Máa Dárí Jini Látọkàn
Wà á jáde:
1. Ìgbà kan wà tẹ́nì kan ṣẹ̀ mí.
Tí mo bá rántí, ó máa ń dùn mí.
Ó máa ń bà mí nínú jẹ́ gan-an.
Mi ò gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ mí.
Mo mọ̀ pé ó yẹ kí n ti dárí jì í.
Àmọ́ kò rọrùn fún mi rárá.
(ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Ohun tó ṣẹlẹ̀ kì í ṣe ẹ̀bi mi.
Jèhófà náà rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn dùn mí.
Mo wá bẹ Jèhófà pé:
(ÈGBÈ)
“Jọ̀ọ́, ràn mí lọ́wọ́.
Jẹ́ kọ́rọ̀ yìí tán nínú mi.
Baba, jẹ́ kí n lè dárí jì í.
Jẹ́ kí n ṣohun tó o fẹ́.
Jèhófà mo mọ̀ pé
Tí mo bá ṣẹ̀ ọ́, ò ń dárí jì mí.
Baba, jẹ́ kí n lè dárí jì í.
Jẹ́ kí n ṣohun tó o fẹ́;
Kí n dárí jì í.”
2. Mò ń gbìyànjú kí n má bàa rántí,
Àmọ́ ó ṣì wà lọ́kàn mi.
Ó yẹ kí n gbàgbé ọ̀rọ̀ àná.
Mo wá rí i pé inú mi kì í dùn.
Tí mo bá ń di àwọn èèyàn sínú,
Ìṣòro mi á máa pọ̀ sí i.
(ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Ohun tó ṣẹlẹ̀ kì í ṣe ẹ̀bi mi.
Jèhófà náà rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn dùn mí.
Mo wá bẹ Jèhófà pé:
(ÈGBÈ)
“Jọ̀ọ́, ràn mí lọ́wọ́.
Jẹ́ kọ́rọ̀ yìí tán nínú mi.
Baba, jẹ́ kí n lè dárí jì í.
Jẹ́ kí n ṣohun tó o fẹ́.
Jèhófà mo mọ̀ pé
Tí mo bá ṣẹ̀ ọ́, ò ń dárí jì mí.
Baba, jẹ́ kí n lè dárí jì í.
Jẹ́ kí n ṣohun tó o fẹ́;
Kí n dárí jì í.
Ràn mí lọ́wọ́
Kí n dárí jì í;
Kí n dárí jì í.”