẹ aládùn tí wọ́n ń pè ní koeksisters tí wọ́n ń tà ládùúgbò yẹn.

 Nígbà tó yá, arábìnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ sílé ọkọ. Arákùnrin George Phillips tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka wá bi mí bóyá màá fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, tayọ̀tayọ̀ ni mo fi gbà.

 Ọdún 1955 ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ìlú Harrismith ni wọ́n sì kọ́kọ́ rán mi lọ. Ojú èmi àti arábìnrin tá a jọ sìn níbẹ̀ rí màbo ká tó rí ilé tá a máa gbé. Nígbà tá a tún jàjà rílé, ṣe ni àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ládùúgbò yẹn fúngun mọ́ ẹni tó gbà wá sílé pé kó lé wa jáde.

 Nígbà tó yá, wọ́n rán mi lọ sí ìlú Parkhurst ní Johannesburg, wọ́n sì rán àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì náà wá síbẹ̀ ká lè jọ máa ṣiṣẹ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ọ̀kan nínú wọn lọ sílé ọkọ. Ètò Ọlọ́run wá rán arábìnrin kejì lọ sí ìlú míì. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Eileen Porter wá gbà mí sílé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé kékeré ni wọ́n ń gbé, wọ́n fi aṣọ pín ibì kan fún mi kí n lè máa sùn síbẹ̀. Èèyàn dáadáa ni Eileen, ó sì máa ń fún mi ní ìṣírí, ìyẹn mú kára tù mí pẹ̀sẹ̀ lọ́dọ̀ ẹ̀. Ìtara tó ní fún òtítọ́ jọ mí lójú gan-an bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tó ń ṣe nínú ilé yẹn kì í ṣe kékeré.

 Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run ní kí èmi àti arábìnrin kan tó ń jẹ́ Merlene Laurens tá a tún máa ń pè ní Merle lọ máa ṣiṣẹ́ ní ìlú Aliwal North tó wà ní agbègbè Eastern Cape. Torí pé ọ̀dọ́ làwa méjèèjì, a ò sì tíì pé ọmọ ọgbọ̀n (30) ọdún, arábìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Dorothy ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fún wa, a sì sábà máa ń pè wọ́n ní Auntie Dot. Nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́, àwọn ajá ya bò wọ́n, wọ́n sì bù wọ́n jẹ níbi tí wọ́n ti ń wàásù. Àmọ́ ìyẹn ò mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì.

 Lọ́dún 1956, ètò Ọlọ́run ní kí Merle lọ sí kíláàsì kejìdínlọ́gbọ̀n (28) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ó wù mí gan-an pé ká jọ lọ. Àmọ́ Auntie Dot tọ́jú mi gan-an, a sì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jù mí lọ dáadáa.

 Nígbà tó yá, wọ́n pe èmi náà sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, inú mi sì dùn gan-an. Kí n tó lọ, mo lọ lo oṣù mẹ́jọ ní ìlú Nigel lọ́dọ̀ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Kathy Cooke tí òun náà ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì rí. Katty jẹ́ kó dá mi lójú pé màá gbádùn ilé ẹ̀kọ́ náà gan-an. Nígbà tó sì di January 1958, mo gbéra mo sì forí lé ìlú New York.

Mo Ṣe Tán Láti Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́

 Nígbà tí mo dé Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, yàrá kan náà ni wọ́n fi èmi àti Tia Aluni tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Samoan àti Ivy Kawhe tó wá láti ẹ̀yà Maori sí. Inú mi dùn gan-an pé èmi àti arábìnrin yìí la jọ wà ní yàrá. Ìdí ni pé nígbà tí mo wà ní South Africa, ìjọba kì í jẹ́ káwọn aláwọ̀ funfun àtàwọn tó wá láti ẹ̀yà míì da nǹkan pọ̀ rárá. Kò pẹ́ tá a fi dọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Inú mi sì dùn pé àwọn tó wá látinú onírúurú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kárí ayé la jọ wà ní kíláàsì.

