Jèhófà Ń Kí Ẹ Káàbọ̀ Sílé
Wà á jáde:
1. Ṣe ló dà bí pé àná ni
Nígbà tó o morúkọ mi,
Tó sì dọ́kàn rẹ.
O wá ṣáko lọ.
O fara dà á fúngbà díẹ̀
Ò ń rántí ohun ayọ̀,
Ó wà lọ́kàn rẹ láti pa dà wá.
(ÈGBÈ)
Káàbọ̀, ọ̀rẹ́ mí.
Ó ṣì lè ṣàtúnṣe.
Dúró sọ́dọ̀ mi
Ọ̀dọ́ mi làlàáfíà
Ayérayé wà
2. Mo fẹ́ kó o mo’un tó yẹ kó o ṣe
Kó o lè pa dà wá sílé
Kítura ọkàn sì lè jẹ́ tìrẹ.
Má bẹ̀rù, màá gbà ọ́ pa dà;
Èmi nibi ààbò rẹ.
Inu rẹ máa dùn
Pó o pa dà bẹ̀rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Káàbọ̀, ọ̀rẹ́ mí.
Ó ṣì lè ṣàtúnṣe.
Dúró sọ́dọ̀ mi
Ọ̀dọ́ mi làlàáfíà
Ayérayé wà
Kú àbọ̀.