DORINA CAPARELLI | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Bó Tiẹ̀ Jẹ́ Pé Mo Máa Ń Tijú, Iṣẹ́ Yìí Náà Ni Màá Tún Fáyé Mi Ṣe!
Mo máa ń tijú gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń yà mí lẹ́nu tí mo bá ronú nípa ohun tí mo ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
Ọdún 1934 ni wọ́n bí mi ní ìlú Pescara tó wà ní àárín gbùngùn etíkun Adriatic lórílẹ̀-èdè Ítálì. Èmi ni àbígbẹ̀yìn nínú ọmọbìnrin mẹ́rin táwọn òbí mi bí. Bí álúfábẹ́ẹ̀tì èdè Gẹ̀ẹ́sì ṣe tò tẹ̀ léra ni bàbá mi fi sọ wá lórúkọ, torí náà lẹ́tà “D” ló bẹ̀rẹ̀ orúkọ mi.
Ó wu bàbá mi láti mọ Ọlọ́run. Ní July 1943, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Liberato Ricci tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, ó sì fún wọn ni Ilé Ìṣọ́ kan. Ìgbà yẹn ni Bàbá mi kọ́kọ́ mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò pẹ́ rárá tí bàbá mi fi bẹ̀rẹ̀ sí sọ ohun tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì fáwọn míì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé màámi ò kàwé, wọ́n gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Wọ́n máa ń há àwọn ẹsẹ Bíbélì sórí, wọ́n sì máa ń sọ ohun tí wọ́n ń kọ́ látinú Bíbélì fáwọn míì.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé yàrá méjì ló wà nínú ilé wa, a máa ń gba àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà lálejò, ìyẹn àwọn tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàású. Bákan náà, ilé wa ni wọ́n ti máa ń ṣe àwọn ìpàdé ìjọ, torí náà èrò kì í dá nílé wa.
Méjì lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́, torí náà kò pẹ́ tí wọ́n fi kúrò nílé tí wọ́n sì ṣègbéyàwó. Àmọ́, èmi àti ẹ̀gbọ́n mi Cesira tí mo tẹ̀ lé fẹ́ràn láti máa tẹ́tí sí bàbá wa tí wọ́n bá ń ka Bíbélì. Bákan náà, a máa ń gbádùn àsọyé Bíbélì táwọn arákùnrin tó máa ń ṣèbẹ̀wò sí àwùjọ wa máa ń sọ.
Mo máa ń tẹ̀ lé bàbá mi àtàwọn míì lọ wàásù, àmọ́ torí bí mo ṣe máa ń tijú, ó gbà mí ní ọ̀pọ̀ oṣù kí n tó lè báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì. Àmọ́, láìka bí mo ṣe ń tijú sí, mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, torí náà mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1950. Ilé wa ni wọ́n ti sọ àsọyé ìrìbọmi náà ká tó lọ síbi odò tí mo ti ṣèrìbọmi. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n ní kí tọkọtaya kan wá máa sìn ládùúgbò wa, torí pé wọn máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, èmi náà máa ń tẹ̀ lé wọn lọ wàásù. Bí mo ṣe ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti wàásù, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń rọrùn fún mi láti báwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ìyẹn sì mú kínú mi máa dùn bí mo ṣe ń fìgbésí ayé mi sin Jèhófà!
Ìpinnu Tó Yí Ìgbésí Ayé Mi Pa Dà
Arákùnrin Piero Gatti a ni alábòójútó àyíká wa àkọ́kọ́, wọ́n fún mi níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, kí n sì lọ síbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, mi ò ronú nípa ẹ̀ rí. Lágbègbè wa, ilé làwọn ọmọbìnrin máa ń wà títí wọ́n á fi lọ́kọ. Torí náà, ilé ni mo wà nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní March 1952. Ìpinnu tí mo ṣe yìí ló yí ìgbésí ayé mi pa dà.
Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Anna náà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lásìkò yẹn. Ó wá kó wá sílé wa, ká lè jọ máa wàásù. Lọ́dún 1954, wọ́n sọ àwa méjèèjì di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì rán wa lọ sí ìlú Perugia. Nígbà yẹn kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbẹ̀, ìrìn ibẹ̀ sì tó ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ (250) kìlómítà síbi tá à ń gbé tẹ́lẹ̀.
