Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Jọ Wà fún Ara Wa

A Jọ Wà fún Ara Wa

Wà á jáde:

  • (ÌBẸ̀RẸ̀)

    Kò síṣọ̀kan nínú ayé!

    Àmọ́ tiwa yàtọ̀ gan-an!

  1. 1. Ọlọ́run kan la jọ ń sìn.

    Ẹ̀kọ́ kan náà ni a sì jọ ń kọ́.

    Tá a bá pàdé ara wa,

    Tẹ̀rín-tọ̀yàyà la máa ń kíra wa.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Bíṣòro bá dé,

    Ọkàn wa balẹ̀.

    A máa ń dúró ti ara wa.

    (ÈGBÈ)

    A kì í fi ọ̀rọ̀ àwọn ará wa ṣeré.

    À ń tu ara wa nínú nígbà ìṣòro.

    Ohun ìyanu ni ìṣọ̀kan yìí mà jẹ́!

    A kò ní jẹ́ kíṣọ̀kan yìí bà jẹ́, lágbára Jèhófà.

  2. 2. Ìwà wa kò lè dọ́gba.

    A máa ń fara dà á fún ara wa.

    Bí a ṣe ń wá àlàáfíà,

    Èyí máa ń mú inú Jèhófà dùn.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ọmọ Jèhófà

    Ni gbogbo wa jẹ́,

    Òtítọ́ ṣáà ló so wá pọ̀.

    (ÈGBÈ)

    A kì í fi ọ̀rọ̀ àwọn ará wa ṣeré.

    À ń tu ara wa nínú nígbà ìṣòro.

    Ohun ìyanu ni ìṣọ̀kan yìí mà jẹ́!

    A kò ní jẹ́ kíṣọ̀kan yìí bà jẹ́, lágbára Jèhófà.

    Ẹ̀kọ́ òtítọ́ ló so wá pọ̀!

    (ÈGBÈ)

    A kì í fi ọ̀rọ̀ àwọn ará wa ṣeré.

    À ń tu ara wa nínú nígbà ìṣòro.

    Ohun ìyanu ni ìṣọ̀kan yìí mà jẹ́!

    A kò ní jẹ́ kíṣọ̀kan yìí bà jẹ́ lágbára Jèhófà.

    Lágbára Jèhófà.

    Lágbára Jèhófà.