Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Bẹ̀rù

Má Bẹ̀rù

Wà á jáde:

  1. 1. Bí ‘ṣòro bá dé, ó máa ń tojú súni.

    A máa ń ṣàníyàn, ó ń tánni lókun.

    Tí ìdààmú bá gbọkàn rẹ,

    Jọ̀ọ́ gbàdúrà sí Baba

    Ọ̀run;

    Ó ń gbọ́.

    (ÈGBÈ)

    Má bẹ̀rù rárá, ó wà pẹ̀lú rẹ,

    Ó ń fọwọ́ ọ̀tún òdodo dì ọ́ mú

    Bí ‘ṣòro bá fẹ́ pọ̀ jù,

    Rántí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.

    Kò ní fi ọ́ sílẹ̀.

    Ọ̀rẹ́,

    Ṣáà máa gbàdúrà.

  2. 2. Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń dúró tì wá.

    Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, wọ́n ń gbàdúrà fún wa.

    Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

    Ó máa ń jẹ́ ká lè fara da

    Ìṣòro,

    Láì mikàn.

    (ÈGBÈ)

    Má bẹ̀rù rárá, ó wà pẹ̀lú rẹ,

    Ó ń fọwọ́ ọ̀tún òdodo dì ọ́ mú

    Bí ‘ṣòro bá fẹ́ pọ̀ jù,

    Rántí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.

    Kò ní fi ọ́ sílẹ̀.

    Ọ̀rẹ́,

    (ÀSOPỌ̀)

    Bí ìrẹ̀wẹ̀sì bá fẹ́ wọlé,

    Ṣọkàn akin

    Ọ̀la ń bọ̀ wá dáa

    (ÈGBÈ)

    Má bẹ̀rù rárá, ó wà pẹ̀lú rẹ,

    Ó ń fọwọ́ ọ̀tún òdodo dì ọ́ mú

    Bí ‘ṣòro bá fẹ́ pọ̀ jù,

    Rántí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.

    Kò ní fi ọ́ sílẹ̀.

    Ọ̀rẹ́,

    Ṣáà máa gbàdúrà.