 Mo rántí ọ̀kan lára olùkọ́ wa ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ìyẹn Arákùnrin Maxwel Friend. Ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà kọ́ wa ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an. Nígbà yẹn, iná mẹ́ta ni wọ́n máa ń lò nínú kíláàsì wọn. Wọ́n pe ọ̀kan ní “ohùn,” ìkejì ni “ìyárasọ̀rọ̀,” ìkẹta sì jẹ́ “ìtara.” Tí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ bá ń sọ àsọyé tàbí tó ń ṣe àṣefihàn, tí ò sì ṣe apá kan nínú ohun tá a sọ yìí dáadáa, ṣe ni Arákùnrin Friend máa tan iná tó fi hàn pé kò ṣe apá náà dáadáa. Torí pé mo máa ń tijú, ọ̀pọ̀ ìgbà ni arákùnrin náà máa ń tan iná yẹn tí mo bá ti ń ṣiṣẹ́, èyí sì máa ń jẹ́ kí n bú sẹ́kún nígbà míì. Bó ti wù kó rí, ẹni ọ̀wọ́n ni Arákùnrin Friend jẹ́ sí mi. Nígbà míì tí mo bá ń ṣiṣẹ́ ìmọ́tótó tí wọ́n yàn fún mi láwọn àsìkò tí mi ò bà sí ní kíláàsì, ṣe ni wọ́n máa ń gbé kọfí wá fún mi.

 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ibi tí wọ́n máa rán mi lọ. Orílẹ̀-èdè Peru ni wọ́n rán Merle tá a jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tẹ́lẹ̀ lọ lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Merle wá sọ fún mi pé kí n lọ bá Arákùnrin Nathan Knorr tó ń bójú tó iṣẹ́ wa nígbà yẹn sọ̀rọ̀, bóyá wọ́n lè rán mi wá sí orílẹ̀-èdè Peru. Ìdí ni pé ẹni tí òun àti ẹ̀ jọ ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì máa tó lọ sílé ọkọ, ó sì máa nílò ẹnì kan tí wọ́n á jọ máa ṣiṣẹ́. Àtìgbàdégbà ni Arákùnrin Knorr máa ń wá síbi tá a ti ń ṣe ilé ẹ̀kọ́ náà, ìyẹn mú kó rọrùn fún mi láti bá wọn sọ̀rọ̀. Torí náà, nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n rán mi lọ sí orílẹ̀-èdè Peru.

A Ṣiṣẹ́ Níbi Tí Òkè Pọ̀ Sí

Èmi àti Merle (apá ọ̀tún) ní Peru lọ́dún 1959

 Inú mi dùn pé èmi àti Merle tún pa dà ríra, a sì jọ máa ṣiṣẹ́ ní ìlú Lima lórílẹ̀-èdè Peru. Gbàrà tí mo débẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í láwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Sípáníìṣì. Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run ní kí èmi àti Merle lọ máa ṣiṣẹ́ ní ìlú Ayacucho tó wà níbi tí òkè pọ̀ sí. Kí n sòótọ́, iṣẹ́ yẹn ò rọrùn rárá. Òótọ́ ni pé mo ti kọ́ èdè Sípáníìṣì díẹ̀, àmọ́ èdè Quechua nìkan lọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ ń sọ. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé òkè pọ̀ lágbègbè náà, ó ṣe díẹ̀ kí agbègbè yẹn tó mọ́ mi lára.

À ń wàásù ní Peru lọ́dún 1964

 Ó ń ṣe mí bíi pé iṣẹ́ ìwàásù tá a ṣe ní ìlú Ayacucho kò sèso rere. Mo sì máa ń ronú pé bóyá la máa rẹ́ni tó máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ níbẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, akéde tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje (700) ló wà nílùú Ayacucho. Kò tán síbẹ̀ o, ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè Quechua tún wà níbẹ̀.

