Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

Ṣé Èèyàn Àlàáfíà àti Kristẹni Tòótọ́ Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New Zealand?

Ṣé Èèyàn Àlàáfíà àti Kristẹni Tòótọ́ Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New Zealand?

 Ní October 21, 1940, orílẹ̀-èdè New Zealand kéde pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tako ìjọba, a sì jẹ́ ewu fún àwọn ará ìlú. Ìkéde yìí mú kí nǹkan nira gan-an fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, síbẹ̀ a ò rẹ̀wẹ̀sì. Bí àpẹẹrẹ, à ń bá ìjọsìn wa nìṣó bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè wá da ìjọsìn wa rú kí wọ́n sì kó wa lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ.

 Andy Clarke, tó jẹ́ ọkọ obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Mary, kíyè sí i pé ìyàwó rẹ̀ ṣì ń lọ sípàdé láìka ìhàlẹ̀ àwọn aláṣẹ sí. Ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí í bà á pé wọ́n lè mú ìyàwó òun níbi tó ti ń lọ sípàdé. Ló bá pinnu pé òun náà á máa tẹ̀ lé e lọ sípàdé, ó sọ fún Mary pé: “Tí wọ́n bá mú ẹ, àfi kí wọ́n kúkú mú èmi náà!” Látìgbà yẹn ni Andy ti ń tẹ̀ lé ìyàwó rẹ̀ lọ sí gbogbo ìpàdé. Nígbà tó yá, òun náà ṣe ìrìbọmi, ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Irú ìpinnu tí Mary ṣe láìka inúnibíni sí ni ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní orílẹ̀-èdè New Zealand nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.

Wọ́n Ń Bá Iṣẹ́ Lọ Lẹ́wọ̀n

 Lọ́jọ́ kan, àwọn ọlọ́pàá dá John Murray tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin (78) dúró lójú ọ̀nà níbi tó ti ń sọ̀rọ̀ Bíbélì fáwọn èèyàn láti ilé dé ilé. Ilé ẹjọ́ dẹ́bi fún un pé ó ń kópa nínú iṣẹ́ ẹgbẹ́ tó ń tako ìjọba. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí míì ni wọ́n tún gbé lọ sílé ẹjọ́, wọ́n bu owó ìtanràn lé àwọn kan, wọ́n sì ju àwọn míì sẹ́wọ̀n fún nǹkan bí oṣù mẹ́ta.

 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í kópa nínú iṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn tí wọ́n ti fi Bíbélì kọ́. (Àìsáyà 2:⁠4) Torí náà, nígbà ogun, wọ́n fojú wọn rí màbo nígbà tí wọ́n pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n wọ iṣẹ́ ológun. Dípò kí wọ́n wọ iṣẹ́ ológun, nǹkan bí ọgọ́rin (80) àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé kí wọ́n fi àwọn sí àtìmọ́lé nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n jálẹ̀ àkókò ogun yẹn. Síbẹ̀, láìka bí wọ́n ṣe ń fìyà burúkú jẹ wọ́n níbẹ̀, pẹ̀lú òtútù tó ń mú gan-an, àwọn arákùnrin wa ń jọ́sìn Jèhófà láì dáwọ́ dúró.

 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fi àkókò ṣòfò rárá, ńṣe ni wọ́n tètè ṣètò bí wọ́n á ṣe máa ṣèpàdé àti bí wọ́n á ṣe máa wàásù. Wọ́n ń ṣèpàdé wọn lọ bí ìjọ, wọ́n sì ń wàásù fáwọn tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n. Kódà, láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n kan, wọ́n gba àwọn Ẹlẹ́rìí láyè láti ṣe àpéjọ àyíká, wọ́n kàn ní kí ẹ̀ṣọ́ kan dúró tì wọ́n. Inú ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn làwọn ẹlẹ́wọ̀n kan ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tí wọ́n sì ṣèrìbọmi.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà látìmọ́lé ṣètò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

 Bruce, tó jẹ́ ọmọkùnrin Mary àti Andy tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan lo àkókò tó fi wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nípa Bíbélì. Ó sọ pé, “Ní tèmi, ńṣe ló dà bíi pé mo lọ sílé ìwé torí pé mo ráyè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, mo kọ́ gbogbo ohun tí mo lè kọ́.”

