Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MILTIADIS STAVROU | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

“Jèhófà Bójú Tó Wa, Ó sì Tọ́ Wa Sọ́nà Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Wa”

“Jèhófà Bójú Tó Wa, Ó sì Tọ́ Wa Sọ́nà Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Wa”

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, bíi tàwọn ọmọ tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́, mo fẹ́ràn láti máa wo àwọn mọ́tò tó ń kọjá ládùúgbò wa ní Tripoli, lórílẹ̀-èdè Lebanon. Lọ́jọ́ kan, mo rí ọkọ̀ pupa kan tó rẹwà gan-an, ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Síríà ló sì ń wà á. Àmọ́, ó yà mí lẹ́nu nígbà tí àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àdúgbò wa sọ fún wa pé ká sọ òkúta lu ọkọ̀ náà torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹni tó ni ín!

 A sọ fún àlùfáà náà pé tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè ṣe ẹni tó ń wa mọ́tò náà léṣe. Ló bá sọ fún wa pé: “Ó pẹ́ kó tó kú dànù. Ẹ máa fi aṣọ mi nu ẹ̀jẹ̀ ẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yín!” Bo tiẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń fi bí ìdílé wa ṣe jẹ́ ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì yangàn, ọ̀rọ̀ tí àlùfáà fìbínú sọ yìí wà lára ohun tó jẹ́ kí n fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀. Kódà, ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ló jẹ́ kí n rí òtítọ́.

Bí Mo Ṣe Mọ Òtítọ́ Nípa Jèhófà

 Bí mo ṣe ń dàgbà, oríṣiríṣi èèyàn tí àṣà, èdè àti ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra ló wà nílùú Tripoli. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ló máa ń fi ẹbí wọn yangàn, èyí ò sì yọ ìdílé tiwa náà sílẹ̀. Èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi mẹ́ta dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní Àwọn Ọmọ Ogun Onígbàgbọ́ a tó máa ń ta ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A ò mọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan, àmọ́ ohun tí àlùfáà wa sọ fún wa nípa wọn ni pé wọ́n ń ta ko ẹ̀sìn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì, ẹnì kan tó ń jẹ́ Jèhófà sì ni aṣáájú wọn. Gbogbo ìgbà ni àlùfáà yẹn máa ń sọ fún wa pé, ibikíbi tá a bá ti rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ni ká gbéjà kò wọ́n.

 Àwọn ẹ̀gbọ́n mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a jọ wà nínú ẹgbẹ́ yẹn ti pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èmi ò sì mọ̀. Dípò kí wọ́n gbéjà kò wọ́n, ṣe ni wọ́n gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn kí wọ́n lè fi han àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn pé ẹ̀sìn èké ni wọ́n ń ṣe. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, mo wọlé mo sì rí i tí inú ilé wa kún fọ́fọ́ fún èrò. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jíròrò Bíbélì pẹ̀lú ìdílé mi àtàwọn aládùúgbò wa kan. Inú bí mi gan-an! Mo ronú pé, kí nìdí táwọn ẹ̀gbọ́n mi fi dalẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì? Bí mo ṣe fẹ́ jáde báyìí ni ọ̀kan lára àwọn aládùúgbò wa tó jẹ́ dókítà àti Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún mi pé kí n jókòó kí n sì máa gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. Mọ̀lẹ́bí wa kan wá ka Sáàmù 83:18 síta látinú Bíbélì mi. Ẹnu yà mí láti rí i pé Jèhófà kì í ṣe aṣáájú ẹgbẹ́ kankan, àmọ́ ohun gan-an ni Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà! Ìgbà yẹn ló tó ṣe kedere sí mi pé irọ́ gbuu ni àlùfáà wa pa fún wa.

Àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi

 Torí pé mo fẹ́ mọ̀ sí i nípa Jèhófà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe nílé wa. Arákùnrin Michel Aboud ló sì máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan lára àwọn tá a jọ wà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà béèrè ìbéèrè kan tó ti wà lọ́kàn mi látìgbà tí mo ti wà ní kékeré. Ó sọ pé, “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún wa, ta ló dá Ọlọ́run?” Arákùnrin Aboud ni ká wo ológbò kan tó sùn sórí àga. Ó wá ṣàlàyé pé bí ológbò yẹn ò ṣe lè lóye ọ̀rọ̀ táwa èèyàn ń sọ tàbí mọ bá a ṣe ń ronú, bẹ́ẹ̀ náà làwa èèyàn ò lè mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Ọlọ́run. Àpèjúwe ṣókí yẹn jẹ́ kí n rí ìdí tí mi ò fi lè lóye àwọn apá kan nípa Jèhófà dáadáa. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), mo sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1946.

Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Jẹ́ Kí Ìgbésí Ayé Mi Nítumọ̀

 Lọ́dún 1948, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ayàwòrán lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi kan tó ń jẹ́ Hanna. Ẹ̀gbẹ́ ṣọ́ọ̀bù Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Najib Salem ni ṣọ́ọ̀bù ẹ̀gbọ́n mi wà. b Arákùnrin Najib nígboyà gan-an, wọ́n sì fìtara wàásù títí wọ́n fi kú lẹ́ni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún. Tá a bá jọ lọ wàásù láwọn abúlé, wọ́n máa ń fìgboyà sọ̀rọ̀ láìka báwọn èèyàn ṣe ń ta kò wá. Bákan náà, ó máa ń rọrùn fún wọn láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnikẹ́ni látinú Bíbélì láìka ẹ̀sìn tẹ́ni náà ń ṣe. Àpẹẹrẹ arákùnrin yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an jálẹ̀ ìgbésí ayé mi.

Àpẹẹrẹ Najib Salem (lọ́wọ́ ẹ̀yìn, lápá ọ̀tún) ràn mí lọ́wọ́ jálẹ̀ ayé mi

 Lọ́jọ́ kan tí mo wà lẹ́nu iṣẹ́, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Mary Shaayah tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Lebanon tó sì ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wá kí wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ ẹ̀ máa ń dí gan-an torí pé ó láwọn ọmọ tó ń tọ́, aṣáájú-ọ̀nà tó nítara ni. Ohun tí wọ́n bá mi sọ lọ́jọ́ yẹn ló yí ìgbésí ayé mi pa dà. Ó lé ní wákàtí méjì tí arábìnrin yìí fi ń sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù fún wa. Kí wọ́n tó máa lọ, arábìnrin Mary sọ fún mi pé: “Milto, kí ló dé tí o ò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ó ṣe tán o ò tíì níyàwó?” Mo sọ pé, bóyá nìyẹn máa ṣeé ṣe o, torí mo ní láti ṣiṣẹ́ kí n lè gbọ́ bùkátà ara mi. Ó wá bi mí pé: “Ó ti tó wákàtí mélòó tí mo ti wà pẹ̀lú ẹ̀ láàárọ̀ yìí?” Mo sọ pé: “Á ti tó wákàtí méjì.” Wọ́n wá sọ pé: “Mi ò tíì rí iṣẹ́ kan tó o ṣe ní gbogbo àsìkò yìí, tó o bá ń fi wákàtí méjì yẹn wàásù lójoojúmọ́, wàá lè ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Gbìyànjú ẹ̀ wò fọ́dún kan, kó o wá pinnu bóyá wàá máa báṣẹ́ náà lọ àbí wàá dáwọ́ dúró.”

 Nínú àṣà ìbílẹ̀ wa, ó ṣọ̀wọ́n kí ọkùnrin kan tó gbàmọ̀ràn lọ́wọ́ obìnrin. Àmọ́ ìmọ̀ràn tí arábìnrin Mary fún mi bọ́gbọ́n mu. Ní January 1952, ìyẹn oṣù méjì léyìn tá a jọ sọ̀rọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nǹkan bí ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n pè mí sí kíláàsì kejìlélógún (22) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíàdì.

Tẹbítọ̀rẹ́ ń kí mi bí mo ṣe ń lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1953

 Lẹ́yìn tí mo kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n rán mi lọ sí agbègbè Middle East. Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, mo fẹ́ Doris Wood tóun náà jẹ́ míṣọ́nnárì ní agbègbè Middle East. Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ti wá, ara ẹ̀ sì yọ̀ mọ́ọ̀yàn gan-an.

A Wàásù Lórílẹ̀-Èdè Síríà

 Kò pẹ́ lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, wọ́n ní kémi àti Doris lọ máa sìn nílùú Aleppo, lórílẹ̀-èdè Síríà. Torí pé wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa níbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló jẹ́ pé ẹnì kan ló sọ fún wa nípa wọn.

 Lọ́jọ́ kan, a lọ sọ́dọ̀ obìnrin kan tó fẹ́ ká máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó ṣe ṣílẹ̀kùn tó sì rí wa báyìí, ẹ̀rù bà á, ló bá sọ fún wa pé: “Ẹ máa ṣọ́ra o! Àwọn ọlọ́pàá ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò níbi ni, wọ́n ń béèrè ibi tẹ́ ẹ̀ ń gbé.” Àṣé àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyé mọ ilé àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. La bá pe àwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní Middle East, wọ́n sì sọ fún wa pé ká fi orílẹ̀-èdè sílẹ̀ kíákíá. Inú wa ò dùn bá a ṣe ń fi àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa sílẹ̀, àmọ́ a rọ́wọ́ ìfẹ́ Jèhófà lára wa, a sì rí i pé òun ló ń dáàbò bò wá.

