Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Wà Lẹ́yìn Mi

Jèhófà Wà Lẹ́yìn Mi

Wà á jáde:

  1. 1. Mo jí lówùúrọ̀ yìí, mo sì gbàdúrà.

    Mo múra, mo sì jáde kúrò nílé.

    Wọn kò fẹ́ kí n wàásù, àmọ́ mi ò gbà.

    Jèhófà ni màá ṣègbọ́ràn sí.

    (ÈGBÈ)

    Ṣe lọkàn mi balẹ̀ bí igi tó wà létí odò.

    Jèhófà wà pẹ̀lú mi, mi ò ní bẹ̀rù.

    Jèhófà wà pẹ̀lú mi, mi ò ní bẹ̀rù.

  2. 2. Mo pàdé àwọn tó nílò ìtùnú.

    Ó wù mí gan-an pé kí n ràn wọ́n lọ́wọ́.

    Ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa tù wọ́n nínú gan-an.

    Jèhófà jọ̀ọ́, jẹ́ kí n tún pa dà rí wọn.

    (ÈGBÈ)

    Ṣe lọkàn mi balẹ̀ bí igi tó wà létí odò.

    Jèhófà wà pẹ̀lú mi, mi ò ní bẹ̀rù.

    Jèhófà wà pẹ̀lú mi, mi ò ní bẹ̀rù.

    (ÀSOPỌ̀)

    Ọ̀rọ̀ rẹ ń jó bí iná lọ́kàn mi.

    Mi ò ní dákẹ́, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ.

    Màá fi ayọ̀ kéde Ọ̀rọ̀ rẹ.

    Màá fìgboyà polongo orúkọ rẹ,

    Bẹ́gbẹ́ ará kárí ayé ti ń ṣe

    Kò síbẹ̀rù, màá ṣọkàn akin

    Gbogbo ayé mi ni màá fi sìn ọ́.

    Ayé tuntun òdodo rẹ dé tán!

  3. 3. Mo dúpẹ́ Jèhófà fọ́jọ́ òní

    Tó o jẹ́ kí n lè fayé mi yìn ọ́.

    Ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀ lọ́la.

    Mo mọ̀ pé ṣe ni wàá dúró tì mí.

    (ÈGBÈ)

    Ṣe lọkàn mi balẹ̀ bí igi tó wà létí odò.

    Jèhófà wà pẹ̀lú mi, mi ò ní bẹ̀rù.

    Jèhófà wà pẹ̀lú mi, mi ò ní bẹ̀rù.