Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀rín Músẹ́ Nìkan Ti Tó

Ẹ̀rín Músẹ́ Nìkan Ti Tó

Wà á jáde:

  1. 1. A lè pa ọgọ́rùn-ún àlọ́;

    A le sọ ẹgbẹ̀rún ìtàn;

    A lè ya ìgbà àwòrán,

    Ṣó máa wọ wọ́n lọ́kàn?

    Àmọ́ wọ́n lè wá gbọ́rọ̀ wa

    Táa bá ṣenúure sí wọn.

    Kí a rẹ́rìn-ín músẹ́

    Sí wọn ti tó ńgbà míì.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ̀rín músẹ́ lè mú kí ọkàn yọ̀.

    Ẹ̀rín músẹ́ lè jẹ́ kí wọ́n gbọ́ wa.

    Tóo bá ń gbàdúrà, wàá ṣàṣeyọrí.

    Wàá rí i pẹ́rìn-ín músẹ́ nìkan ti tó.

  2. 2. Ọmọ aráyé burú, kò sífẹ̀ẹ́ kò sójú àánú.

    Wọn kì í ṣojú àánú sáwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́.

    Ó ń hàn lójú wọn nígbà míì, táa bá pàdé wọn lọ́nà.

    À ń bá wọn sọ̀rọ̀ ìtùnú, táa fún wọn nírètí.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ̀rín músẹ́ lè mú kí ọkàn yọ̀.

    Ẹ̀rín músẹ́ lè jẹ́ kí wọ́n gbọ́ wa.

    Tóo bá ń gbàdúrà, wàá ṣàṣeyọrí.

    Wàá rí i pẹ́rìn-ín músẹ́ nìkan ti tó.

  3. 3. Inú wa lè máà fẹ́ dùn, tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́

    Ọ̀rọ̀ táa lọ bá wọn sọ, tó máa fún wọn nírètí.

    Ọkàn àwọn kan ti le jù, wọn kò fẹ́ gbọ́ ìwàásù.

    Àmọ́ tá a bá rẹ́rìn-ín sí wọn, ọkàn wọn lè wá rọ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ̀rín músẹ́ lè mú kí ọkàn yọ̀.

    Ẹ̀rín músẹ́ lè jẹ́ kí wọ́n gbọ́ wa.

    Tóo bá ń gbàdúrà, wàá ṣàṣeyọrí.

    Wàá rí i pẹ́rìn-ín músẹ́ nìkan ti tó.