 Nígbà tó yá, Merle fẹ́ Arákùnrin Ramón Castillo tó jẹ́ alábòójútó àyíká. Nígbà tó sì di ọdún 1964, ètò Ọlọ́run ní kí Ramón wá sí ilé ẹ̀kọ́ olóṣù mẹ́wàá kan ní Gílíádì. Wọ́n pe arákùnrin kan tó ń jẹ́ Fu-lone Liang náà wá sí ilé ẹ̀kọ́ yìí, èmi àti ẹ̀ jọ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì nígbà yẹn, ìlú Hong Kong ló sì ti ń sìn. Wọ́n pè é fún ilé ẹ̀kọ́ yìí kí wọ́n lè dá a lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń bójú tó ẹ̀ka ọ́fíìsì. a Fu-lone wá béèrè nípa mi lọ́wọ́ Ramón. Kò sì pẹ́ sígbà yẹn lèmi àti Fu-lone bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà síra wa.

 Àtìbẹ̀rẹ̀ ni Fu-lone ti jẹ́ kí n mọ̀ pé bá a ṣe ń kọ lẹ́tà síra wa yìí, a ti ń fẹ́ra wa sọ́nà nìyẹn o. Arákùnrin Harold King tí òun náà jẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Hong Kong sábà máa ń lọ sí ilé ìfìwéránṣẹ́, òun ló sì máa ń bá Fu-lone fi àwọn lẹ́tà ẹ̀ ránṣẹ́. Harold sábà máa ń ya àwọn àwòrán kéékèèké tàbí kó kọ ọ̀rọ̀ ránpẹ́ kan sẹ́yìn lẹ́tà tí Fu-lone fi ránṣẹ́ sí mi. Wọ́n lé kọ ọ́ pé, “Màá rí i dájú pé Fu-lone túbọ̀ ń kọ lẹ́tà sí ẹ!”

Èmi àti Fu-lone ọkọ mi

 Lẹ́yìn ọdún kan ààbọ̀ tá a ti ń kọ lẹ́tà síra wa. Èmi àti Fu-lone ṣègbéyàwó. Bó ṣe di pé mo kúrò ní Peru lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méje tí mo ti wà níbẹ̀ nìyẹn.

Ìgbé Ayé Ọ̀tun ní Hong Kong

 November 17, 1955 lèmi àti Fu-lone ṣègbéyàwó. Ẹ̀ka ọ́fíìsì lèmi àti ọkọ mi àtàwọn tọkọtaya méjì míì ń gbé. Mo gbádùn àsìkò yẹn gan-an. Tí ọkọ mi bá ń ṣiṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè lẹ́ka ọ́fíìsì, èmi á jáde lọ wàásù. Kò rọrùn fún mi rárá láti kọ́ èdè Cantonese. Àmọ́, ọkọ mi àtàwọn arábìnrin méjì tá a jọ jẹ́ míṣọ́nnárì ṣe sùúrù fún mi, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Bí mo ṣe ń fi ìwọ̀nba èdè tí mo gbọ́ kọ́ àwọn ọmọdé lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún mi láti kọ́ èdè náà.

Àwa mẹ́fà tá à ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Hong Kong láwọn ọdún 1960. Èmi àti Fu-lone ló wà láàárín

 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, a kó lọ sí ilé àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní ìlú Kwun Tong. Ìdí ni pé ètò Ọlọ́run fẹ́ kí ọkọ mi máa kọ́ àwọn míṣọ́nnárì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ní èdè Cantonese. b Mo gbádùn iṣẹ́ ìwàásù lágbègbè yẹn débi pé láwọn ìgbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pe kí n má pa dà wálé!

 Inú mi dùn gan-an nígbà tí ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye jáde lọ́dún 1968. Ìdí ni pé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí rọrùn lò ju ìwé “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ,” tá à ń lò tẹ́lẹ̀ pàápàá fún àwọn tí kò mọ̀ nípa Bíbélì àti ẹ̀sìn Kristẹni.

 Àmọ́ àṣìṣe kan wà tí mo ṣe. Mo ronú pé tí àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá ti lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nínú ìwé náà, á jẹ́ pé ohun tí mò ń kọ́ wọn yé wọn nìyẹn, ó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Mo rántí ìgbà kan tí ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì parí ìwé Òtítọ́ látìbẹ̀rẹ̀ dópin, síbẹ̀ kò gba Ọlọ́run gbọ́. Mo wá rí i pé á dáa kí n máa béèrè àwọn ìbéèrè táá jẹ́ kí àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Ìyẹn á jẹ́ kí n mọ bí ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣe rí lára wọn.