Mo gbádùn iṣẹ́ yìí gan-an! Ọmọ ogún (20) ọdún ni mí nígbà yẹn, ìgbà tí mo tẹ̀ lé àwọn òbí mi lọ sípàdé agbègbè ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo kúrò nílé. Àmọ́, mo ti wá filé sílẹ̀ báyìí. Ọkàn bàbá mi ò balẹ̀ torí èmi àti Anna nìkan la fẹ́ máa dá gbé. Torí náà, wọ́n wá bá wa wálé. Yàrá kan tá a gbà là ń sùn, tá a sì fi ń ṣèpàdé. Níbẹ̀rẹ̀, èmi àti Anna nìkan là ń ṣèpàdé. Síbẹ̀ náà, à ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an ní Perugia àti láwọn ìlú àtàwọn abúlé tó wà láyìíká wa. Ìsapá wa ò já sásán torí a ráwọn èèyàn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Lẹ́yìn ọdún kan tá a ti wà ní ìlú Perugia, arákùnrin kan kó wá síbẹ̀, òun ló wá ń bójú tó àwọn ìpàdé. Inú wa dùn pé nígbà tá a fi máa kúrò nílùú Perugia lọ́dún 1957 torí iṣẹ́ ìsìn wa tó yí pa dà, ìjọ kékeré kan ti wà níbẹ̀.
Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Terni, tó wà ní àárín gbùngùn orílẹ̀-èdè Ítálì ni wọ́n rán wa lọ. Iṣẹ́ ìwàásù rọrùn gan-an níbẹ̀, torí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ pọ̀ níbẹ̀. Síbẹ̀, a ṣì láwọn ìṣòro tá a dojú kọ. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba apàṣẹwàá ti dópin lọ́dún 1943, àwọn aláṣẹ ṣì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti dá iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúró, wọ́n ní a gbọ́dọ̀ gbàwé àṣẹ ká tó lè máa wàásù láti ilé dé ilé.
Àwọn ọlọ́pàá máa ń ṣọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri. Àmọ́, nígbà míì a máa ń kó sáàárín èrò kọ́wọ́ wọn má bàa tẹ̀ wá. Bí mo ṣe ṣọ́ra tó, ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n mú mi. Ìgbà àkọ́kọ́ nìgbà témi àti alábòójútó àyíká jọ ń wàásù. Wọ́n mú wa lọ sí àgọ́ wọn, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wá pé, à ń wàásù láìgba ìwé àṣẹ. Wọ́n ní ká sanwó ìtanràn, àmọ́ a kọ̀ láti sanwó náà, torí a ò rú òfin kankan. Ṣe ni àyà mi ń lù kì kì, ẹ̀rù sì bà mí gan-an torí mi ò mọ ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí. Àmọ́, ọkàn mi balẹ̀ lápá kan torí èmi àti alábòójútó àyíká la jọ wà níbẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó wà ní Àìsáyà 41:13 tún fi mí lọ́kàn balẹ̀. Ó sọ pé: “Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.” Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, wọ́n ní ká máa lọ sílé, wọ́n wá gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́. Àmọ́ inú wa dùn pé ilé ẹjọ́ dá wa láre. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà ni wọ́n tún pa dà mú mi, àmọ́ bíi tìgbà àkọ́kọ́ ṣe ni wọ́n tún dá mi láre.
Mo Láàǹfààní Láti Ṣe Púpọ̀ Sí I Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
Mi ò lè gbàgbé àpéjọ agbègbè tá a ṣe lọ́dún 1954 nílùú Naples, ní gúúsù orílẹ̀-èdè Ítálì. Nígbà tá a dé bẹ̀, mo yọ̀ǹda ara mi láti tún ibi tá a fẹ́ lò ṣe, wọ́n sì ní kí n lọ ṣiṣẹ́ nítòsí pèpéle. Bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́, mo rí arákùnrin kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Antonio Caparelli. Arákùnrin náà dùn-ún wò gan-an, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń bójú tó èrò, orílẹ̀-èdè Libya ló ti ń sìn. Ọwọ́ ìparí ọdún 1930 làwọn ìdílé ẹ̀ kọ́ lọ síbẹ̀ láti orílẹ̀-èdè Ítálì.
Antonio nígboyà, ó sì lákíkanjú. Ó máa ń fi ọ̀kadà rìnrìn àjò lọ sáwọn ìgbèríko tó wà lórílẹ̀-èdè Libya kó lè wàásù fáwọn ọmọ Ítálì tó ń gbé níbẹ̀. A máa ń kọ lẹ́tà síra wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1959, ó pa dà sí Ítálì, ó sì lo oṣù mélòó kan ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Róòmù. Kò pẹ́ sígbà yẹn ló di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì rán an lọ sílùú Viterbo ní àárín gbùngùn orílẹ̀-èdè Ítálì. Ojoojúmọ́ là ń nífẹ̀ẹ́ ara wa sí i, a sì ṣègbéyàwó ní September 29, 1959. Ni èmi àti ọkọ mi bá jọ ń báṣẹ́ lọ ní Viterbo.
