Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ
Wà á Jáde:
1. Mò ń wora mi láyé tuntun,
Níbi tí kò ní síbẹ̀rù mọ́.
Ó dé tán.
Ó dá mi
Lójú gan-an.
2. Jèhófà ló ṣe ìlérí yìí.
Ó dá mi lójú pé òótọ́ ni.
Ọkàn mi sì
Balẹ̀ pé
Ó máa ṣẹ.
(ÈGBÈ)
Ìtura—
Máa dé bá gbogbo àwọn èèyàn.
Àlàáfíà—
Yóò wá jọba bí Jèhófà ṣe fẹ́.
3. Àwọn èèyàn wa tí wọ́n ti kú,
Wọ́n máa jíǹde, a ó sì pa dà rí wọn.
Ó dé tán.
Ó dá mi
Lójú gan-an.
4. Kò ní sírora àtẹkún mọ́.
Ara gbogbo èèyàn máa jí pépé.
Ọkàn mi
Balẹ̀ pé
Yóò rí bẹ́ẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ìtura—
Máa dé bá gbogbo àwọn èèyàn.
Àlàáfíà—
Yóò wá jọba bí Jèhófà ṣe fẹ́.
5. Mo nígbàgbọ́ nínú Jèhófà;
Gbogbo ọ̀rọ̀ tó bá sọ yóò ṣẹ.
(ÀSOPỌ̀)
Ọkàn mi
Balẹ̀ pé
Ọjọ́ kan ń bọ̀
Tí ayé tuntun máa dé.
Ṣáà máa—
6. Wora rẹ láyé tuntun,
Níbi tí kò ní síbẹ̀rù mọ́.
Ó dé tán.
Ó dá mi
Lójú gan-an.