 Lẹ́yìn tá a lo ọdún díẹ̀ ní Kwun Tong, a pa dà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Wọ́n sì ní kí ọkọ mi wà lára àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Hong Kong. Láwọn ọdún yìí wá, mo ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń tọ́jú ilé àtàwọn tó ń gbàlejò. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ètò Ọlọ́run máa ń ní kí ọkọ mi lọ bójú tó àwọn iṣẹ́ kan tó jẹ́ pé mi ò lè tẹ̀ lé wọn lọ. Àmọ́ inú mi dùn pé mò ń ti ọkọ mi lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún wọn.

Fu-lone ń mú apá kejì ìwé Asọtẹ́lẹ̀ Aísáyà jáde ní èdè Chinese ti ìbílẹ̀ àti èyí tá a mú kó rọrùn

Ìyípadà Kan Tó Bà Mí Lọ́kàn Jẹ́

 Lọ́dún 2008, ohun kan tí mi ò retí ṣẹlẹ̀ tó bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an. Nígbà tó ku díẹ̀ ká ṣe Ìrántí Ikú Kristi, ọkọ mi ọ̀wọ́n rìnrìn àjò kan. Àmọ́ àlọ wọn ni mo rí, mi ò rí àbọ̀ wọn. Ikú wọn dùn mí gan-an. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin dúró tì mí. Ohun tí ò sì jẹ́ kí n sunkún lásìkò Ìrántí Ikú Kristi yẹn ni pé, mò ń bá obìnrin kan tó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi ṣí Bíbélì tí wọ́n ń pè. Ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tí ọkọ mi fẹ́ràn jù ló fún mi lókun lásìkò yẹn. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú . . . ‘Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’ ”​—Àìsáyà 41:13.

 Ọdún méje lẹ́yìn tí ọkọ mi kú, àwọn ará ní Hong Kong sọ pé á dáa kí n lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó tóbi níbi tí wọ́n á ti lè tọ́jú mi dáadáa. Torí náà lọ́dún 2015, ètò Ọlọ́run ní kí n lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì South Africa, ibẹ̀ ò sì jìnnà síbi tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́dún 1947.

 Mo gbádùn ọ̀pọ̀ ọdún tí mo lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, mo sì gbà pé Jèhófà bù kún mi gan-an. Mo ṣì ń gbúròó àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn, inú mi sì dùn pé wọ́n ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà. Mo tún rí i pé Jèhófà máa ń bù kún ohun tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bó ti wù kó kéré mọ. Bí àpẹẹrẹ, iye akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Peru lọ́dún 1958 ò ju ọgọ́rùn-ún méje ó lé ọgọ́ta (760). Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 2021, iye yẹn ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádóje (133,000). Bákan náà, iye akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Hong Kong lọ́dún 1965 ò ju ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgbọ̀n (230). Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 2021, iye yẹn ti lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún ààbọ̀ (5,565).

 Ní báyìí, ara ti ń dara àgbà, mi ò sì lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Àmọ́, ó ṣì máa ń wù mí láti ṣe púpọ̀ sí i. Mo sì ń fojú sọ́nà fún ayé tuntun níbi tí màá ti lè lo ara mi dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Tó bá dìgbà yẹn, iṣẹ́ máa pọ̀ fún gbogbo wa láti ṣe. Inú mi á sì dùn láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá yàn fún mi.

a Tó o bá fẹ́ mọ bí Fu-lone Liang ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 1974, ojú ìwé 51 lédè Gẹ̀ẹ́sì.

b Tó o ba fẹ́ ka ọ̀kan nínú àwọn ìrírí tí Fu-lone ní nígbà tó wà ní Kwun Tong, wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 1974, ojú ìwé 63 lédè Gẹ̀ẹ́sì.