A nílò ibi tí àá ti máa ṣe àwọn ìpàdé àti ibi tí àá máa gbé. Torí náà, a gba yàrá kan tó kéré gan-an, balùwẹ̀ ẹ̀ náà kéré, ọwọ́ ẹ̀yìn ló sì wà. A fi nǹkan pin yàrá náà sí méjì, a gbé bẹ́ẹ̀dì wa sí apá kan. A sì fi apá tó kù ṣe ibi tí àá máa lò sí tàbí ká fi ṣe ìpàdé láwọn ọjọ́ tá a máa ń ṣèpàdé. Ká ní èmi nìkan ní, mi ò ní lè gbé irú ilé yẹn, tórí kò rọrùn rara. Àmọ́ inú mi dùn torí èmi àti ọkọ mi la jọ wà pa pọ̀.
Lọ́dún 1961, Antonio di alábòójútó àyíká. Nígbà yẹn, ó gbọ́dọ̀ lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn ìránṣẹ́ ìjọ tàbí alábòójútó fúngbà díẹ̀. Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé èmi nìkan ní màá wà nílé fún odindi oṣù kan. Kí n má parọ́, nǹkan ò rọrùn fún mi nígbà yẹn, pàápàá tí mo bá dá wà nínú yàrá lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Síbẹ̀, inú mi dùn gan-an pé ọkọ mi yọ̀ǹda ara ẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Torí pé mo jẹ́ kọ́wọ́ mi dí, ká tó ṣẹ́jú pẹ́ oṣù kan ti pé.
Iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò gbà pé ká máa lọ láti ibì kan sí ibòmíì. A lọ láti ìlú Veneto tó wà ní apá àríwá sí ìlú Sicily tó wà ní apá gúúsù lórílẹ̀-èdè Ítálì. Níbẹ̀rẹ̀, ọkọ̀ èrò là máa ń wọ̀ torí a ò ní mọ́tò. Lẹ́yìn tá a rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ èrò gba ojú ọ̀nà tí ò dáa lọ sábúlé kan nílùú Sicily, bá a ṣe dé ibùdókọ̀, a bá àwọn arákùnrin tí wọ́n ti ṣètò kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó máa kó ẹrù wa. Lọ́jọ́ yẹn kóòtù àti táì lọkọ mi wọ̀, èmi náà sì wọṣọ àwọn alákọ̀wé. Ó ṣeé ṣe kó máa pa àwọn èèyàn lẹ́rìn-ín bí wọ́n ṣe rí wa tá à ń rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin wa tó jẹ́ àgbẹ̀ yìí, torí ìmúra wa yàtọ̀ sí tiwọn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ló sì kó àwọn báàgì àti ẹ̀rọ ìtẹ̀wé wa.
Àwọn arákùnrin yẹn lawọ́ gan-an bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní. Àwọn ilé kan tó wà níbẹ̀ ò ní balùwẹ̀ tàbí omi ẹ̀rọ. Láàárín àkókò yẹn, a gbé ní yàrá kan tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni ẹnì kankan ò fi gbé níbẹ̀, ṣe ni mò ń yí kiri nígbà tí mo sùn lálẹ́, lọkọ mi bá jí mi. Nígbà tá a ká aṣọ tó wà lórí bẹ́ẹ̀dì wa kúrò, sí ìyàlẹ́nu wa oríṣiríṣi kòkòrò la rí! Torí pé òru ni, a ò fi bẹ́ẹ̀ rí nǹkan kan ṣe sí i, ńṣe la kàn gbá àwọn kòkòrò náà tá a sì pa dà lọ sùn.
Mi ò wo àwọn ipò tí kò bára dé yìí bí ìṣòro, ohun tó kà mí láyà jù ni bí mo ṣe máa ń tijú. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá kọ́kọ́ bẹ ìjọ kan wò, kì í rọrùn fún mi láti láwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Àmọ́ mo sapá gan-an torí ó máa ń wù mí láti fún àwọn arábìnrin níṣìírí kí ń sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Mo rọ́wọ́ Jèhófà, torí kí ọ̀sẹ̀ náà tó parí, ara mi á ti mọlé. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún mi láti bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yẹn ṣiṣẹ́, torí pé wọ́n nígbàgbọ́, wọ́n lawọ́, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.
Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ témi àti ọkọ mi fi ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká àti agbègbè, b wọ́n pè wá sí Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Rome lọ́dún 1977, ká lè ṣèrànwọ́ fún ìmúrasílẹ̀ àpéjọ àgbáyé tó máa wáyé lọ́dún 1978 tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ìgbàgbọ́ Aṣẹ́gun.” Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, a di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Kò pẹ́ sígbà yẹn lọkọ mi di ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka.