Jèhófà Tọ́ Wa Sọ́nà Lórílè-Èdè Iraq

 Lọ́dún 1955, ètò Ọlọ́run ní ká lọ máa sìn nílùú Baghdad, lórílẹ̀-èdè Iraq. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè fọgbọ́n wàásù fún gbogbo àwọn tó wà ní Iraq, àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn Kristẹni la máa ń dìídì wá lọ.

Èmi àtàwọn míṣọ́nnárì míì ní Iraq

 A tún máa ń gbìyànjú láti bá àwọn Mùsùlùmí tá a bá pàdé lọ́jà tàbí lójú ọ̀nà sọ̀rọ̀. Ìyàwó mi sábà máa ń sọ ohun táwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ sí. Bí àpẹẹrẹ, ó lè sọ pé: “Bàbá mi sábà máa ń sọ pé gbogbo wa la máa jíhìn níwájú Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Á tún wá fi kún un pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbèésí ayé mi. Kí lẹ̀yin náà rò nípa ẹ̀?”

 A gbádùn nǹkan bí ọdún mẹ́ta tá a fi sìn ní Baghdad, a sì ran àwọn ará tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣètò bí wọ́n ṣe lè máa fọgbọ́n wàásù. Bákan náà, ilé wa la ti máa ń ṣèpàdé léde Lárúbáwá. Inú wa dùn gan-an láti rí àwọn tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Ásíríà tí ọ̀pọ̀ nínú wọn jẹ́ Kristẹni ní àwọn ìpàdé wa. Nígbà tí wọ́n rí bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wa, tá a sì wà níṣọ̀kan, wọ́n gbà pé àwa gan-an ni ọmọlẹ́yìn Jésù lóòótọ́.​—John 13:35.

A máa ń ṣèpàdé nílé wa ní Baghdad

 Lára àwọn tó kọ́kọ́ wá sínú òtítọ́ ni Nicolas Aziz, èèyàn jẹ́jẹ́ ni, ó sì jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Armenia àti Ásíríà. Nígbà tí Nicolas àti Helen ìyàwó ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà àti Jésù ọmọ rẹ̀ yàtọ̀ síra, inú wọn dùn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ sì ni wọ́n gba ẹ̀kọ́ yẹn. (1 Kọ́ríńtì 8:5, 6) Mo ṣì rántí ọjọ́ tí Nicolas àtàwọn míì tó tó ogún (20) ṣèrìbọmi nínú Odò Yúfírétì.

Jèhófà Ràn Wá Lọ́wọ́ Lórílẹ̀-Èdè Iran

Ní Iran lọ́dún 1958

 Ní July 14, 1958, àwọn kan dìtẹ̀ gbàjọba, wọ́n sì pa ọba ilẹ̀ Iraq, ìyẹn Ọba Faisal Kejì. Kò pé lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ni ìjọba lé wa lọ sórílẹ̀-èdè Iran. Nígbà tá a débẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ sí í fọgbọ́n wàásù fáwọn àjèjì tó wà níbẹ̀ fún nǹkan bí oṣù mẹ́fà.

 Ká tó kúrò nílùú Tehran tó jẹ́ olú ìlú Iran, àwọn ọlọ́pàá mú mi lọ sí àgọ́ wọn kí wọ́n lè fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò. Èyí jẹ́ kí n rí i pé àwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ wa lọ́wọ́lẹ́sẹ̀. Lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yẹn, mo pe ìyàwó mi, mo sì sọ fún un pé àwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ wa o. Torí kí wọ́n má bàa ṣe wá níjàǹbá, a pinnu pé kí n má pa dà sílé, kémi àti ẹ̀ má sì wà pa pọ̀ títí dìgbà tá a fi máa kúrò lórílẹ̀-èdè náà.

 Ìyàwó mi rí ibì kan tó lè fara pa mọ́ sí títí dìgbà tá a fi máa pàdé ní pápákò òfúrufú. Àmọ́, báwo ló ṣe máa débẹ̀ pẹ̀lú báwọn ọlọ́pàá ṣe ń ṣọ́ ọ. Ó wá fi ọ̀rọ̀ náà sádùúrà.

 Lójijì, ojó ńlá kan bẹ̀rẹ̀, gbogbo èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ibi tí wọ́n máa fara pa mọ́ sí títí kan àwọn ọlọ́pàá. Ní gbogbo ojú ọ̀nà bá dá, ìyàwó mi sì ráyè wá sí pápákò òfúrufú náà láìséwu. Ìyàwó mi wá sọ pé, “Iṣẹ́ ìyanu ńlá gbáà ni òjò yẹn jẹ́!”

