LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA
Wọ́n Ń Sin Jèhófà Nìṣó Láìka Ìṣòro Àìlówó Lọ́wọ́ Sí
Bí nǹkan ṣe ń wọ́n sí i lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè ń mú kí nǹkan nira fáwọn èèyàn, kò sì yọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀. Àmọ́, dípò ká máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ, ọkàn wa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà kò ní ‘pa àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tì láé’. (Hébérù 13:5) Ká sòótọ́, Jèhófà ò já wa kulẹ̀ rí. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Philippines. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ ló jẹ́ òtòṣì, kódà láàárín ọdún 1970 sí 1989, ìyà jẹ àwọn èèyàn gan-an lórílẹ̀-èdè yẹn, àmọ́ Jèhófà ò fi àwọn èèyàn ẹ̀ sílẹ̀.
Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Vicky a sọ bí nǹkan ṣe rí nígbà yẹn, ó ní: “Mo máa ń sunkún torí mi ò kì í jẹun re kánú. Mo tiẹ̀ rántí àwọn ìgbà kan tó jẹ́ pé a ò ní ju ìrẹsì, iyọ̀ àti omi.” Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Florencio ni tiẹ̀ wá iṣẹ́ títí, àmọ́ kò ríṣẹ́. Ó ní: “Mi ò ní ju ẹ̀wù mẹ́ta àti ṣòkòtò mẹ́ta, mo ṣáà máa ń yọ ọ́ síra tí mo bá ń lọ sípàdé àti àwọn àpéjọ wa.” Kí ló jẹ́ káwọn èèyàn Jèhófà lè fara dà á? Kí ló sì mú kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lábẹ́ ipò tó ṣòro yẹn? Tá a bá ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn, báwo nìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ táwọn nǹkan àìròtẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa?
Wọ́n Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
Ó dá àwọn ará tó wà lórílẹ̀-èdè Philippines lójú pé Jèhófà ò ní fi àwọn sílẹ̀ lákòókò tí nǹkan nira yẹn. (Hébérù 13:6) Jèhófà sì ràn wọ́n lọ́wọ́ lóòótọ́, kódà láwọn ọ̀nà tó yà wọ́n lẹ́nu. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Cecille, ó sọ pé: ‘Mo rántí ọjọ́ kan tó jẹ́ pé gbogbo oúnjẹ tó kù nílé ò ju agolo ìrẹsì kan lọ. Ohun làwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jẹ láàárọ̀ ọjọ́ yẹn. Ká tó jẹ ẹ́, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, a sì tún bẹ̀ ẹ́ pé kó pèsè àwọn nǹkan tá a máa nílò fún ọjọ́ yẹn. Jèhófà dáhùn àdúrà yẹn lọ́nà àrà, torí a ṣì ń jẹun lọ́wọ́ nígbà tí arákùnrin kan gbé ìrẹsì nǹkan bíi agolo méjìlélọ́gbọ̀n wá fún wa. Ṣe ni omijé ayọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú wa. Inú wa dùn gan-an, a sì mọyì ohun tí Jèhófà ṣe yìí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà sì ti ṣe irú nǹkan báyìí fún wa.’
Bákan náà, àwọn èèyàn Ọlọ́run fi ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì sílò. (Òwe 2:6, 7) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Arcelita tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi. Arábìnrin yìí ò tí ì lọ́kọ nígbà yẹn, ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu sì nira fún un torí náà ó sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ fún Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ó ronú lórí ohun tó wà ní Òwe 10:4 tó sọ pé: “Ọwọ́ tó dilẹ̀ ń sọni di òtòṣì, àmọ́ ọwọ́ tó ń ṣiṣẹ́ kára ń sọni di ọlọ́rọ̀.” Torí náà ó dá oko sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ẹ̀, èyí sì fi hàn pé ó fi ẹsẹ Bíbélì yẹn sílò. Arábìnrin Arcelita sọ pé: “Mo rí ọwọ́ Jèhófà lára mi torí irè oko tí mo rí pọ̀ débi pé mo jẹ nínú ẹ̀ mo sì tún tà lára ẹ̀ kí n lè rí owó ọkọ̀.”
Wọn Ò Kọ Ìpàdé Sílẹ̀
Yàtọ̀ sí ìṣòro àtijẹ-àtimu, àwọn ará tó wà lórílẹ̀-èdè Philippines ò ní owó tó pọ̀ tó láti ra ilẹ̀, kí wọ́n sì kọ́ àwọn Ilé Ìpàdé. Àmọ́ wọn ò torí ìyẹn kọ ìpàdé sílẹ̀, wọ́n ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé ká máa pàdé pọ ká lè máa gba ara wa níyànjú. (Hébérù 10:24, 25) Kí wọ́n lè máa ríbi ṣèpàdé, ṣe ni wọ́n dọ́gbọ́n sí i. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Deborah sọ pé: “Èmi àti arábìnrin tá a jọ ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kọ́ ahéré kékeré kan, àwa mẹ́fà la sábà máa ń ṣe ìpàdé níbẹ̀. A lo igi ọ̀pẹ láti ṣe òrùlé, imọ̀ igi àgbọn la fi ṣe ògiri, a sì lo ara igi ọ̀pẹ láti ṣe ìjókòó.”
Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ará máa ń ṣe ìpàdé nílé wọn. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Virginia sọ pé: “Igi ọparun àti ewé la fi kọ́ ilé tá à ń gbé, ibẹ̀ sì kéré gan-an. Ní gbogbo ọjọ́ Saturday, a máa ń kó gbogbo àga tó wà níbẹ̀ jáde, ká lè ráyè ṣèpàdé lọ́jọ́ kejì.” Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Noel sọ pé: “Òrùlé wa máa ń jò, torí náà tójò bá ń rọ̀ ṣe la máa ń gbé ike sílẹ̀. Àmọ́ ara máa ń tù wá torí pé à ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa.”
Ìtara Wọn fún Iṣẹ́ Ìwàásù Kò Dín Kù
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará yìí ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, ìtara wọn fún iṣẹ́ ìwàásù ò dín kù. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lindina tó ń gbé ní erékùṣù Negros sọ pé: “Torí pé a pọ̀ nínú ìdílé wa, tó sì jẹ́ pé bàbá mi nìkan ló ń ṣiṣẹ́, a ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Kódà, a kì í rí owó wọ mọ́tò lọ sóde ìwàásù, ẹsẹ̀ la fi máa ń rìn. Àmọ́, ṣe ni inú wa máa ń dùn torí pé a wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa, wọ́n ní ká rìn ká pọ̀ yíyẹ ní ń yẹni. A sì tún ń láyọ̀ bá a ṣe ń múnú Jèhófà dùn.”
Òkè pọ̀ láwọn agbègbè kan, ó sì jìnnà. Ìyẹn mú kó ṣòro láti lọ wàásù níbẹ̀ torí pé ọkọ̀ èrò kì í sábà lọ síbẹ̀. Arábìnrin Esther tó ń gbé ní erékùṣù Luzon sọ pé: “Nígbà míì, a máa ń tó bíi mẹ́fà sí méjìlá tá a máa ń lọ sáwọn agbègbè yẹn láti lọ wàásù, a sì máa ń tètè kúrò nílé torí pé ọ̀pọ̀ kìlómítà la máa rìn. A máa ń wàásù látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Ní ti oúnjẹ ńkọ́, ohun tá a máa ń ṣe ni pé àá ti se oúnjẹ dá ní, àá wá jókòó sábẹ́ igi tó tutù láti jẹun. Àwọn ará wa kan máa ń wà pẹ̀lú wa tí wọn ò ní ohun tí wọ́n máa jẹ, àmọ́ wọn ò torí ìyẹn sọ pé àwọn ò ní wá. A máa ń sọ fún wọn pé kí wọ́n fọkàn balẹ̀, pé oúnjẹ tá a gbé dá ní máa tó gbogbo wa jẹ.”
Jèhófà ń bù kún àwọn ará yìí gan-an. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1970, àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Philippines jẹ́ 54,789. Nígbà tó fi máa di ọdún 1989, iye yẹn ti di 102,487, ìyẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì. Lọ́dún 2023, iye àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Philippines ti tó 253,876.
“A Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Bá A Tiẹ̀ Jẹ́ Aláìní”
Láìka bí ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu ṣe nira tó, àwọn ará wa ṣì ń fayọ̀ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Antonio sọ pé: “A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìní.” Arábìnrin Fe Abad sọ pé: “Nígbà tí ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu dójú ẹ̀ fún èmi àti ọkọ mi, a ò fi Jèhófà sílẹ̀, a jẹ́ kí ohun tá a ni tẹ́ wa lọ́rùn, Jèhófà sì bù kún wa. Èyí jẹ́ káwọn ọmọ wa rí i pé ó yẹ káwọn náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”
Arábìnrin Lucila tó ń gbé ní erékùṣù Samar sọ pé: “Tí pe ẹnì kan jẹ́ aláìní ò ní kó má sin Jèhófà. Tá a bá fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́, a máa ní ìtẹ́lọ́rùn, àá sì máa láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, inú mi dùn gan-an nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àwa méjèèjì sì jọ ń ṣe iṣẹ́ náà.”
A mọ̀ pé ńṣe ni nǹkan a máa nira sí í bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, torí náà ẹ jẹ́ ká máa rántí ohun tí alàgbà kan tó ń jẹ́ Rodolfo sọ. Ó ní: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan nira gan-an láàárín ọdún 1970 sí 1989, mo rí ọwọ́ Jèhófà láyé mi. Òótọ́ ni pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, síbẹ̀ ọkàn mi balẹ̀ torí pé Jèhófà ń bójú tó mi. Mo lè fi gbogbo ẹnu sọ pé ìgbésí ayé mi nítumọ̀, mò sì ń fojú sọ́nà fún ‘ìyè tòótọ́’ nínú Párádísè tó ń bọ̀.”—1 Tímótì 6:19.
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.