Bí mo ṣe máa ń tijú ò jẹ́ kí n tètè túra ká nígbà tá a dé Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́, Jèhófà lo àwọn tó wà nínú ìdílè Bẹ́tẹ́lì láti ràn mí lọ́wọ́, kò pẹ́ sígbà yẹn lara mi mọlé.
A Kojú Àwọn Ìṣòro Míì
Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, a kojú ìṣòro míì, ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn. Lọ́dún 1984, wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún un nínú ọkàn, ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn ìyẹn, àìsàn náà burú sí i. Lọ́dún 1999, wọ́n sọ pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé akíkanjú ọkùnrin lọkọ mi, àìsàn náà ò jẹ́ kó lè ṣe nǹkan kan mọ́. Inú mi bà jẹ́ gan-an bí mo ṣe ń rí i tí agbára ẹ̀ ń dín kù. Mo gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn pé kó fún mi lókun kí ń lè ran ọkọ mi ọ̀wọ́n lọ́wọ́ lákòókò tí nǹkan ò rọrùn fún un yìí. Bákan náà, mo máa ń ka àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Sáàmù. Tí mo bá ń ronú tàbí tọ́kàn mi ò balẹ̀, àwọn ohun tí mo kà yìí máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀. Antonio kú ní March 18, 1999. Nǹkan bí ogójì (40) ọdún la sì fi wà pa pọ̀.
Ó ṣì máa ń ṣe mí bí i pé mo dá nìkan wà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn yí mi ká. Ká sòótọ́, àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tá a mọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò fìfẹ́ hàn sí mi, wọ́n sì tù mí nínú. Láìka báwọn ọ̀rẹ́ àtàtà yìí ṣe ń fìfẹ́ hàn sí mi, ó ṣì máa ń ṣe mí bíi pé mi ò rẹ́ni fojú jọ, pàápàá láwọn ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ tí mo bá pa dà sí yàrá. Kí n má parọ́, kò rọrùn fún mi rárá, àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ńṣe lára ń tù mí bí mo ṣe ń gbàdúrà tí mo sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí, ó ti wá rọrùn fún mi láti ronú lórí àwọn àkókò alárinrin tí èmi àti ọkọ mi jọ lò pa pọ̀, bákan náà mí ò lè gbàgbé bá a ṣe jọ ń ṣe nǹkan pa pọ̀. Mo mọ̀ pé Jèhófà ò gbàgbé ọkọ mi àti pé màá rí i nígbà àjíǹde.
Onírúurú ẹ̀ka ni mo ti ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, àmọ́ ibi tí wọ́n ti ń ránṣọ ni mo ti ń ṣiṣẹ́ báyìí. Bí mo ṣe ń ran ìdílé Bẹ́tẹ́lì lọ́wọ́ ń múnú mi dùn, mi ò sì fi iṣẹ́ ìwàásù ṣeré. Òótọ́ ni pé mi ò lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù torí ara ti ń dara àgbà, síbẹ̀ mo ń ṣe ìwọ̀nba tágbára mi gbé, torí ohun tó wù mí kí ń fayé mi ṣe nìyẹn látìgbà tí mo ti wà lọ́dọ̀ọ́. Mo mọ̀ pé iṣẹ́ aláyọ̀ ni iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìdí nìyẹn tí mo fi máa ń gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú pé káwọn náà ṣe é.
Tí mo bá ń ronú lórí àádọ́rin (70) ọdún ti mo ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, mo rí i pé ọ̀pọ̀ ìbùkún ni mo ti gbádùn, Jèhófà sì ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Kò ní yà yín lẹ́nu pé títí di báyìí mo ṣì máa ń tijú. Torí náà, ó ṣe kedere pé Jèhófà ló mú kí n lè ṣe gbogbo ohun tí mo ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ibi ni mo ti lọ lórílẹ̀-èdè yìí, onírúurú èèyàn ni mo bá pà dé, tí mo sì kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ lára wọn. Mo lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ pé mi ò kábàámọ̀, ká ló ṣeé ṣe kí ń pa dà di ọ̀dọ́ ni, iṣẹ́ yìí náà ni màá tún fáyé mi ṣe.
a Ìtàn ìgbésí ayé Piero Gatti tó sọ pé, “Mo Bẹ̀rù Ikú, Àmọ́ Ìyè ‘Lọ́pọ̀ Yanturu’ Ni Mò Ń Retí Báyìí,” wà nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2011.
b Alábòójútó agbègbè ló máa ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn àyíká mélòó kan tó wà ní agbègbè kan.