 Lẹ́yìn tá a kúrò ní Iran, ètò Ọlọ́run ní ká lọ sí agbègbè míì. Níbẹ̀, a wàásù fáwọn èèyàn tó wá láti onírúurú ẹ̀yà, tí ẹ̀sìn wọn náà sì yàtọ̀ síra. Nígbà tó di 1961, a di alábòójútó àyíká, a sì ń bẹ àwọn ará tó wà láwọn agbègbè tó wà ní Middle East wò.

A Rí Agbára Ẹ̀mí Jèhófà Lẹ́nu Iṣẹ́ Wa

 Inú wa dùn gan-an láti rí bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, tó sì ń mú káwọn èèyàn wà níṣọ̀kan ní agbègbè Middle East. Mo ṣì rántí àwọn ìjíròrò alárinrin tí mo máa ń ní pẹ̀lú àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Palẹ́sìnì méjì, ìyẹn Eddy àti Nicolas bí mo ṣe ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn méjèèjì gbádùn kí wọ́n máa wá sípàdé, àmọ́ ṣàdédé ni wọ́n dá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn dúró torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ òṣèlú gan-an. Mo wá gbàdúrà pé kí Jèhófà jọ̀ọ́, kó fọwọ́ tọ́ ọkàn wọn. Nígbà tí wọ́n lóye pé kì í ṣe ìṣòro àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Palẹ́sìnì nìkan ni Ọlọ́run máa yanjú, àmọ́ tí gbogbo aráyé, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn pa dà. (Àìsáyà 2:4) Wọ́n jáwọ́ nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Nígbà tó yá, Nicolas di alábòójútó àyíká tó nítara.

 Bí èmi àti ìyàwó mi ṣe ń rìnrìn àjò láti ìlú kan dé òmíì, a rí i pé àwọn ará wa jẹ́ olóòótọ́ láìka onírúurú ipò tí wọ́n wà sí, ìyẹn sì wú wa lórí gan-an. Torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn ará wa yìí ń fara dà, mo pinnu pé màá ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe láti máa tù wọ́n nínú nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò. (Róòmù 1:11, 12) Kí èyí lè ṣeé ṣe, mo máa ń sapá kí n má bàa máa ronú pé mo sàn ju àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi lọ. (1 Kọ́ríńtì 9:22) Bí mo ṣe ń tu àwọn ará nínú, tí mo sì ń fún wọn níṣìírí múnú mi dùn gan-an.

 Bá a ṣe ń rí i tí ọ̀pọ̀ àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì di ìránṣẹ́ Jèhófà mórí wa wú gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan nínú wọn ti kó lọ sókè òkun torí rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ nílùú wọn, àwọn yìí ti ṣèrànwọ́ gan-an láwọn ìjọ tó ń sọ èdè Lárúbáwà ní Ọsirélíà, Kánádà, Yúróòpù àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, díẹ̀ lára àwọn ọmọ wọn tó ti dàgbà pa dà sí Middle East kí wọ́n lè lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn akéde onígboyà. Inú èmi àtìyàwó mi máa ń dùn gan-an torí pé a ní ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ọmọ àti ọmọ ọmọ fún wa nípa tẹ̀mí.

Títí Láé La Máa Gbára Lé Jèhófà

 Ojoojúmọ́ ayé wa là ń rí bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ bójú tó wa, tó sì ń tọ́ wa sọ́nà. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ràn mí lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè tí mo ní nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́. Bí àwọn ará tí kì í ṣojúsàájú tó sì nígboyà ṣe dá mi lẹ́kọ̀ọ́ mú kó ṣeé ṣe fémi náà láti wàásù fún onírúurú èèyàn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra. Bí èmi àtìyàwó mi ṣe ń rìnrìn àjò láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíì, ọ̀pọ̀ ìṣòro la dojú kọ, a ò sì mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa. Èyí mú ká gbára lé Jèhófà pátápátá dípò ara wa.​—Sáàmù 16:8.

 Tí mo bá ń ronú nípa ọ̀pọ̀ ọdún ti mo ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, mo rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà Baba mi ọ̀run ti ṣe fún mi. Mo gbà pẹ̀lú ìyàwó mi tó sábà máa ń sọ pé kò sí ohun tó lè mú ká jáwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kódà a ò ní jáwọ́ tí wọ́n bá fi ikú halẹ̀ mọ́ wa! A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà tó fún wa láǹfààní láti wàásù ìhìn rere àlàáfíà ní agbègbè Middle East. (Sáàmù 46:8, 9) Bá a ṣe ń ronú nípa ojọ́ iwájú, ọkàn wa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà á máa darí, á sì máa dáàbò bò gbogbo àwọn tó bá gbára lé e.​—Àìsáyà 26:3.

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹgbẹ́ yìí, wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 1980, ojú ìwé 186 sí 188.

b Wàá rí ìtàn ìgbésí ayé Najib Salem nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 2001, ojú ìwé 22 sí 26.