 Lọ́dún 1944, ìjọba pinnu láti dá àwọn kan lára wa sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Àmọ́ àwọn ọ̀gágun ò gbà torí ó dá wọn lójú pé tí wọ́n bá tú wa sílẹ̀, àá máa sọ̀rọ̀ Bíbélì fáwọn èèyàn. Ìròyìn yẹn sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀wọ̀n ká àwọn agbawèrèmẹ́sìn yẹn lọ́wọ́ kò díẹ̀, kò lè yí ìgbàgbọ́ wọn pa dà.”

Wọn Kì Í Ṣe Ewu Fáwọn Ará Ìlú

 Nítorí ìròyìn tó gbòde kan pé wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, àwọn kan fẹ́ mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó yá, ọ̀pọ̀ èèyàn wá mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò lè ṣe àwọn ará ìlú ní jàǹbá kankan. Wọ́n ti wá mọ̀ pé Kristẹni tòótọ́ àti èèyàn àlàáfíà ni wá. Èyí ló mú kí iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New Zealand pọ̀ sí i láti 320 èèyàn lọ́dún 1939 sí 536 èèyàn lọ́dún 1945!

 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn aláṣẹ tó lọ́kàn rere máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé bí wọ́n ṣe fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò bẹ́tọ̀ọ́ mu. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí adájọ́ kan gbọ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan arákùnrin wa kan torí pé ó ń wàásù, adájọ́ náà fòpin sí ẹjọ́ yẹn. Ó sọ pé: “Pẹ̀lú ohun tí mo mọ̀ àti níbi tí òfin yé mi dé, kò bọ́gbọ́n mu láti ka ẹnì kan sí ọ̀daràn nítorí pé ó ń pín Bíbélì kiri fún àwọn èèyàn.”

 Nígbà tí wọ́n fún wa lómìnira lẹ́yìn ogun, ńṣe ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pinnu láti túbọ ran àwọn aládùúgbò wa lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Lọ́dún 1945, ẹ̀ka ọ́fíìsì fi lẹ́tà kan ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ tó wà ní New Zealand, wọ́n sọ pé: “Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín máa ṣọ́ra ṣe, kẹ́ ẹ jẹ́ onínúure, kẹ́ ẹ sì mú àwọn èèyàn lọ́rẹ̀ẹ́. Ẹ má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà tàbí bá wọn jiyàn. Ẹ máa rántí pé gbogbo èèyàn tá à ń bá pàdé ló ní ìgbàgbọ́ tiwọn, tí wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé e. . . . Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ṣì máa di ‘àgùntàn’ Olúwa, àwa la sì máa sìn wọ́n lọ sọ́dọ̀ Jèhófà àti sínú ìjọba rẹ̀.”

 Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá a lọ láti sọ̀rọ̀ Bíbélì fáwọn ará ìlú àtàwọn àlejò tó wá sí New Zealand. Lọ́jọ́ kan, láàárín wákàtí mélòó kan péré, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin ní ìlú Turangi bá àlejò mẹ́tàdínláàádọ́rin (67) tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàdínlógún (17) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sọ̀rọ̀ Ọlọ́run!

 Ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn New Zealand gbà pé èèyàn àlàáfíà àti Kristẹni tòótọ́ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti pé a rọ̀ mọ́ òtítọ́ Bíbélì, a sì ń sapá láti ṣe ohun tó sọ. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún, tí wọ́n sì ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó fi máa di ọdún 2019, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi ayọ̀ jọ́sìn ní orílẹ̀-èdè yìí ti ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rinlà (14,000) lọ.

Àwọn ará kóra jọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́yìn tí wọ́n fòfin dè wá lọ́dùn 1940

Àwọn yàrá ẹ̀wọ̀n ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní North Island, lórílẹ̀-èdè New Zealand

Ọgbà ẹ̀wọ̀n Hautu ní North Island, lórílẹ̀-èdè New Zealand

Lọ́dùn 1949, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi sí ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí wọn ò dá sí ìṣèlú